ÌSỌ̀RÍ 3
Jẹ́ Kí Ìwà Rẹ Àti Bó o Ṣe Ń bá Àwọn Ẹlòmíràn Lò Máa Múnú Ọlọ́run Dùn
Báwo ni wàá ṣe dáhùn ìbéèrè yìí: ‘Kí ni ohun tí Jèhófà ń béèrè lọ́wọ́ rẹ?’ (Míkà 6:8) Ìwé àwọn wòlíì méjìlá náà jẹ́ ká lóye èyí. Wàá rí i ní Orí Kẹjọ sí Ìkẹ́wàá nínú ìwé yìí pé àwọn ìwé méjìlá náà lè ràn ọ́ lọ́wọ́ kó o lè mọ bí wàá ṣe máa ṣe àwọn nǹkan kan tó lè má rọrùn, bíi sísọ òtítọ́ nígbà gbogbo àti yíyẹra fún ìwà ipá. Wàá tún rí àwọn ìmọ̀ràn tó wúlò tí wọ́n fúnni nípa ìdílé tó ṣeé ṣe kí ìwọ náà mú lò.