ORIN 110
“Ìdùnnú Jèhófà”
1. Ìhìnrere là ń kéde fún aráyé
Pé Ìjọba náà ti bẹ̀rẹ̀.
Ẹ gbórí yín sókè, ìgbàlà dé tán;
Ìdáǹdè wa ti sún mọ́lé!
(ÈGBÈ)
Ìdùnnú Jèhófà lagbára wa.
Ká fi ayọ̀ kọrin ìyìn.
Ká fìmọrírì hàn fún ‘rètí táa ní,
Ká fọpẹ́ àt’ìyìn f’Ọ́lọ́run.
Ìdùnnú Jèhófà lagbára wa.
Ká pòkìkí rẹ̀ fáráyé.
Ká jọ́sìn Ọlọ́run wa tọkàntọkàn,
Ká sì máa láyọ̀ lẹ́nu ‘ṣẹ́ rẹ̀.
2. Ẹ̀yin tẹ́ ẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run,
Ẹ má bẹ̀rù, ẹ má fòyà.
Ẹ fi ìtara gbé ohùn yín sókè,
Kẹ́ ẹ kọrin ìyìn s’Ọ́lọ́run!
(ÈGBÈ)
Ìdùnnú Jèhófà lagbára wa.
Ká fi ayọ̀ kọrin ìyìn.
Ká fìmọrírì hàn fún ‘rètí táa ní,
Ká fọpẹ́ àt’ìyìn f’Ọ́lọ́run.
Ìdùnnú Jèhófà lagbára wa.
Ká pòkìkí rẹ̀ fáráyé.
Ká jọ́sìn Ọlọ́run wa tọkàntọkàn,
Ká sì máa láyọ̀ lẹ́nu ‘ṣẹ́ rẹ̀.
(Tún wo 1 Kíró. 16:27; Sm. 112:4; Lúùkù 21:28; Jòh. 8:32.)