ORÍ 28
Bí A Ṣe Lè Mọ Ẹni Tó Yẹ Kí Á Ṣègbọràn Sí
NÍGBÀ mìíràn ó máa ń nira láti mọ ẹni tó yẹ kí á ṣègbọràn sí. Bàbá rẹ tàbí ìyá rẹ lè sọ pé kí o ṣe ohun kan. Ṣùgbọ́n olùkọ́ tàbí ọlọ́pàá lè ní kí o ṣe ohun mìíràn tó yàtọ̀. Bí ìyẹn bá ṣẹlẹ̀, èwo nínú wọn ni ìwọ yóò ṣègbọràn sí?—
Lápá ìbẹ̀rẹ̀ ìwé yìí, ní Orí 7, a ka Éfésù 6:1-3 nínú Bíbélì. Ibẹ̀ sọ pé kí àwọn ọmọ ṣègbọràn sí àwọn òbí wọn. Ìwé Mímọ́ yẹn sọ pé: “Ẹ̀yin ọmọ, ẹ jẹ́ onígbọràn sí àwọn òbí yín ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Olúwa.” Ǹjẹ́ o mọ ohun tí ó túmọ̀ sí láti wà “ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Olúwa”?— Àwọn òbí tó bá wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Olúwa máa ń kọ́ àwọn ọmọ wọn láti máa pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́.
Ṣùgbọ́n àwọn èèyàn kan tó ti dàgbà kò gba Jèhófà gbọ́. Tí ọ̀kan nínú irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ bá wá sọ pé kò burú láti ṣe èrú lásìkò ìdánwò ní ilé ìwé tàbí pé kò burú láti mú ohun kan nínú ilé ìtajà láì san owó ńkọ́? Ṣé ìyẹn ti fi hàn pé ó tọ́ kí ọmọdé máa ṣe èrú tàbí kí ó máa jalè?—
Rántí pé Nebukadinésárì Ọba pàṣẹ nígbà kan pé kí gbogbo èèyàn tẹrí ba fún ère wúrà tí òun gbé kalẹ̀. Ṣùgbọ́n Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò kò tẹrí ba fún ère náà. Ǹjẹ́ o mọ ohun tó fà á tí wọn kò fi tẹrí ba?— Ó jẹ́ nítorí pé Bíbélì sọ pé Jèhófà nìkan ṣoṣo ni kí àwọn èèyàn máa jọ́sìn.—Ẹ́kísódù 20:3; Mátíù 4:10.
Lẹ́yìn tí Jésù kú, àwọn kan kó àwọn àpọ́sítélì wá síwájú Sànhẹ́dírìn, ìyẹn ilé ẹjọ́ ìsìn ti àwọn Júù. Àlùfáà Àgbà tó ń jẹ́ Káyáfà sọ pé: “A pa àṣẹ fún yín ní pàtó láti má ṣe máa kọ́ni nípa orúkọ [Jésù], síbẹ̀, sì wò ó! ẹ ti fi ẹ̀kọ́ yín kún Jerúsálẹ́mù.” Kí ló dé tí àwọn àpọ́sítélì kò fi ṣègbọràn sí àwọn Sànhẹ́dírìn?— Pétérù gbẹnu sọ fún gbogbo àwọn àpọ́sítélì yòókù, ó dá Káyáfà lóhùn pé: “Àwa gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò àwọn ènìyàn.”—Ìṣe 5:27-29.
Ní ayé ìgbà yẹn, àwọn aṣáájú ìsìn àwọn Júù ní agbára púpọ̀ gan-an. Àmọ́, abẹ́ ìjọba Róòmù ni orílẹ̀-èdè yẹn wà nígbà náà. Késárì ni wọ́n ń pe àwọn olórí ìjọba Róòmù. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Júù kò fẹ́ kí Késárì máa ṣàkóso wọn, ìjọba Róòmù ń ṣe ohun rere púpọ̀ fún àwọn èèyàn. Àwọn ìjọba òde òní pẹ̀lú ń ṣe ohun rere púpọ̀ fún àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè wọn. Ǹjẹ́ o mọ díẹ̀ lára nǹkan wọ̀nyí bí?—
Ìjọba ń ṣe ojú ọ̀nà tí a fi ń rìnrìn àjò, wọ́n ń san owó fún àwọn ọlọ́pàá àti panápaná kí wọ́n máa dáàbò bò wá. Wọ́n ń pèsè ilé ìwé fún àwọn èwe, wọ́n sì ń pèsè àbójútó ìlera fún àwọn àgbàlagbà pẹ̀lú. Ó ń ná ìjọba lówó láti ṣe nǹkan wọ̀nyí. Ǹjẹ́ o mọ ibi tí ìjọba ti ń rí owó náà?— Ọ̀dọ̀ àwọn ará ìlú ni. Owó tí àwọn ará ìlú ń san fún ìjọba ni à ń pè ní owó orí.
Nígbà tí Olùkọ́ Ńlá wà ní ayé, ọ̀pọ̀ àwọn Júù kì í fẹ́ san owó orí fún ìjọba Róòmù. Nítorí náà, ní ọjọ́ kan àwọn àlùfáà rán àwọn ọkùnrin kan pé kí wọ́n lọ bi Jésù ní ìbéèrè kan láti lè kó Jésù sínú ìjàngbọ̀n. Ìbéèrè náà ni, ‘Ṣé ó yẹ kí á máa san owó orí fún Késárì tàbí kò yẹ?’ Wọ́n fẹ́ fi ìbéèrè yìí tan Jésù ni o. Bí Jésù bá sọ pé, ‘Bẹ́ẹ̀ ni, ẹ gbọ́dọ̀ san owó orí,’ inú ọ̀pọ̀ àwọn Júù kò ní dùn nítorí ohun tí ó sọ. Ṣùgbọ́n Jésù kò lè sọ pé, ‘Rárá, kò yẹ kí ẹ san owó orí.’ Èyíinì yóò jẹ́ ohun tó lòdì láti sọ.
Nítorí náà, kí ni Jésù ṣe? Ó sọ pé: ‘Ẹ fi owó ẹyọ kan hàn mí.’ Nígbà tí wọ́n mú owó yẹn fún Jésù, ó bi wọ́n pé: ‘Àwòrán àti orúkọ ta ni ó wà lára rẹ̀?’ Àwọn ọkùnrin náà dáhùn pé: “Ti Késárì ni.” Nítorí náà, Jésù sọ pé: “Ẹ rí i dájú, nígbà náà, pé ẹ san àwọn ohun ti Késárì padà fún Késárì, ṣùgbọ́n àwọn ohun ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.”—Lúùkù 20:19-26.
Ṣé o rí i, kò sí ẹnikẹ́ni tí ó rí ohun tí ó burú nínú ìdáhùn yẹn. Bí Késárì bá ń ṣe àwọn nǹkan fún àwọn èèyàn, ohun tó tọ́ láti ṣe ni pé kí wọ́n lo owó tí Késárì ṣe láti fi san owó àwọn nǹkan wọ̀nyẹn padà fún un. Nítorí náà, ṣe ni Jésù ń fi hàn pé ó tọ́ láti san owó orí fún ìjọba nítorí àwọn ohun tí à ń rí gbà.
Wàyí o, ó ṣeé ṣe kí o máà tíì dàgbà tó láti máa san owó orí. Ṣùgbọ́n ohun kan wà tó yẹ kí o máa fún ìjọba. Ǹjẹ́ o mọ ohun náà?— Pípa òfin ìjọba mọ́ ni. Bíbélì sọ pé: ‘Ẹ máa ṣègbọràn sí àwọn aláṣẹ onípò gíga.’ Àwọn aláṣẹ yìí ni àwọn tó wà ní ipò àkóso nínú ìjọba. Nítorí náà, Ọlọ́run ni ó sọ pé kí á máa pa òfin ìjọba mọ́.—Róòmù 13:1, 2.
Òfin lè wà pé ẹnikẹ́ni ò gbọ́dọ̀ ju ìdọ̀tí bébà tàbí àwọn pàǹtírí mìíràn sí ojú pópó. Ǹjẹ́ ó yẹ kí o ṣègbọràn sí òfin yẹn?— Bẹ́ẹ̀ ni o, Ọlọ́run ń fẹ́ kí o pa òfin yẹn mọ́. Ṣé ó yẹ kí o ṣègbọràn sí àwọn ọlọ́pàá pẹ̀lú?— Ìjọba ni ó ń san owó fún àwọn ọlọ́pàá kí wọ́n lè máa dáàbò bo àwọn èèyàn. Tí a bá ṣègbọràn sí wọn á jẹ́ pé ìjọba ni à ń ṣègbọràn sí.
Nítorí náà, tí o bá fẹ́ sọdá ojú ọ̀nà tí ọlọ́pàá kan sì sọ pé “Dúró!” kí ló yẹ kí o ṣe?— Bí àwọn mìíràn bá kọ̀ tí wọ́n sáré kọjá síbẹ̀síbẹ̀, ǹjẹ́ ó yẹ kí ìwọ náà ṣe bẹ́ẹ̀?— Ṣe ni kí o dúró, àní bí ó bá tiẹ̀ jẹ́ pé ìwọ nìkan ni ó kù tó dúró. Ọlọ́run sọ fún ọ pé kí o ṣègbọràn.
Ìjàngbọ̀n lè ṣẹlẹ̀ ní àdúgbò, kí ọlọ́pàá sì sọ pé: “Má ṣe rìn lójú pópó. Má ṣe jáde síta.” Ṣùgbọ́n o lè gbọ́ ariwo, kí o sì fẹ́ mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀. Ǹjẹ́ ó yẹ kí o jáde síta láti lọ wò ó?— Ǹjẹ́ o ṣègbọràn sí “àwọn aláṣẹ onípò gíga” tí o bá ṣe bẹ́ẹ̀?—
Ní àwọn ibi púpọ̀, ìjọba máa ń kọ́ ilé ìwé, wọ́n sì máa ń san owó fún àwọn olùkọ́. Nítorí náà, ǹjẹ́ o rò pé Ọlọ́run ń fẹ́ kí o máa ṣègbọràn sí àwọn olùkọ́?— Ronú nípa rẹ̀ ná. Ìjọba máa ń san owó fún àwọn olùkọ́ láti máa kọ́ni níwèé, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ń san owó fún àwọn ọlọ́pàá láti máa dáàbò bo àwọn èèyàn. Nítorí náà, ṣíṣe ìgbọràn sí àwọn ọlọ́pàá tàbí olùkọ́ jẹ́ ṣíṣe ìgbọràn sí ìjọba.
Ṣùgbọ́n, bí olùkọ́ bá wá sọ pé o gbọ́dọ̀ júbà níwájú ère, àwòrán tàbí aṣọ kan ńkọ́? Kí ni wàá ṣe?— Àwọn Hébérù mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ò tẹrí ba fún ère, kódà nígbà tí Nebukadinésárì Ọba pàápàá sọ pé kí wọ́n tẹrí ba. Ǹjẹ́ o rántí ohun tó fà á?— Ohun tó fà á ni pé wọn ò fẹ́ ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run.
Òpìtàn kan tó ń jẹ́ Will Durant kọ̀wé nípa àwọn tó kọ́kọ́ jẹ́ Kristẹni ní ayé àtijọ́, ó sọ pé ‘wọn kò jẹ́ fi ìfọkànsìn [tàbí, ìdúróṣinṣin] wọn tó ga jù lọ fún Késárì.’ Wọn kò fún Késárì rárá, nítorí pé ti Jèhófà ni! Nítorí náà, rántí pé Ọlọ́run ló yẹ kí á máa fi ṣáájú nínú ohun gbogbo tí a bá ń ṣe.
À ń ṣègbọràn sí ìjọba nítorí pé ó jẹ́ ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ká ṣe. Ṣùgbọ́n tí ẹnì kan bá sọ pé kí á ṣe ohun tí Ọlọ́run sọ pé a kò gbọ́dọ̀ ṣe, kí ló yẹ kí á sọ?— Ó yẹ kí á sọ ohun tí àwọn àpọ́sítélì sọ fún àwọn àlùfáà àgbà náà pé: “Àwa gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò àwọn ènìyàn.”—Ìṣe 5:29.
Bíbélì kọ́ni pé kí á bọ̀wọ̀ fún òfin. Ka ohun tó wà nínú Mátíù 5:41; Títù 3:1; àti 1 Pétérù 2:12-14.