Ibeere Lati Ọwọ́ Awọn Òǹkàwé
Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ha yẹra fun ṣiṣayẹyẹ ọjọ ibi nitori pe aṣa naa ni ero-itumọ ti isin ni awọn akoko igbaani bi?
Ṣiṣayẹyẹ ọjọ ibi pilẹṣẹ ninu igbagbọ ninu ohun asan ati isin eke, ṣugbọn iyẹn kọ́ ni kiki tabi lajori idi ti Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa fi yẹra fun aṣa naa.
Awọn àṣà-ìṣẹ̀dálẹ̀ kan ti o figbakanri jẹ ti isin kò jẹ bẹẹ mọ ni ọpọlọpọ ibi. Fun apẹẹrẹ, oruka igbeyawo ni ijẹpataki ti isin nigba kan ri, ṣugbọn ni ibi pupọ lonii, ko ri bẹẹ mọ́. Fun idi yii ọpọlọpọ awọn Kristian tẹwọgba àṣà-ìṣẹ̀dálẹ̀ adugbo naa ti wíwọ oruka igbeyawo lati fi ẹri han pe ẹnikan ti ṣegbeyawo. Ni iru awọn ọran bẹẹ, ohun ti ń nipa lee lori ni boya aṣa kan ni a sopọ mọ ijọsin eke nisinsinyi.—Wo “Ibeere Lati Ọwọ́ Awọn Òǹkàwé” ninu llé-Ìṣọ́nà January 15, 1972 (Gẹẹsi), ati October 15, 1991.
Bi o ti wu ki o ri, ko si sísẹ́ pe ọpọlọpọ awọn iwe atọka ṣipaya igbagbọ ninu ohun asan ati iṣe ijọsin atẹhinwa ti o wà ninu ṣiṣayẹyẹ ọjọ ibi. Iwe agbédègbẹ́yọ̀ The Encyclopedia Americana (ẹ̀dà ti 1991) ṣakiyesi pe: “Ayé Egipti, Giriki, Romu, ati Persia igbaani ṣayẹyẹ ọjọ ìbí awọn ọlọrun, awọn ọba ati awọn ọtọkulu.” O sọ pe awọn ara Romu ṣakiyesi ìbí Artemis ati ọjọ Apollo. Ni iyatọ ifiwera, “bi o tilẹ jẹ pe awọn ọmọ Isreali igbaani pa akọsilẹ ọjọ ori awọn ọmọkunrin ibilẹ wọn mọ́, ko si ẹri kankan pe wọn ṣe ajọdun eyikeyii ni ayajọ ọjọ ibi naa.”
Awọn iwe atọka miiran ṣe ọpọlọpọ alaye ẹkunrẹrẹ nipa ipilẹṣẹ ayẹyẹ ọjọ ibi: ‘Apejẹ ọjọ ibi bẹrẹ ni Europe ni awọn ọdun diẹ sẹhin. Awọn eniyan gbagbọ ninu ẹmi buburu ati rere, ti a ń pe nigba miiran ni iwin rere ati buburu. Olukuluku ni ń bẹru awọn ẹmi wọnyi, pe wọn yoo ṣepalara fun alaṣeyẹ ọjọ ibi naa, nitori naa awon ọrẹ ati mọlẹbi yi i ká awọn ẹni ti idaniyan fun ire, ati wiwa nibẹ wọn, yoo daabobo o kuro lọwọ awọn jamba ti a ko mọ̀ ti ọjọ ibi naa mu lọwọ. Fifun un ní ẹbun tilẹ mu ki aabo naa tubọ nipọn. Jijẹun papọ pese aabo siwaju sii ti o si ṣeranwọ lati mu ọpọlọpọ ibukun awọn ẹmi rere wọle wá. Nitori naa apẹjẹ ọjọ ibi ni a pete ni ipilẹ lati mu ki ẹnikan yebọ lọwọ ibi ati lati rii daju pe ọdun rere ń bọ̀ lọna.’—Birthday Parties Around the World, 1967.
Iwe naa ṣalaye nipa ipilẹṣẹ ọpọ awọn aṣa ọjọ ibi, pẹlu. Fun apẹẹrẹ: “Idi [fun lilo awọn àbẹ́là] lọ jìnnà sẹhin si ọdọ awọn Griki ati Romu ijimiji awọn ẹni ti wọn gbagbọ pe “awọn àbẹ́là” ni awọn agbara idán. Wọn yoo gba awọn adura ati ìdáníyàn eyi ti ọmọ-ina awọn àbẹ́là naa yoo gbé lọ sọdọ awọn ọlọrun. Lẹhin naa awọn ọlọrun naa yoo da awọn ibukun wọn jade ati boya ki wọn dahun awọn adura naa.” Iru awọn isọfunni ipilẹ miiran ni a kojọ si awọn oju-iwe 69 si 70 iwe Reasoning From the Scriptures, ti a tẹ̀ lati ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.
Bi o ti wu ki o ri, gẹgẹ bi a ti mẹnuba a ohun pupọ ni ibeere yii ní ninu ju boya ṣiṣayẹyẹ ọjọ ibi ti jẹ tabi o si jẹ ti isin sibẹ. Bibeli mu ọran ọjọ ibi wa sojutaye, awọn Kristian adagbadenu si fi pẹlu ọgbọn kiyesara nipa itọka eyikeyii ti o fi funni.
Awọn iranṣẹ Ọlọrun igba atijọ ṣakọsilẹ igba ti a bi ẹnikọọkan, eyi ti o ran wọn lọwọ lati le ṣe iṣiro ọjọ ori. A ka pe: “Noa si jẹ ẹni ẹẹdẹgbẹta ọdun: Noa si bi Ṣemu, Hamu, ati Jafeti.” “Ni ẹgbẹta ọdun ọjọ ayé Noa, . . . ni gbogbo isun ibú nla ya.”—Genesisi 5:32; 7:11; 11:10-26.
Gẹgẹ bi Jesu ti mẹnuba a paapaa, laaarin awọn eniyan Ọlọrun ibi ọmọ jẹ iṣẹlẹ alayọ, onibukun kan. (Luku 1:57, 58; 2:9-14; Johannu 16:21) Sibẹ, awọn eniyan Jehofa ko ṣayajọ ọjọ ibi; wọn pa awọn ajọdun miiran mọ́ ṣugbọn kì í ṣe ọjọ ibi. (Johannu 10:22, 23) Iwe agbédègbẹ́yọ̀ Encyclopaedia Judaica sọ pe: “Ṣiṣayẹyẹ ọjọ ibi jẹ ohun ti a ko mọ̀ ninu aato-aṣa atọwọdọwọ awọn Ju.” Iwe Customs and Traditions of Israel ṣakiyesi pe: “Ṣiṣayẹyẹ ọjọ ibi ni a yá lati ọdọ aṣa awọn orilẹ-ede miiran, niwọn bi a ko ti mẹnuba aṣa yii laaarin awọn Ju yala ninu Bibeli, tabi Talmud, tabi akọsilẹ awọn ọkunrin ọlọgbọn lẹhin naa. Niti tootọ, o jẹ aṣa awọn ara Egipti igbaani.”
Isopọ yẹn pẹlu awọn ara Egypti ṣe kedere lati inu ayẹyẹ ọjọ ibi ti Bibeli rohin, eyi ti awọn olujọsin tootọ kii ṣayẹyẹ rẹ̀. Ó jẹ àsè ọjọ ibi Farao ti o ń ṣakoso nigba ti Josẹfu wà ninu tubu Egipti. Diẹ lara awọn aboriṣa yẹn ti le layọ lori àsè naa, sibẹ ọjọ ibi naa ni a sopọ mọ́ gige ori olori awọn alase Farao. —Genesisi 40:1-22.
Ayẹye ọjọ ibi miiran ti a ṣalaye rẹ̀ ninu Iwe Mimọ ni a fihan lọna aidara—ti Herodu Atipas, ọmọ Herodu Nla. Dajudaju a ko fi ayẹyẹ ọjọ bi yii han ninu Bibeli gẹgẹ bi ajọdun alailẹṣẹ. Kaka bẹẹ, o ṣokunfa bibẹ ori Johannu Arinibọmi. Nigba naa, “awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si wá wọn gbé oku rẹ̀ sin, wọn si lọ, wọn si wi fun Jesu,” ‘ẹni ti o dide kuro nibẹ lọ si ibi iju, oun nikan.’ (Matteu 14:6-13) Iwọ ha le rò pe awọn ọmọ-ẹhin wọnni tabi Jesu nimọlara ifamọra si aṣa ṣiṣayẹyẹ ọjọ ibi bi?
Loju-iwoye mimọ ipilẹṣẹ ṣiṣayẹyẹ ọjọ ibi, ati eyi ti o ṣe pataki ju, ọna didara ti a gbà fi gbé wọn yọ ninu Bibeli, Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni idi ti o pọ̀ to lati fasẹhin kuro ninu aṣa naa. Kò pọndandan fun wọn lati tẹ̀lé aṣa ayé yii, nitori wọn lè wọn si ń jẹ àsè alayọ nigbakuugba laaarin ọdun. Fifunni ni ẹbun wọn kì í ṣe ọran aigbọdọmaṣe tabi labẹ ikimọlẹ ti apejẹ; o jẹ ti ṣiṣajọpin awọn ẹbun lati inu wa ni akoko eyikeyii lati inu iwa ọlawọ ati ojulowo ìdaníyàn.—Owe 17:8; Oniwasu 2:24; Luku 6:38; Iṣe 9: 36, 39; 1 Korinti 16:2, 3.