Orí 125
Ijẹrora Lori Òpó-igi
PAPỌ pẹlu Jesu awọn ọlọṣa meji ni a mú jade lọ lati jiya iku. Nibi ti ko jinna si ilu naa, itolọwọọwọ naa duro ni ibikan ti a npe ni Goligota, tabi Ibi Agbárí.
Awọn ẹlẹwọn naa ni a bọ́ aṣọ wọn. Lẹhin naa ni a pese waini ti a po pẹlu òjíá. O jọ pe awọn obinrin Jerusalẹmu ni o ṣe é, awọn ara Roomu si yọnda àpòpọ̀ aparora yii fun awọn wọnni ti a ńkàn mọ́gi. Bi o ti wu ki o ri, nigba ti Jesu tọ́ ọ wo, ó kọ̀ lati mú ninu rẹ̀. Eeṣe? Lọna ti o han gbangba oun fẹ lati ṣakoso gbogbo agbara ero ori rẹ lẹkun-unrẹrẹ nigba idanwo igbagbọ rẹ gigajulọ yii.
Jesu ni a nà sori opó igi nisinsinyi pẹlu awọn ọwọ rẹ lókè ori rẹ. Lẹhin naa awọn ọmọ-ogun kàn ìṣó titobi wọ inu awọn ọwọ ati ẹsẹ rẹ. Oun jà pẹlu irora bi awọn ìṣó naa ti gun ẹran ati iṣan wọnu. Nigba ti wọn gbe opo igi naa nàró, irora naa buru jai, nitori ìwọ̀n iwuwo ara fa oju ọgbẹ́ ìṣó naa ya. Sibẹ, dipo kí ó halẹ, Jesu gbadura fun awọn ọmọ ogun Roomu naa: “Baba, dariji wọn; nitori ti wọn ko mọ ohun ti wọn nṣe.”
Pilatu ti kàn àmì kan sara opó igi ti o ka pe: “Jesu ti Nasarẹti Ọba awọn Juu.” O jọ pe, o kọ eyi kii ṣe kiki nitori pe oun bọwọ fun Jesu nikan ni ṣugbọn nitori pe oun korira awọn alufaa Júù fun fifipa mú un ṣedajọ iku fun. Ki gbogbo eniyan ba le ka ami naa, Pilatu kọ ọ ni ede mẹta—ni Heberu, ni Latin ti a fi aṣẹ yàn, ati ni Giriiki ti o wọpọ.
Awọn olori alufa, papọ pẹlu Kaifa ati Anasi, ni irẹwẹsi bá. Ipokiki olojurere yii ba wakati ayọ iṣẹgun wọn jẹ. Nitori naa wọn ṣatako pe: “Maṣe kọ ọ́ pe, Ọba awọn Juu; ṣugbọn pe oun wipe, Emi ni Ọba awọn Juu.” Ni fifi ibinu han fun ṣiṣiṣẹ gẹgẹ bi irinṣẹ lati mu ete awọn alufaa ṣẹ, Pilatu dahun pẹlu ifidimulẹ gbọnyin pe: “Ohun ti mo ti kọ tan, mo ti kọ ọ na.”
Awọn alufaa, papọ pẹlu ọpọlọpọ ero, korajọ nisinsinyi si ibi ifiya iku jẹni naa, awọn alufaa si gbiyanju lati tako ẹ̀rí àmì naa. Wọn ṣatunsọ ẹri eke ti wọn sọ ni iṣaaju nibi ìgbẹ́jọ́ Sanhẹdrin. Nitori naa ko yanilẹnu pe awọn ti nkọja bẹrẹsii sọ ọrọ eebu, ti wọn nmi ori wọn ni ṣiṣẹlẹya wipe: “Óò iwọ ti yoo wo tẹmpili palẹ ti yoo si kọ́ ọ ni ọjọ mẹta, gba ara rẹ la! Bi iwọ ba jẹ ọmọkunrin Ọlọrun, sọkalẹ kuro lori opo-igi idaloro!”
“Awọn miiran ni oun gbala; oun ko le gba araarẹ la!” Awọn olori alufa ati awọn ọrẹ kòríkòsùn wọn onisin jalu ọrọ naa. “Ọba Isirẹli ni oun; ẹ jẹ ki o sọkalẹ kuro lori opo-igi idaloro nisinsinyi awa yoo si ni igbagbọ ninu rẹ. Oun ti fi igbẹkẹle rẹ̀ sinu Ọlọrun; ẹ jẹ ki O gbà á silẹ nisinsinyi bi Oun ba fẹ ẹ, nitori oun wipe, ‘Ọmọkunrin Ọlọrun ni emi.’”
Bi ẹmi naa ti ràn wọn, awọn ọmọ-ogun pẹlu darapọ ninu fifi Jesu ṣe yẹyẹ. Wọn pese ọtí kíkan fun un lati fi ṣe ẹlẹya, ti o jọ pe wọn gbe e soke rekọja awọn ètè rẹ ti o ti gbẹ. Wọn ṣáátá pe, “Bi iwọ ba jẹ ọba awọn Júù, gba ara rẹ la.” Ani awọn ọlọṣa naa paapaa—wọn kan ọkan si apa ọtun Jesu ati ekeji si apa osi—pẹgan rẹ. Rò ó wò na! Ọkunrin titobilọla julọ ti o tii gbe aye rí, bẹẹni, ẹni naa ti o ṣajọpin pẹlu Jehofa Ọlọrun ninu dida ohun gbogbo, jiya gbogbo eebu yii pẹlu iṣotitọ!
Awọn ọmọ-ogun mu awọn ẹwu awọleke Jesu wọn si pin si apa mẹrin. Wọn ṣẹ́ kèké lati mọ ti ta ni iwọnyi yoo jẹ. Bi o ti wu ki o ri, ẹwu awọtẹlẹ rẹ ko ni oju rírán, ni jijẹ ojulowo didaraju. Nitori naa awọn ọmọ-ogun naa wi fun ara wọn pe: “Ẹ maṣe jẹ ki a fa a ya, ṣugbọn ki a ṣẹ́ kèké nitori rẹ ti ẹni ti yoo jẹ.” Nipa bayi, laimọ, wọn mu iwe mimọ ṣẹ ti o wipe: “Wọn pin aṣọ mi laaarin araawọn, wọn si ṣẹ́ kèké le aṣọ ileke mi.”
Laipẹ ọkan lara awọn ọlọṣa wa mọriri pe Jesu nitootọ gbọdọ jẹ ọba kan. Nitori naa, ni bíbá ẹlẹgbẹ rẹ wi, oun wipe: “Iwọ ko bẹru Ọlọrun, ti iwọ wa ninu ẹbi kan naa? Niti wa, wọn jare nitori ere ohun ti awa ṣe ni awa njẹ: ṣugbọn ọkunrin yi ko ṣe ohun buburu kan.” Lẹhin naa oun ba Jesu sọrọ ni taarata, ni bibẹbẹ pe: “Ranti mi nigba ti iwọ ba de ijọba rẹ.”
Jesu fesi pe, ‘Loootọ ni mo wi fun ọ lonii, iwọ yoo wa pẹlu mi ni Paradise.’ Ileri yii ni a o muṣẹ nigba ti Jesu ba nṣakoso gẹgẹ bi Ọba ni ọrun ti o si ji oluṣe buburu aronúpìwàdà yii dide si iye lori ilẹ-aye ninu Paradise ti awọn olùla Amagẹdọn ja ati awọn alabaakẹgbẹ wọn yoo ni anfaani lati mú gbilẹ̀. Matiu 27:33-44, NW; Maaku 15:22-32; Luku 23:27, 32-43; Johanu 19:17-24.
▪ Eeṣe ti Jesu fi kọ̀ lati mu waini ti a po pẹlu òjíá?
▪ Ki ni o jọ pe o jẹ idi ti a fi gbe àmì sori opo igi Jesu, ifọrọwerọ wo ni eyi si tun mu wa laaarin Pilatu ati awọn olori alufaa?
▪ Eebu siwaju sii wo ni Jesu gba lori opo igi, ki ni o si fa a lọna hihan gbangba?
▪ Bawo ni asọtẹlẹ ṣe ni imuṣẹ nipa ohun ti o ṣẹlẹ si awọn ẹwu Jesu?
▪ Iyipada wo ni ọkan lara awọn ọlọṣa naa ṣe, bawo si ni Jesu yoo ṣe mu ibeere rẹ̀ ṣẹ?