Awọn Olupokiki Ijọba Rohin
Kikari Ipinlẹ Àdádó Ni Paraguay Mú Eso Jade
Ẹ̀KA Watch Tower Society ni Paraguay mọ̀ aini naa lati waasu ihinrere Ijọba naa ni gbogbo ipinlẹ rẹ̀ lẹkun-un-rẹrẹ. (Iṣe 1:8) Akoko niyi fun gbogbo eniyan lati kọ́ nipa Ijọba naa ati lati ṣiṣẹsin Jehofa ṣaaju ki o tó mú opin wá si eto igbekalẹ buburu yii ninu “ipọnju ńlá” ti ń bọ̀. (Matiu 24:21, 22) Iriri ti o tẹle e yii fi ohun ti a ń ṣe lati ran awọn eniyan ti wọn wà ninu ipinlẹ ti a kò pín funni lọwọ. Ẹ̀ka naa rohin pe:
Awọn iṣeto ni a ṣe lati kárí gbogbo ipinlẹ ti a kò pín funni nipasẹ awọn aṣaaju-ọna akanṣe onigba kukuru. Laaarin oṣu November titi dé January ti ọdun iṣẹ-isin 1990, awọn arakunrin ati arabinrin 39 kárí aropọ ọgọrun-un ilu ati awọn ìletò keekeeke nibi ti awọn akede Ijọba kankan kò tii sí sibẹsibẹ. Ó ṣeeṣe fun wọn lati pín 6,119 iwe, 4,262 iwe pẹlẹbẹ, ati 5,144 iwe irohin kiri. Gẹgẹ bi iyọrisi igbokegbodo yii, awujọ titun ti awọn akede ni a ti dá silẹ.
◻ Obinrin kan gba iwe Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye lọwọ arabinrin Aṣaaju-ọna kan ti ń ṣiṣẹ ninu ipinlẹ ti a kò pín funni. Aṣaaju-ọna naa fi imuratan lati dari ikẹkọọ Bibeli pẹlu rẹ̀ hàn, ó sì fi tayọtayọ gbà. Nigba ti aṣaaju-ọna naa pada dé, kì í ṣe obinrin naa nikan ni ó ń duro dè é ṣugbọn ọkọ rẹ̀ ati awọn ọmọ rẹ̀ mẹwaa pẹlu. Nigba ibẹwo ti o tẹle e, idile naa ati awọn ọ̀rẹ́ ati aladuugbo wọn ti ṣetan fun ikẹkọọ Bibeli naa! Obinrin naa ti ké sí wọn, ni sisọ pe ikẹkọọ naa dara ati pe ireti ati awọn ibukun ti Jehofa fi funni jẹ́ agbayanu. Eyi jẹ́ ohun kan ti ẹnikẹni kò tii sọ fun un rí ṣaaju, nitori naa ó nimọlara pe awọn aladuugbo ati ọ̀rẹ́ rẹ̀ gbọdọ gbọ́ ihinrere yii.
Ni gbogbo ìgbà ti aṣaaju-ọna naa bá dari ikẹkọọ naa, ọpọlọpọ ni ó ń wà nibẹ debi pe o dabi ìjọ kekere kan. Awọn olufifẹhan wọnyi beere ọpọlọpọ awọn ibeere wọn sì lọwọ ninu ikẹkọọ naa. Nigba ti aṣaaju-ọna naa sọ pe gbàrà ti ipinlẹ naa bá ti di ṣiṣe pari, oun yoo ṣí lọ pẹlu awọn alabaakẹgbẹ oun si agbegbe titun, obinrin naa fi idaamu ọkàn beere oun ti yoo ṣẹlẹ si awọn. Wọn ṣeto pẹlu awọn ará lati ijọ ti o sunmọtosi julọ lati maa bá ikẹkọọ naa lọ. Nisinsinyi awọn aṣaaju-ọna ni a ti yàn lati ran awọn olufifẹhan, awọn eniyan bii agutan wọnyi lọwọ.
◻ Nigba ti o ń lọ lati ile de ile ni ipinlẹ ti a kó pín funni miiran, arabinrin aṣaaju-ọna kan rí ọkunrin kan ti o ti gba iwe Otitọ ti Nsinni Lọ si Iye Aiyeraiye ni nǹkan bí ọdun mẹwaa ṣaaju. Lati ìgbà yẹn ó ti padanu gbogbo ifarakanra pẹlu Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Bi o ti wu ki o ri, ó mọ̀ pe Jehofa, ẹni ti ó pè ni Jehofa awọn ọmọ-ogun, ni Ọlọrun tootọ kanṣoṣo naa ati pe Oun nikan ni a nilati jọsin. Pẹlu ìdánúṣe araarẹ, ó ti ń sọrọ nipa Jehofa fun gbogbo eniyan ti ó mọ̀. Niti tootọ, lọsọọsẹ ó ń rin ibusọ meji lati bẹ tọkọtaya olufifẹhan kan wò lati sọrọ nipa Ọlọrun fun wọn nitori pe, gẹgẹ bi ó ti sọ ọ́, ‘Bi mo bá dáwọ́ bíbẹ̀ wọ́n wò duro, wọn yoo gbagbe nipa Jehofa.’ Ni afikun si tọkọtaya ti o ti ṣegbeyawo yii, awọn bii mẹwaa miiran wà ti wọn fẹ́ ikẹkọọ Bibeli—gbogbo rẹ̀ nitori pe olufifẹhan yii ti waasu fun wọn.
Lọna pípẹtẹrí, ní ohun ti ó wulẹ jẹ́ iwọnba ọjọ diẹ ṣaaju ki aṣaaju-ọna naa tó ṣe ikesini sọdọ rẹ̀, ọkunrin yii kan naa kò jẹ́ ki alufaa adugbo ati awọn èrò ti wọn tò tẹle e wọnu ile pẹlu ère wundia kan, ni ṣiṣalaye pe oun kò gbagbọ ninu awọn ère. Alufaa naa gbanájẹ. Ni alẹ́ ọjọ yẹn ọkunrin naa gbadura si Jehofa fun iranlọwọ. Iwọ lè finuro bi ó ti kún fun idunnu ati ayọ tó nigba ti aṣaaju-ọna naa dé! Lọ́gán ni wọn ṣeto fun ikẹkọọ Bibeli oní-sísẹ̀-n-tẹ̀le e, ọkunrin naa sì ń baa lọ lati tẹsiwaju ninu ibakẹgbẹ pẹlu eto-ajọ ti iṣakoso Ọlọrun.
Loootọ, Jehofa ń bukun iṣẹ ìkórèwọlé ni Paraguay bi awọn ará ti ń ṣakun lati funni ni ijẹrii kúnnákúnná ni awọn ipinlẹ ti a kò pín funni wọnyi.—Matiu 24:14.