Orí 92
A Mú Awọn Adẹ́tẹ̀ Mẹ́wàá Láradá Lákòókò Ìrìn Àjò Jesu Tí Ó Kẹhin sí Jerusalẹmu
JESU sọ ìsapá ìgbìmọ̀ Sanhẹdrin lati pa á di asan nipa fífi Jerusalẹmu sílẹ̀ tí ó sì rìnrìn àjò lọ sí ìlú Efraimu, boya tí ó wà ní nǹkan bii ibùsọ̀ mẹẹdogun péré ní àríwá ìlà-oòrùn Jerusalẹmu. Nibẹ ni ó dúró sí pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, jinna sí awọn ọ̀tá rẹ̀.
Bí ó ti wù kí ó rí, àkókò Irekọja 33 C.E. ti ńsúnmọ́lé, ati pe láìpẹ́ Jesu ti tún mú ọ̀nà rẹ̀ pọ̀n. Ó rin ìrìn-àjò la Samaria kọja lati lọ sókè títí wọ Galili. Eyi jẹ́ ìbẹ̀wò rẹ̀ tí ó kẹhin sí àgbègbè yii ṣaaju ikú rẹ̀. Nigba tí ó fi wà ní Galili, ó ṣeeṣe kí oun ati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ti darapọ̀ mọ́ awọn ẹlomiran tí wọn wà loju ọna lọ sí Jerusalẹmu fun àṣeyẹ Irekọja. Wọn gbà ojú ọ̀nà tí ó là àgbègbè Peria kọja, ní ìlà-oòrùn Odò Jọdani.
Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò naa, nigba ti Jesu fi ńwọ abúlé kan yálà ní Samaria tabi ní Galili, awọn ọkunrin mẹ́wàá tí wọn ní ẹ̀tẹ̀ pade rẹ̀. Òkùnrùn bíbanilẹ́rù yii maa ńjẹ awọn ẹ̀yà ara ènìyàn tán ní diẹdiẹ—awọn ọmọ ìka ọwọ́ rẹ̀, awọn ọmọ-ìka ẹsẹ̀ rẹ̀, etí rẹ̀, imú rẹ̀, ati awọn ètè rẹ̀. Lati daabobo awọn ẹlomiran kuro lọwọ dídi ẹni tí a kó èèràn ràn, Òfin Ọlọrun sọ nipa adẹ́tẹ̀ kan pe: “Kí ó sì fi ìbò bò ètè rẹ̀ òkè, kí ó sì maa ké pe, Aláìmọ́, aláìmọ́. Ní gbogbo ọjọ́ tí àrùn naa ńbẹ ní ara rẹ̀ ni kí ó jẹ́ eléèérí. . . . Lẹhin ibùdó ni ibùjókòó rẹ̀ yoo gbé wà.”
Awọn adẹ́tẹ̀ mẹ́wàá naa pa awọn ìkálọ́wọ́kò Òfin fun awọn adẹ́tẹ̀ mọ́ wọn sì dúró ní ọ̀nà jíjìn sí Jesu. Sibẹ, wọn ké pẹlu ohùn rara pe: “Jesu, Olùkọ́ni, ṣàánú fun wa!”
Ní rírí wọn ní òkèèrè, Jesu pàṣẹ pe: “Ẹ lọ fi araayin hàn fun awọn alufaa.” Jesu sọ eyi nitori pe Òfin Ọlọrun fàṣẹ fún awọn alufaa lati maa kéde pe a ti mú awọn adẹ́tẹ̀ tí wọn bá ti sàn kuro ninu àrùn wọn láradá. Ní ọ̀nà yii irúfẹ́ awọn ẹni bẹẹ rí ìtẹ́wọ́gbà lati maa gbé lẹẹkan sí i láàárín awọn ènìyàn onílera.
Awọn adẹ́tẹ̀ mẹ́wàá naa ní ìgbọ́kànlé ninu awọn agbára iṣẹ́ ìyanu Jesu. Nitori naa wọn yára lọ lati rí awọn alufaa, bí ó tilẹ jẹ́ pe a kò tíì mú wọn láradá sibẹ. Bí wọn ti ńlọ ní ọ̀nà, ìgbàgbọ́ wọn ninu Jesu ni a san ẹ̀san fun. Wọn bẹrẹsii rí ti wọn sì ńní ìmọ̀lára ìlera wọn tí a ti múpadà bọ̀sípò!
Mẹ́sàn-án ninu awọn adẹ́tẹ̀ tí a ti wẹ̀mọ́ naa bá ọ̀nà tiwọn lọ, ṣugbọn adẹ́tẹ̀ kan tí ó ṣẹ́kù, ara Samaria kan, padà wá lati wá Jesu kiri. Eeṣe? Nitori pe oun kún fun ìmoore gidigidi fun ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí i. Ó yìn Ọlọrun pẹlu ohùn rara, nigba ti ó sì wá Jesu rí, ó wólẹ̀ ní ẹsẹ̀ rẹ̀, ní dídúpẹ́ lọwọ rẹ̀.
Ní ìfèsìpadà Jesu wipe: “Awọn mẹ́wàá kí a sọ di mímọ́? Awọn mẹ́sàn-án iyooku ha dà? A kò rí ẹnikan tí ó padà wá fi ògo fun Ọlọrun, bikoṣe alejo yii?”
Lẹhin eyi ó sọ fun ara Samaria naa pe: “Dìde, kí o sì maa lọ: ìgbàgbọ́ rẹ mú ọ láradá.”
Nigba ti a bá kà nipa ìmúláradá tí Jesu ṣe fun awọn adẹ́tẹ̀ mẹ́wàá naa, awa gbọdọ gba ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n naa tí ibeere rẹ̀ dọ́gbọ́n fihàn sinu ọkàn-àyà pe: “Awọn mẹ́sàn-án iyooku ha dà?” Àìmoore tí awọn mẹ́sàn-án yooku naa fihan jẹ́ àìdójú ìwọ̀n tí ó wúwo. Njẹ awa, gẹgẹ bi ara Samaria naa, yoo ha fi ara wa hàn gẹgẹ bi ẹni tí ó moore fun awọn ohun tí a rí gbà lati ọ̀dọ̀ Ọlọrun, títíkan ìlérí iye ainipẹkun tí ó ti dájú ninu ayé titun òdodo Ọlọrun? Johanu 11:54, 55; Luuku 17:11-19; Lefitiku 13:16, 17, 45, 46; Iṣipaya 21:3, 4.
▪ Bawo ni Jesu ṣe sọ awọn ìsapá lati pa á di asan?
▪ Nibo ni Jesu rìnrìn àjò lọ lẹhin naa, nibo ni ó sì ńrè?
▪ Eeṣe tí awọn adẹ́tẹ̀ naa fi dúró ní òkèèrè, kí sì ni ìdí tí Jesu fi sọ pe ki wọn lọ sọdọ awọn alufaa?
▪ Ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n wo ni ó yẹ kí a kọ́ lati inú ìrírí yii?