Awọn Olupokiki Ijọba Rohin
Isọnidominira Nipa Tẹmi Ni Colombia
LATI akoko awọn ajagun-ṣẹgun ti ilẹ̀ Spain, isin Katoliki ti ni agbara-idari lori isin lọna lilagbara ni Guusu America. Ni Colombia oun ni o ti jẹ isin ti Ijọba faṣẹsi fun orilẹ-ede naa. Lati ọdun 105 sẹhin, Vatican ti fọwọsi adehun imulẹ pẹlu ijọba ilẹ Colombia eyi ti o daabobo ṣọọṣi naa ti o si fun un ni awọn akanṣe anfaani ninu pápá ti ẹkọ-iwe ati igbeyawo.
Ni December 1990 awọn ará Colombia yan àjọ igbimọ kan lati gbe awọn ofin ipilẹ titun kan kalẹ, eyi ti a pari rẹ̀ ni ìdajì ọdun 1991. Ofin ipilẹ titun naa yí ipo tí isin wà ni Colombia pada. Gbogbo isin ti wá ni ẹtọ kan-naa labẹ ofin nisinsinyi, ti a kò si lè fi tipátipá kọ́ awọn ọmọ lẹkọọ isin mọ́ ni awọn ilé-ẹ̀kọ́ gbogbogboo. Adehun imulẹ pẹlu Vatican ti yẹ fun atungbeyẹwo ni fifi awọn iyipada ninu ofin ipilẹ wọnyi sọkan.
Ominira isin ti o ga jù yii yoo din agbara-idari ti Ṣọọṣi Katoliki kù, ni mimu ki o tubọ rọrun fun awọn olotiitọ-ọkan lati jere imọ Bibeli ati lati ri ominira nipa tẹmi gbà.
Ni ifojusọna fun isọnidominira nipa tẹmi yii, 51,000 awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti wọn wà ni orilẹ-ede naa ti ń ṣe imurasilẹ fun bibojuto awọn olùwá-ibi-ìsádi nipa tẹmi. Awọn ilé alasokọra ti orile-iṣẹ wọn titun ti o ni awọn ohun eelo ti a mú gbooro sii, ti o ni ninu ẹ̀rọ ìtẹ̀wé alátẹ̀yípo ayára-bí-àṣá tí ń mú iwe aláwọ̀ àràbarà jade, ni a ti fẹrẹẹ pari. Awọn aṣaaju-ọna akanṣe fun ìgbà diẹ ni a ti rán lọ sinu awọn ìlú keekeeke, lati wá awọn agutan Jehofa ti wọn ti sọnu rí ti wọn si ti ṣe aṣeyọri agbayanu ninu iṣẹ́ ikọnilẹkọọ Bibeli. Ni awọn ilu 63, ti ọkọọkan wọn ni nǹkan bii 10,000 olùgbé, awọn ijọ ati awujọ titun 47 ni a ti dásílẹ̀.
Bi ẹmi Jehofa ti ń baa lọ lati sun awọn eniyan olotiitọ-ọkan ṣiṣẹ́, ọpọ awọn èwe ni wọn ń dahunpada pẹlu. Itẹjade naa Questions Young People Ask—Answers That Work ti jasi aranṣe alaiṣeediyele fun awọn ọ̀dọ́ eniyan ati awọn òbí wọn lapapọ. Bi ó ti ń lọ lati ẹnu-ọna si ẹnu-ọna, Ẹlẹ́rìí kan ṣalabaapade ọkunrin kan ti o ti ka ipin diẹ ninu iwe yii, ẹ̀dà kan eyi ti aladuugbo rẹ̀ kan yá a. Ọgbọ́n gbigbeṣẹ ti o fihàn bi o ti ń jiroro awọn iṣoro idile wú u lori gidigidi. Ori 4, “Why Did Dad and Mom Split Up?” (Eeṣe Ti Baba ati Mama Fi Pínyà?) wu u lori ni pataki, niwọn bi oun ati aya rẹ̀ ti wà ni gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ pipinya. O sọ pe iwe naa gba oun là kuro lọwọ jàm̀bá wiwuwo kan. Nisinsinyi oun pẹlu idile rẹ̀ ń kẹkọọ Bibeli pẹlu awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti wọn si ń wá si gbogbo awọn ipade ijọ. Wọn kun fun ọpẹ́ fun ọgbọ́n ti o gbeṣẹ ti Jehofa ń pese nipasẹ Bibeli ati eto-ajọ rẹ̀.
Iriri yii ṣapejuwe isọnidominira nipa tẹmi naa ti ń ṣẹlẹ ni Colombia bi awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti ń ran awọn ti ebi ń pa nipa tẹmi lọwọ lati kẹkọọ nipa awọn ète ati ayé titun agbayanu ti Jehofa, ti o kù si dẹdẹ nisinsinyi.—2 Peteru 3:13.