‘Àmì kan Lati Ọ̀run Wá’
EWÌ adúnbárajọ kan kà pe: “Oju ọ̀runpupa lálẹ́, mú ayọ awọn atukọ̀ búrẹ́kẹ́,/Oju ọ̀run pupa lówùúrọ̀, jẹ́ ikilọ fun awọn atukọ̀.” Lonii, awọn satellite, ikẹkọọ ìgbóná-ìtutù oju-ọjọ ti a ń fi ẹ̀rọ kọmputa mú sunwọn sii, Doppler radar, ati awọn ọ̀nà ti imọ-ijinlẹ miiran ni a ń lò lati sọ asọtẹlẹ ipò-ojú-ọjọ́. Awọn isọtẹlẹ sábà maa ń bá ewì adúnbárajọ ti a ṣẹṣẹ ṣàyọlò ọ̀rọ̀ rẹ̀ tán yii mu.
Awọn ọ̀tá onisin Jesu Kristi nigba kan rí fi dandan beere lọwọ rẹ̀ fun ‘àmì lati ọ̀run wá,’ ìfihàn àrà-mérìíyìírí kan lati fihàn pe Messia ni oun. “Nigba ti ó bá di àṣálẹ́,” ni ó sọ, “ẹyin a wi pe, Ọjọ óò dara: nitori ti oju ọ̀run pọ́n. Ati ni owurọ ẹyin a wi pe, Ọjọ kì yoo dara lonii, nitori ti oju ọ̀run pọ́n, ó sì ṣú dẹdẹ. A! ẹyin agabagebe, ẹyin lè mọ àmì oju ọ̀run; ṣugbọn ẹyin kò lè mọ àmì akoko wọnyi? Iran buburu ati panṣaga ń fẹ́ àmì; a kì yoo sì fi àmì fun un, bikoṣe àmì ti Jona wolii.”—Matteu 16:1-4.
Awọn ọ̀tá Jesu lè sọ asọtẹlẹ ipò-ojúọjọ́ ṣugbọn wọn kò lè loye awọn ọ̀ràn tẹmi. Fun apẹẹrẹ, ki ni nipa “àmì ti Jona”? Lẹhin lilo nǹkan bi ọjọ mẹta ninu ikùn ẹja titobi kan, Jona wolii Ọlọrun waasu ni Ninefe ó sì tipa bayii di àmì kan fun olu-ilu Assiria. Iran Jesu ní “àmì ti Jona” nigba ti Kristi lo apakan awọn ọjọ mẹta ninu iboji kan ti a sì jí i dide. Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ polongo ẹ̀rí iṣẹlẹ yẹn, ati nipa bayii Jesu di àmì kan fun iran yẹn.—Matteu 12:39-41.
Ni akoko iṣẹlẹ miiran, awọn ọmọ-ẹhin Jesu beere “àmì wíwàníhìn-ín” rẹ̀ ọjọ-ọla ninu agbara Ijọba lọwọ rẹ̀. Ni ifesipada, ó fun wọn ní àmì ti o ní oriṣiriṣi apa ninu, papọ pẹlu awọn ogun, isẹlẹ ńláǹlà, aito ounjẹ alailẹgbẹ, ati iwaasu yika-aye nipa Ijọba Ọlọrun ti ọ̀run ti a ti fidii rẹ̀ mulẹ.—Matteu 24:3-14, NW.
Iwọ ha dá àmì wíwàníhìn-ín Kristi gẹgẹ bi Ọba ti ọ̀run ti kò ṣeefojuri mọ̀ bi? Awọn apa-iha rẹ̀ ni ó ti ń ní imuṣẹ lori iran yii. (Matteu 24:34) Ọjọ-ọla sì ń kọ́? Bibeli kò ṣipaya pe opin eto-igbekalẹ awọn nǹkan yii ti sunmọle nikan ni ṣugbọn ó tún sọ asọtẹlẹ ojumọ titun ti Ọlọrun ṣeleri eyi ti ó maa tó mọ́ kedere kèdèrè fun araye.—2 Peteru 3:13.