Ibeere Lati Ọwọ́ Awọn Onkawe
◼ Joobu 33:24 sọrọ nipa “ìràpadà” ti a ri fun Joobu, ti o yọnda fun un lati yẹra fun kíkú. Ta ni ìbá jẹ ìràpadà yẹn fun Joobu?
Ko si ẹbọ ìràpadà ẹda-eniyan kankan ti a pese fun Joobu lẹ́hìn náà lọ́hùn-ún, ṣugbọn Ọlọrun bò, tabi dariji àṣìṣe Joobu.
Satani fa ọpọlọpọ ìyọnu fun Joobu, títíkan “oówo kíkankíkan lati àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ lọ dé àtàrí rẹ.” Ipo Joobu buru tobẹẹ gẹẹ ti iyawo rẹ rọ̀ọ́ ki o “bu Ọlọrun ki o si ku.” Ani Joobu paapaa ronu jinlẹ lori boya ikú dara ju iru ijiya bẹẹ lọ.—Joobu 2:7-9; 3:11.
Nigba ti o jọ pe Joobu lè kú, Elihu diyele ipo elewu Joobu o si fi ìpìlẹ̀ fun ìrètí lélẹ̀ ni wiwipe: “Ẹran ara rẹ̀ rùn, titi a kò si fi lè rii mọ; . . . Ani ọkàn rẹ sunmọ isà-òkú, ẹmi rẹ̀ si sunmọ ọdọ awọn iranṣẹ ikú. Bi ońṣẹ́ kan ba wà lọdọ rẹ̀, ẹni ti nṣe alágbàwí, ọkan ninu ẹgbẹ̀rún lati fi ọ̀nà pipe han ni; nigba naa ni o ṣoore ọfẹ fun un, o si wipe, gbà á kuro ninu ilọ sinu isà-òkú, emi ti ri ìràpadà; ara rẹ yoo si jà yọ̀yọ̀ ju ti ọmọ kekere, yoo si tun pada si ọjọ́ igba èwe rẹ.”—Joobu 33:21-25.
Awa mọ pe Jesu Kristi yọnda iwalaaye ẹda-eniyan pipe rẹ gẹgẹbi ìràpadà ṣíṣerẹ́gí fun awọn eniyan alaipe. Ẹbọ rẹ ṣe deedee pẹlu ohun ti Adamu gbé sọnù, o san iye-owo ti a nilo lati mu ìtúsílẹ̀ kúrò lọwọ ẹṣẹ wa. (Roomu 5:12-19; 1 Timoti 2:5, 6) Bi o ti wu ki o ri, eyi kì í ṣe ìlò kanṣoṣo ti “ìràpadà” ninu Bibeli. Ọrọ Heberu naa ti a ri ni Joobu 33:24 ni ìpìlẹ̀ tumọsi “fibo.” (Ẹkisodu 25:17) Nigba ti Ọlọrun nba Israẹli igbaani lo, oun ni iṣeto lati bo, tabi ṣètùtù fun, awọn ẹṣẹ—awọn ẹbọ ti o ńbò ẹṣẹ, ni mimu awọn ọ̀ràn tọ́ láàárín eniyan ati Ọlọrun.—Ẹkisodu 29:36; Lefitiku 16:11, 15, 16; 17:11.
Ṣugbọn, ni iṣaaju, Ọlọrun ti ṣetan lati gba ẹbọ gẹgẹbi ìfihànjáde ọpẹ tabi ibeere fun idariji ati ìtẹ́wọ́gbà. (Jẹnẹsisi 4:3, 4; 8:20, 21; 12:7; 31:54) Joobu loye iniyelori iru awọn ẹbọ bẹẹ. A kà pe: “O si dide ni kùtùkùtù owurọ, o si ru ẹbọ-sisun niwọn iye gbogbo [awọn ọmọkunrin rẹ]; nitoriti Joobu wipe: boya awọn ọmọ mi ti ṣẹ̀, wọn sì ti sọrọ òdì si Ọlọrun lọkan wọn. Bẹẹni Joobu maa nṣe nigbagbogbo.” (Joobu 1:5) Niwọnbi oun ti gbiyanju lati wu Ọlọrun ti ó sì daju pe oun ni ẹmi ìròbìnújẹ́, awọn ẹbọ rẹ niyelori niwaju Ọlọrun. —Saamu 32:1, 2; 51:17.
Ṣugbọn Joobu lẹhin naa jẹrora aisan ti o jọ bi ẹnipe o halẹ̀ mọ́ iwalaaye rẹ̀. Oun tun ni oju-iwoye ti ko tọna nipa iwa-ododo rẹ, nitori naa oun nilo ibawi, eyi ti Elihu pese lẹhin naa. (Joobu 32:6; 33:8-12; 35:2-4) Elihu wipe Joobu ko nilati maa ba lọ ninu ipo ibanujẹ rẹ titi de iku ati ihò (sheol, tabi saree lapapọ). Bi Joobu yoo ba ronúpìwàdà, “ìràpadà” ni o le ri.—Joobu 33:24-28.
Awa ko nilati ronu pe nipa “ìràpadà” Elihu nii lọkan pe ẹda-eniyan kan nigba naa lọhun-un yoo ku nititori Joobu. Loju iwoye awọn ẹbọ ti awọn olujọsin tootọ ti dojúlùmọ̀ lati pese, iru ìràpadà eyi ti Elihu nsọrọ ba ni ọran ti Joobu le ti jẹ irubọ ẹran kan. O fani lọkan mọra pe, Ọlọrun sọ fun awọn alariiwisi ẹlẹgbẹ Joobu mẹta lẹhin naa pe: “Ki ẹ ru ẹbọ sisun fun ara yin; Joobu iranṣẹ mi yoo si gbadura fun yin.” (Joobu 42:8) Ọna yoowu ki a gba ṣe ìràpadà naa, lajori kókó Elihu ni pe Joobu ni a le bo aṣiṣe rẹ ki o si niriiri àǹfààní ti o nti inu rẹ jade.
Ohun ti o ṣẹlẹ niyẹn. Joobu “ronupiwada ninu ekuru ati eérú.” Lẹhin naa ki ni? “Oluwa [“Jehofa,” NW] sì yí ìgbèkùn Joobu pada, . . . bẹẹni Oluwa [“Jehofa,” NW] bukun igbẹhin Joobu ju iṣaaju rẹ̀ lọ; . . . lẹhin eyi Joobu wa ní ayé ni ogoje ọdun, o si ri awọn ọmọ rẹ ọkunrin ati awọn ọmọ-ọmọ rẹ ọkunrin, ani iran mẹrin.” Ki a gba bẹẹ pe ìràpadà kò tú Joobu silẹ ni ominira kuro lọwọ ẹṣẹ, nitori naa nigba ti ó ya ó ku. Sibẹ, ẹmi rẹ̀ ti o tubọ gun fi ẹri han pe lọna ti o gbeṣẹ, ‘ara rẹ jàyọ̀yọ̀ ju ti ọmọ kekere, oun si tun pada si ọjọ igba ewe rẹ.’—Joobu 33:25; 42:6, 10-17.
Awọn ibukun wọnni ti wọn wa lati inu fifi ìràpadà ti o ni aala silo fun Joobu ṣiṣẹ gẹgẹbi aworan iṣaaju fun awọn ibukun pupọ yanturu ti yoo wa fun araye onigbagbọ ninu aye titun. Nigba naa, anfaani kikun ti ẹbọ ìràpadà Jesu yoo wà lárọ̀ọ́wọ́tó, yoo mu ipa onijaaba tí ẹṣẹ ati àìpé ní kuro titi lae. Iru idi wo ni awa yoo ni fun “ikigbe alayọ,” gẹgẹbi Elihu ti sọ!—Joobu 33:26.