“Bí Ó Ṣe Yẹ Kí Àwọn Kristian Tòótọ́ Máa Hùwà Nìyẹn”
NÍNÚ ìwé rẹ̀ ti ọdún 1990 Arbeit macht tot—Eine Jugend in Auschwitz (Iṣẹ́ Ń Pààyàn—Ìgbà Ọ̀dọ́kùnrin ní Auschwitz), Tibor Wohl ẹnì kan tí ó yèbọ́ ní Auschwitz kọ àkọsílẹ̀ ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ kan láàárín àwọn ẹlẹ́wọ̀n ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ méjì èyí tí ó ta sí i létí. Ọ̀kan, tí ó jẹ́ ará Austria, jẹ́wọ́ pé òun jẹ́ “aláìgbàgbọ́.” Síbẹ̀, ó yin àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí wọ́n ní àmì onígun-mẹ́ta elésè àlùkò lára—àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli, gẹ́gẹ́ bí a ti ń pe àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa nínú ibùdó náà.
Ará Austria náà sọ fún ẹnì kejì rẹ̀ pé: “Wọ́n kìí lọ sógun. Wọ́n yóò gbà kí a pa wọ́n ju kí wọ́n pa ẹlòmíràn lọ. Ní ojú-ìwòye tèmi bí ó ṣe yẹ kí àwọn Kristian tòótọ́ máa hùwà nìyẹn. Mo gbọ́dọ̀ sọ fún ọ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ alárinrin kan tí mo ní ìrírí rẹ̀ pẹ̀lú wọn. A wà nínú ilé kan náà pẹ̀lú àwọn Juu àti àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli nínú ibùdó ti Stutthof. Ní àwọn ọjọ́ wọ̀nyẹn àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli níláti ṣe iṣẹ́ àfipámúniṣe, ní ìta nínú otútù nini. Kò yé wa bí wọ́n ṣe là á já. Wọ́n sọ pé Jehofa ni ó fún àwọn ní okun. Ebi búrẹ́dì tí a fún wọn ń pa wọn gidigidi, níwọ̀n bí a ti ń fi ebi jẹ wọ́n níyà. Ṣùgbọ́n kí ni wọ́n ṣe? Wọ́n gba gbogbo búrẹ́dì tí wọ́n ní jọ, wọ́n mú ìdajì nínú rẹ̀ wọ́n sì fi ìdajì tí ó kú fún àwọn arákùnrin wọn, àwọn arákùnrin wọn nípa tẹ̀mí, tí wọ́n wọlé wá láti àwọn ibùdó mìíràn pẹ̀lú ebi nínú. Wọ́n kí wọn káàbọ̀ wọ́n sì fi ẹnu kò wọ́n ní ẹnu. Ṣáájú kí wọ́n tó jẹun, wọ́n gbàdúrà, ojú wọn sì kún fún ayọ̀ lẹ́yìn náà. Wọ́n sọ pé kò sí ẹni tí ebi ń pa mọ́. Nítorí náà, ṣe o rí i, nígbà náà ni mo wá rò ó nínú ara mi pé, ‘Àwọn Kristian tòótọ́ nìwọ̀nyí.’ Nígbà gbogbo ni mo máa ń wòye pé bí ó ṣe yẹ kí wọ́n rí nìyẹn. Báwo ni ìbá ti dára tó láti fún àwọn ẹlẹgbẹ́ wa tí ń jìyà lọ́wọ́ ebi ní irú ìkíni káàbọ̀ bẹ́ẹ̀ ní Auschwitz níbí!”