Ẹ Yọ̀ Ninu Ilẹ̀-ayé mímọ́ Tonitoni Ti Ó Wà Niwaju!
ATI kún fun ayọ tó pe Jehofa, Ọlọrun eto ati imọtoto, yoo mú ète rẹ̀ ipilẹṣẹ lati sọ ilẹ̀-ayé di paradise agbaye kan ṣẹ! (Isaiah 11:6-9) Ó ṣeleri pe: “Bẹẹ ni ọ̀rọ̀ mi ti ó ti ẹnu mi jade . . . kì yoo pada sọdọ mi lófo, ṣugbọn yoo ṣe eyi ti ó wù mí, yoo sì maa ṣe rere ninu ohun ti mo rán an.” “Kò lè ṣeeṣe fun Ọlọrun lati ṣèké,” nitori naa iwọnyi kìí ṣe òfìfo ọ̀rọ̀.—Isaiah 55:11; Heberu 6:18.
Ara lè tù wá pe Jehofa yoo fi ifẹ dá sí i ki awọn eniyan tó fa ìsọdèérí pupọ tobẹẹ gẹẹ debii pe iwolulẹ ibugbe ohun alaaye patapata ni a kì yoo lè dá duro!—Ìfihàn 11:18.
Jehofa yoo mú awọn olùsọ-nǹkàn-deléèérí alaironupiwada, alailakooso ati awọn eniyan ti wọn fi iṣọtẹ ṣaika awọn itọni eto ati imọtoto rẹ̀ sí kuro. Kò sí ẹni ti a o gbà láàyè lati fi Paradise ti a mupadabọsipo naa sinu ewu.—Owe 2:20-22.
Nigba iṣakoso Ijọba Ọlọrun, labẹ itọsọna Kristi Jesu, awọn eniyan ni a ó kọ́ ni bi a ṣe lè fa gbòǹgbò awọn okunfa ìsọdèérí nipa ti ara tí ó kù tu. Nigba naa—kìí ṣe nisinsinyi—ni yoo jẹ́ akoko ti ó bojumu pe ki gbogbo iranṣẹ Ọlọrun fi taratara lọwọ ninu iṣeto ti ara-ẹni ati ti apapọ eyi ti yoo fikun ìpalẹ̀-ìdọ̀tí-mọ́ kari ayé alailafiwe kan.—Fiwe Esekieli 39:8-16.
Awọn olula opin eto-igbekalẹ awọn nǹkan buburu isinsinyi já yoo ṣetilẹhin fun itolẹsẹẹsẹ pípalẹ̀-ìdọ̀tí-mọ́ niti ara yii pẹlu ifọkansin ati ìtara kan-naa ti wọn fi lọwọ ninu igbetaasi pípalẹ̀-ìdọ̀tí-mọ́ tẹmi ti sanmani ti a wà yii.—Orin Dafidi 110:3.
Ilẹ̀-ayé kan ti o mọ́ tonitoni ni ó daju pe yoo dé, ṣaaju eyi ti igbetaasi pípalẹ̀-ìdọ̀tí-mọ́ giga julọ ti a tii rí rí, ti Ijọba Ọlọrun ṣe aṣepari rẹ̀ yoo waye. Gbogbo ami ìsọdèérí ni a o mú kuro. Kò ni sí aworan ara ogiri nibikibi mọ́. Kò sí awọn àfọ́kù ìgò, agolo, àpò ọlọ́ràá, bébà ṣingọọmu ati ti ipapanu olóyinmọmọ, iwe agberohinjade ati iwe-irohin mọ́ lati sọ etikun tabi agbegbe oniparadise eyikeyii di onipantiri.
Ẹ yọ̀ ninu ilẹ̀-ayé mímọ́ tonitoni ti ó wà niwaju!
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Iwọ yoo ha lọwọ ninu ìpalẹ̀-ìdọ̀tí-mọ́ kari-aye ti ń bọ̀ bi?