ORIN 5
Àwọn Iṣẹ́ Àgbàyanu Ọlọ́run
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Ọlọ́run fagbára rẹ̀ dá mi,
Ó mọ̀ mí gan-an ju bí mo ṣe rò lọ.
Ó sì rí mi nínú ikùn ìyá mi;
Bí a ṣe bí mi, tí mò ń rìn,
tí mò ń sọ̀rọ̀.
Bí mo ṣe ń dìde, tí mò ń jókòó,
Bí mo ṣe ń sùn àti bí mo ṣe ń jí,
Àmọ̀dunjú ni gbogbo rẹ̀ jẹ́ fún ọ;
Èmi yóò gbé ọ lárugẹ,
màá sì yìn ọ́.
Ìmọ̀ rẹ pọ̀, ó sì kọjá òye mi;
Àgbàyanu ni èyí jẹ́ fún mi.
Bí mo bá sì sá lọ sínú òkùnkùn,
Ìwọ lè fi ẹ̀mí rẹ wá mi rí.
Kò sí ibi tí mo lè sá lọ
Tàbí tí mo lè fara pa mọ́ sí.
Ì báà jẹ́ ‘nú ibojì tàbí òkun
Ibikíbi tí mo bá wà,
o lè rí mi.
(Tún wo Sm. 66:3; 94:19; Jer. 17:10.)