‘Awọn Àjàkálẹ̀-Àrùn Lati Ibikan Sí Ibomiran’
AWỌN àjàkálẹ̀-àrùn ni iwọn ti kò lẹgbẹ jẹ́ apakan “ami wiwa nihin-in [Jesu Kristi] ati ti opin eto igbekalẹ awọn nǹkan” ti a ti sọtẹlẹ. (Matiu 24:3, NW) Luuku onkọwe Ihinrere naa fi kulẹkulẹ yii ti a kò mẹnukan ninu akọsilẹ ti Matiu ati Maaku kun un. (Matiu, ori 24 ati 25; Maaku, ori 13) Ibẹsilẹ àrùn ti ńgbèèràn ati awọn àrùn apanirun yoo ṣẹlẹ “lati ibikan sí ibomiran” ni awọn ọjọ ikẹhin. (Luuku 1:3; 21:11, NW) Lati ibo ni iru awọn àrùn bẹẹ ti lè wa?
“Awọn onimọ ijinlẹ mọ awọn kokoro fairọsi melookan ti wọn farasin ni awọn ilẹ oloooru ti ó jẹ́ pe—pẹlu iranlọwọ diẹ lati ọdọ ìṣẹ̀lẹ̀ adanida—wọn lè ṣokunfa ipadanu ẹmi pupọ sii ju bi iyọrisi ti ó ṣeeṣe lati inu àrùn AIDS ti ńgbèèràn yoo ti ṣe,” ni iwe irohin naa Science News wi. “Bi akọsilẹ iye kokoro fairọsi aye kò bá tilẹ ni afikun sii mọ́, awọn aṣewadii wi pe, awọn ilẹ oloooru ní ‘agbara ìṣọṣẹ́’ lati run ipin titobi ninu awọn eniyan ti ngbe ori ilẹ-aye.”
Ohun ti ó sọ tiwa di sanmani kan ti a ṣí silẹ si ewu pupọ sii ni iye awọn eniyan ti ngbe ilẹ-aye ti wọn nyara kánkán pọ sii ati awọn aini titobi ju ti aye ti eniyan ti kún fọ́fọ́. “Itan fihan pe ibẹsilẹ kokoro fairọsi ti nhalẹ mọ iwalaaye ti saba maa ntẹle e nigba ti awọn eniyan ba ṣí lọ sinu ilẹ ti a kò gbé rí tabi nigba ti awọn ipo gbigbe ninu ilu nla ba jó rẹhin ní awọn ọna ti nṣokunfa ogidigbo kokoro fairọsi titun,” ni iwe irohin Science News sọ. Bi awọn eniyan ti ńrọ́ wọnu agbegbe ti o ni kokoro fairọsi tí kò ṣee wọ̀ ni iṣaaju, àrùn kokoro fairọsi titun ti ńgbèèràn ni ó saba maa ntẹle e. Ohun kan naa ni ó nṣẹlẹ bí awọn kokoro ti nmu agbegbe wọn gbooro sii nigba ti irisi oju ọjọ yika aye bá yipada. “Ni afikun,” iwe irohin naa wi pe, “awọn ọgbọn imọ ẹrọ iṣegun ode oni bii ifajẹsinilara ati yiyọ ẹya ara sira ti pese ọna atagba titun fun awọn kokoro fairọsi laaarin awọn eniyan ti wọn ni kokoro naa lara. Bẹẹ ni oniruuru awọn iyipada ti ẹgbẹ oun ọgba ati ti iwahihu ti ṣe pẹlu, lati ori irin ajo jakejado laaarin awọn ọlọrọ ati gbajúmọ̀ eniyan dori iṣajọpin abẹrẹ kan naa laaarin awọn ti wọn ti sọ ogun di baraku.”
“Itan lọ́ọ́lọ́ọ́ pese awọn apẹẹrẹ ti ó han gbangba nipa gidigbo pẹlu kokoro fairọsi ni awọn agbegbe àdádó ti ó lè duro fun awọn ibẹsilẹ gbigbooro sii ni ọjọ ọla,” ni ọrọ-ẹkọ naa fikun un. Awọn apẹẹrẹ ni: kokoro fairọsi Marburg ti a kò mọ̀ ṣaaju naa, kokoro fairọsi aṣekupani ti ilẹ oloooru ti ó pọ́n ọpọ awọn onimọ ijinlẹ lójú ni West Germany ni ipari awọn ọdun 1960; kokoro fairọsi ti nṣokunfa ibà Rift Valley ti ó ran araadọta ọkẹ ti ó sì pa ẹgbẹẹgbẹrun ni Ijibiti ni 1977; kokoro fairọsi Ebola ti ilẹ oloooru ti ó ran ohun ti ó ju ẹgbẹrun kan awọn eniyan ni Zaire ati Sudan ni 1976 ti ó sì pa nǹkan bi 500, ọpọlọpọ ninu wọn jẹ́ awọn dokita ati nọọsi ti nṣetọju awọn ojiya ipalara rẹ̀.
Awọn igbejakoni kokoro fairọsi apanirun ni a kii saba lè sọtẹlẹ ṣaaju. “Fun apẹẹrẹ, ni 1918, irú àrùn gágá kan tí nyara gbeeran lọna ti nṣekupani ti o jẹ́ eyi ti nkọlu eniyan ni pataki tankalẹ yika agbaye, ni pipa awọn eniyan ti a diwọn iye wọn si 20 million,” ni iwe Science News wi. “Lẹnu aipẹ yii, ìrújáde kokoro fairọsi kan ti o dabii pe o ti figba kan jẹ́ ti kiki awọn ọbọ Africa bá aye ni ẹ̀jafùú lẹẹkansii. Kokoro fairọsi àrùn AIDS ti ran 5 million si 10 million awọn eniyan ni awọn ilẹ orilẹ-ede 149 nisinsinyi, gẹgẹ bi awọn idiyele Eto-ajọ Ilera Agbaye ti fihan. Ṣugbọn laika gbogbo afiyesi ti ìyọnu ajakalẹ lọ́ọ́lọ́ọ́ julọ yii ti fà, awọn ohun ti ndayafoni lọna pupọ ju nduro dè wá, ọpọ awọn onimọ ijinlẹ nipa kokoro àrùn fairọsi bẹru.”
Bi awọn ajakalẹ àrùn ti ndanilaamu tó, wọn jẹ́ apakan ami alapa pupọ ti wiwa nihin-in Jesu ninu ogo Ijọba, papọ pẹlu iru awọn apá ẹ̀ka gẹgẹ bi ogun, ìyàn, ati awọn isẹlẹ nla. (Maaku 13:8; Luuku 21:10, 11) Awọn apá ẹ̀ka naa tun jẹ́ idi fun ayọ, nitori Luuku fi kun awọn ọrọ Jesu pe: “Ṣugbọn nigba ti nǹkan wọnyi ba bẹrẹ sii ṣẹ, njẹ ki ẹ wo oke, ki ẹ sì gbé ori yin soke; nitori idande yin kù sí dẹdẹ.”—Luuku 21:28.