Ẹ̀kọ́ 6
Kí Ni Ìjọba Ọlọrun?
Níbo ni ibùjókòó Ìjọba Ọlọrun? (1)
Ta ni Ọba rẹ̀? (2)
Àwọn mìíràn ha nípìn-ín nínú ìṣàkóso pẹ̀lú Ọba náà bí? Bí ó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, àwọn mélòó ni? (3)
Kí ní fi hàn pé a ń gbé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn? (4)
Kí ni Ìjọba Ọlọrun yóò ṣe fún aráyé ní ọjọ́ iwájú? (5-7)
1. Nígbà tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé, Jesu kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti gbàdúrà fún Ìjọba Ọlọrun. Ìjọba jẹ́ àkóso tí ọba ń ṣolórí rẹ̀. Ìjọba Ọlọrun jẹ́ àkóso àrà ọ̀tọ̀ kan. Ọ̀run ni a gbé e kalẹ̀ sí, yóò sì ṣàkóso lé ilẹ̀ ayé yìí lórí. Yóò ya orúkọ Ọlọrun sí mímọ́ tàbí sọ ọ́ di mímọ́. Yóò mú kí ìfẹ́ Ọlọrun di ṣíṣe lórí ilẹ̀ ayé, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ń ṣe é ní ọ̀run.—Matteu 6:9, 10.
2. Ọlọrun ṣèlérí pé Jesu yóò dí Ọba Ìjọba Òun. (Luku 1:30-33) Nígbà tí Jesu wà lórí ilẹ̀ ayé, ó fẹ̀rí hàn pé òun yóò jẹ́ Alákòóso pípé, onínúure, tí kì í ṣègbè. Nígbà tí ó padà sí ọ̀run, a kò gbé e gun orí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọba Ìjọba Ọlọrun lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. (Heberu 10:12, 13) Ní 1914, Jehofa fún Jesu ní ọlá àṣẹ tí Òún ti ṣèlérí fún un. Láti ìgbà náà wá, Jesu ti ń ṣàkóso ní ọ̀run gẹ́gẹ́ bí Ọba tí Jehofa yàn sípò.—Danieli 7:13, 14.
3. Jehofa tún ti yan àwọn ọkùnrin àti obìnrin olùṣòtítọ́ kan, láti inú ayé, láti lọ sí ọ̀run. Wọn yóò ṣàkóso pẹ̀lú Jesu gẹ́gẹ́ bí ọba, onídàájọ́, àti àlùfáà lórí aráyé. (Luku 22:28-30; Ìṣípayá 5:9, 10) Jesu pe àwọn alájùmọ̀ṣàkóso wọ̀nyí nínú Ìjọba rẹ̀ ní “agbo kékeré.” Iye wọ́n jẹ́ 144,000.—Luku 12:32; Ìṣípayá 14:1-3.
4. Ní gbàrà tí Jesu di Ọba, ó lé Satani àti àwọn áńgẹ́lì búburú rẹ̀ jáde ní ọ̀run, sí sàkání ilẹ̀ ayé. Ìdí nìyẹn tí àwọn nǹkan fi burú tó bẹ́ẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, láti ọdún 1914. (Ìṣípayá 12:9, 12) Ogun, ìyàn, àjàkálẹ̀ àrùn, ìwà àìlófin tí ń pọ̀ sí i—gbogbo ìwọ̀nyí jẹ́ apá kan “àmì” tí ń fi hàn pé Jesu ń ṣàkóso àti pé ètò ìgbékalẹ̀ yìí ti wà ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn rẹ̀.—Matteu 24:3, 7, 8, 12; Luku 21:10, 11; 2 Timoteu 3:1-5.
5. Láìpẹ́, Jesu yóò ṣèdájọ́ àwọn ènìyàn, yóò yà wọ́n sọ́tọ̀, gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn ti ń ya àgùntàn sọ́tọ̀ kúrò lára ewúrẹ́. “Àgùntàn” ni àwọn tí wọn yóò ti fẹ̀rí hàn pé wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin ọmọ abẹ́ rẹ̀. Wọn yóò jèrè ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé. “Ewúrẹ́” ni àwọn tí wọn yóò ti kọ Ìjọba Ọlọrun sílẹ̀. (Matteu 25:31-34, 46) Ní ọjọ́ iwájú tí kò jìnnà mọ́, Jesu yóò pa gbogbo ẹni bí ewúrẹ́ run. (2 Tessalonika 1:6-9) Bí ìwọ́ bá fẹ́ẹ́ jẹ́ ọ̀kan lára “awọn àgùntàn” Jesu, o gbọ́dọ̀ fetí sí ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà, kí o sì ṣiṣẹ́ lórí ohun tí o bá kọ́.—Matteu 24:14.
6. Nísinsìnyí, a ti pín ilẹ̀ ayé sí ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè. Ọ̀kọ̀ọ̀kan ní ìjọba tirẹ̀. Àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí sábà máa ń bá ara wọn jà. Ṣùgbọ́n Ìjọba Ọlọrun yóò rọ́pò gbogbo ìjọba ènìyàn. Yóò ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ìjọba kan ṣoṣo lórí gbogbo ilẹ̀ ayé. (Danieli 2:44) Nígbà náà, kì yóò sí ogun, ìwà ọ̀daràn, àti ìwà ipá mọ́. Gbogbo ènìyàn yóò máa gbé pọ̀ ní àlááfíà àti ìṣọ̀kan.—Mika 4:3, 4.
7. Nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Jesu, àwọn ẹ̀dá ènìyàn olùṣòtítọ́ yóò di pípé, gbogbo ilẹ̀ ayé yóò sì di paradise kan. Ní òpin ẹgbẹ̀rún ọdún náà, Jesu yóò ti ṣe gbogbo ohun tí Ọlọrun sọ pé kí ó ṣe. Nígbà náà, òun yóò dá Ìjọba náà padà fún Bàbá rẹ̀. (1 Korinti 15:24) Èé ṣe tí o kò fi sọ fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ àti àwọn àyànfẹ́ rẹ nípa ohun tí Ìjọba Ọlọrun yóò ṣe?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Lábẹ́ ìṣàkóso Jesu, kì yóò sí ìkórìíra tàbí ẹ̀tanú mọ́