Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Níwọ̀n bí Jesu ti wá láti ìlà ìran Jesse àti Dafidi, èéṣe tí a fi pè é ní “gbòǹgbò” àwọn babańlá rẹ̀ Jesse àti Dafidi?
Èyí jẹ́ ìbéèrè kan tí ó mọ́gbọ́n dání, níwọ̀n bí o ti máa ń ronú nípa gbòǹgbò igi tàbí ohun ọ̀gbìn kan gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó hù ṣáájú ìtí igi tàbí àwọn ẹ̀ka igi náà. Nítorí náà yóò dàbí ẹni pé Jesse (tàbí ọmọ rẹ̀ Dafidi) ni ó yẹ kí a sọ pé wọ́n jẹ́ gbòǹgbò náà lára èyí tí Jesu ti hù jáde nígbẹ̀yìn gbẹ́yín. Síbẹ̀, Isaiah 11:10 sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé Messia tí ń bọ̀ náà yóò jẹ́ “kùkùté Jesse,” Romu 15:12 sì mú àsọtẹ́lẹ̀ yìí bá Jesu Kristi mu. Lẹ́yìn èyí Ìfihàn 5:5 pè é ní “Kìnnìún ẹ̀yà Juda, Gbòǹgbò Dafidi.” Ìdí wà fún àwọn orúkọ àfimọni wọ̀nyí.
Bibeli sábà máa ń lo ohun ọ̀gbìn, bí igi kan, lọ́nà àpèjúwe. Nígbà mìíràn èyí máa ń jẹ́rìí sí òtítọ́ náà pé irúgbìn kan ń hù ó sì ń dàgbà, gbòǹgbò ń dàgbà ṣáájú ẹ̀ka-igi, àwọn ẹ̀ka mìíràn, tàbí èso níwọ̀n bí gbòǹgbò náà ti jẹ́ orísun gbogbo wọn. Fún àpẹẹrẹ, Isaiah 37:31 kà pé: “Àti ìyókù tí ó sálà nínú ilé Juda yóò tún fi gbòǹgbò múlẹ̀ nísàlẹ̀, yóò sì so èso lókè.”—Jobu 14:8, 9; Isaiah 14:29.
Bí jàm̀bá kan bá ṣe gbòǹgbò náà, ìyókù igi náà yóò mọ̀ ọ́n lára. (Fiwé Matteu 3:10; 13:6.) Lọ́nà kan náà, Malaki kọ̀wé pé: “Ọjọ́ náà tí ń bọ̀ yóò sì jó wọn run, ni Oluwa awọn ọmọ-ogun wí, tí kì yóò fi ku gbòǹgbò tàbí ẹ̀ka fún wọn.” (Malaki 4:1) Ìtumọ̀ náà ṣe kedere—ìkékúrò pátápátá. Àwọn òbí (àwọn gbòǹgbò) ni a óò ké kúrò, àti àwọn ọmọ wọn pẹ̀lú (àwọn ẹ̀ka).a Èyí tẹnumọ́ ẹrù-iṣẹ́ bàǹtà banta tí àwọn òbí ní lórí àwọn ọmọ wọn aláìtójúúbọ́; ọjọ́ ọ̀la wíwàpẹ́títí àwọn ọmọdé aláìtójúúbọ́ ni a lè pinnu nípasẹ̀ ìdúró àwọn òbí wọn níwájú Ọlọrun.—1 Korinti 7:14.
Èdè-ọ̀rọ̀ tí a lò ní Isaiah 37:31 àti Malaki 4:1 jẹ́rìí sí òtítọ́ náà pé àwọn ẹ̀ka (àti èso tí ó wà lára àwọn ọwọ́ ẹ̀ka) gba ìwàláàyè wọn láti ọ̀dọ̀ gbòǹgbò. Èyí ni kọ́kọ́rọ́ náà sí lílóye bí Jesu ṣe jẹ́ “kùkùté Jesse” àti “gbòǹgbò Dafidi.”
Lọ́nà ti ara, Jesse àti Dafidi jẹ́ babańlá Jesu; àwọn ni gbòǹgbò, òun ni èéhù tàbí ẹ̀ka. Isaiah 11:1 sọ nípa Messia náà tí ń bọ̀ pé: “Èèkàn kan yóò sì jáde láti inú kùkùté Jesse wá, ẹ̀ka kan yóò sì hù jáde láti inú gbòǹgbò rẹ̀.” Bákan náà, ní Ìfihàn 22:16, Jesu pe ara rẹ̀ ní “irú-ọmọ Dafidi.” Ṣùgbọ́n ó tún pe araarẹ̀ ní “gbòǹgbò Dafidi.” Èéṣe?
Ọ̀nà kan tí Jesu gbà jẹ́ “gbòǹgbò” Jesse àti Dafidi ni pé nípasẹ̀ rẹ̀ ni ìlà ìdílé wọn fi wàláàyè. Kò sí ẹ̀dá ènìyàn kankan lónìí tí ó lè fi ẹ̀rí hàn pé òun jẹ́ ẹ̀yà Lefi, Dani, tàbí ti Juda pàápàá, ṣùgbọ́n a lè ní ìdánilójú pé ìlà ìran Jesse àti Dafidi ṣì wàláàyè síbẹ̀ nítorí pé Jesu wàláàyè ní ọ̀run nísinsìnyí.—Matteu 1:1-16; Romu 6:9.
Jesu tún gba ipò Ọba ọ̀run. (Luku 1:32, 33; 19:12, 15; 1 Korinti 15:25) Èyí jẹ́rìí sí ipò-ìbátan rẹ̀ pẹ̀lú àwọn babańlá rẹ̀ pàápàá. Lọ́nà alásọtẹ́lẹ̀, Dafidi pé Jesu ní Oluwa òun.—Orin Dafidi 110:1; Iṣe 2:34-36.
Lákòótán, Jesu Kristi ni a gbé agbára wọ̀ gẹ́gẹ́ bí Onídàájọ́. Láàárín Ìṣàkóso Ẹlẹ́gbẹ̀rún Ọdún tí ń bọ̀, àǹfààní ìràpadà Jesu yóò nasẹ̀ dé ọ̀dọ̀ Jesse àti Dafidi pẹ̀lú. Ìwàláàyè wọn lórí ilẹ̀ ayé nígbà yẹn yóò sinmi lé Jesu, ẹni tí yóò ṣiṣẹ́sìn gẹ́gẹ́ bí “Baba Ayérayé” wọn.—Isaiah 9:6.
Nítorí náà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Jesu wá láti ìlà ìran Jesse àti Dafidi, ohun tí ó ti jẹ́ tí yóò sì tún ṣe mú kí ó tóótun ní ẹni tí a lè pè ní “kùkùté Jesse” àti “gbòǹgbò Dafidi.”
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àkọlé ara ibojì àwọn ara Phoenicia ìgbàanì kan lo èdè-ọ̀rọ̀ kan náà. Ó sọ nípa ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣí ibojì náà pé: “Wọn kì yóò ní gbòǹgbò nísàlẹ̀ tàbí èso lókè!”—Vetus Testamentum, April 1961.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 31]
Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.