Ẹ̀KỌ́ 51
Jagunjagun àti Ọmọbìnrin Kékeré Kan
Ọmọbìnrin Ísírẹ́lì kan wà ní ilẹ̀ Síríà, ilẹ̀ yìí sì jìnnà gan-an sí ìlú rẹ̀. Àwọn ọmọ ogun Síríà ni wọ́n mú un kúrò lọ́dọ̀ àwọn òbí rẹ̀ lọ sí ilẹ̀ Síríà, ó sì ń ṣe ìránṣẹ́ fún ìyàwó ọ̀gágun kan tó ń jé Náámánì. Jèhófà ni ọmọbìnrin ń yìí ń jọ́sìn bó tilẹ̀ jẹ́ pé òrìṣà ni àwọn tó wà ní àyíkà rẹ̀ ń bọ.
Ó ṣẹlẹ̀ pé Náámánì ní àìsàn burúkú kan tó máa ń jẹ́ kí ara ro ó. Ó sì wu ọmọbìnrin yìí pé kí òun ran Náámánì lọ́wọ́. Ó wá sọ fún ìyàwó Náámánì pé: ‘Mo mọ ẹnì kan tó lè ran ọkọ yín lọ́wọ́. Ilẹ̀ Ísírẹ́lì ni ẹni náà wà, wòlíì Jèhófà ni, Èlíṣà sì ni orúkọ rẹ̀. Ó lè wo ọkọ yín sàn.’
Nígbà tí ìyàwó Náámánì sọ ọ̀rọ̀ ọmọbìnrin yìí fún Náámánì, Náámánì pinnu pé òun á lọ sí Ísírẹ́lì lọ bá Èlíṣà. Náámánì rò pé tí òun bá dé Ísírẹ́lì, ó yẹ kí Èlíṣà ṣe òun bí èèyàn pàtàkì. Àmọ́ Èlíṣà kò rí Náámánì sójú, ńṣe ló ní kí ìránṣe òun lọ pàdé Náámánì, kó sì sọ fún un pé: ‘Lọ wẹ̀ nínú Odò Jọ́dánì ní ìgbà méje, àìsàn rẹ yóò sì lọ.’
Ọ̀rọ̀ yìí bí Náámánì nínú gan-an. Ló bá ní: ‘Mo rò pé ńṣe ni wòlíì yìí á gbàdúrà fún mi tí á sì gbé ọwọ́ lé mi lórí, tí ara mi á sì yá. Ó wá ń sọ pé kí n lọ wẹ̀ nínú odò wọn ní Ísírẹ́lì. Ṣèbí a ní odò tó dára ju ìyẹn lọ ní Síríà, kí ló dé tí kò lè sọ pé kí n lọ wẹ̀ níbẹ̀?’ Ọ̀rọ̀ yìí bí Náámánì nínú gan-an débi pé ó fi ìbínú kúrò nílé Èlíṣà.
Ni àwọn ìránṣẹ́ Náámánì bá bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ Náámánì kó lè ṣe ohun tí ó tọ́. Wọ́n sọ fún un pé: ‘Tó bá jẹ́ pé ohun tí wòlíì yẹn sọ ló máa mú yín lára dá, ó dára kí ẹ ṣe é? Ohun tí wòlíì yìí sì ni kí ẹ ṣe kò le rárá. Kí ló wá dé tí ẹ ò fẹ́ ṣe é?’ Náámánì fetí sí wọn. Ó lọ sí Odò Jọ́dánì, ó sì wẹ̀ níbẹ̀ ní ìgbà méje. Nígbà tí Náámánì máa jáde nínú odò ní ìgbà keje, àìsàn tó ń ṣe é ti lọ. Inú rẹ̀ dùn gan-an, ó sì pa dà lọ dúpẹ́ lọ́wọ́ Èlíṣà. Náámánì ní: ‘Mo ti wá mọ̀ pé Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́.’ Báwo ló ṣe máa rí lára ọmọbìnrin Ísírẹ́lì yẹn nígbà tó rí i pé ara Náámánì ti yá?
“Láti ẹnu àwọn ìkókó àti àwọn ọmọ ẹnu ọmú ni o ti mú ìyìn jáde.”—Mátíù 21:16