A Ha Sọ Àsọdùn Nípa Ọrọ̀ Ọba Sólómọ́nì Bí?
“Ìwọ̀n wúrà tí ó ń dé ọ̀dọ̀ Sólómọ́nì ní ọdún kan, jẹ́ ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀ta ó lé mẹ́fà tálẹ́ńtì.”—Àwọn Ọba Kìíní 10:14.
GẸ́GẸ́ bí ẹsẹ Bíbélì yìí ṣe sọ, Ọba Sólómọ́nì ń kó iye tí ó ju tọ́ọ̀nù 25 wúrà jọ ní ọdún kan ṣoṣo! Lónìí, èyí yóò jẹ́ 240,000,000 dọ́là. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìlọ́po méjì wúrà tí a wà lágbàáyé ní ọdún 1800. Èyí ha ṣeé ṣe bí? Kí ni ẹ̀rí àwọn awalẹ̀pìtàn fi hàn? Ó fi hàn pé, dájúdájú àkọsílẹ̀ Bíbélì nípa ọrọ̀ Sólómọ́nì bọ́gbọ́n mu. Ìwé ìròyìn Biblical Archaeology Review sọ pé:
◻ Ọba Thutmose Kẹta ti Íjíbítì (ẹgbẹ̀rúndún kejì ṣááju Sànmánì Tiwa) gbé iye tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó tọ́ọ̀nù 13.5 wúrà lọ sí tẹ́ḿpìlì Amon-Ra ní Karnak—èyí sì wulẹ̀ jẹ́ apá kan ẹ̀bùn náà.
◻ Àkọlé àwọn ará Íjíbítì ṣàkọsílẹ̀ àwọn ẹ̀bùn tí àpapọ̀ wọn fẹ́rẹ̀ẹ́ tó tọ́ọ̀nù 383 wúrà àti fàdákà tí Ọba Osorkon Kìíní (ní ìbẹ̀rẹ̀ ẹgbẹ̀rúndún kìíní ṣááju Sànmánì Tiwa) fún àwọn ọlọ́run.
Síwájú sí i, ìdìpọ̀ ìwé Classical Greece nínú àwọn ọ̀wọ́ Great Ages of Man ròyìn pé:
◻ Ibi ìwakùsà Pangaeum ní Thrace ń mú iye tí ó ju tọ́ọ̀nù 37 wúrà jáde lọ́dọọdún, fún Ọba Philip Kejì (359 sí 336 ṣááju Sànmánì Tiwa).
◻ Nígbà tí ọmọ Philip, Alexander Ńlá (336 sí 323 ṣááju Sànmánì Tiwa), ṣẹ́gun Susa, olú ìlú ilẹ̀ ọba Páṣíà, wọ́n rí àwọn ohun iyebíye tí ó tó tọ́ọ̀nù 1,200 wúrà.
Nítorí náà, àpèjúwe tí Bíbélì ṣe nípa ọrọ̀ Ọba Sólómọ́nì kì í ṣe ohun tí kò lè rí bẹ́ẹ̀. Pẹ̀lúpẹ̀lù, rántí pé, Sólómọ́nì “pọ̀ ju gbogbo àwọn ọba ayé lọ, ní ọrọ̀ àti ní ọgbọ́n” ní àkókò yẹn.—Àwọn Ọba Kìíní 10:23.
Báwo ni Sólómọ́nì ṣe lo ọrọ̀ rẹ̀? Ó fi “wúrà dídára jù lọ” bo ìtẹ́ rẹ̀, gbogbo ife rẹ̀ jẹ́ “wúrà,” ó sì ní 200 asà wúrà àti 300 apata “[àdàlù, NW] wúrà.” (Àwọn Ọba Kìíní 10:16-21) Ju gbogbo rẹ̀ lọ, a lo wúrà Sólómọ́nì fún tẹ́ḿpìlì Jèhófà ní Jerúsálẹ́mù. Wúrà àti fàdákà ni a fi ṣe àwọn ọ̀pá fìtílà tẹ́ḿpìlì náà àti ohun èlò mímọ́ ọlọ́wọ̀, bí àmúga, àwo kòtò, ago, àti ọpọ́n. A fi wúrà bo àwọn kérúbù tí ó ga ní mítà 4.5 tí ó wà nínú Ibi Mímọ́ Jù Lọ, pẹpẹ tùràrí, àti gbogbo inú ilé náà látòkèdélẹ̀.—Àwọn Ọba Kìíní 6:20-22; 7:48-50; Kíróníkà Kìíní 28:17.
Tẹ́ḿpìlì tí a fi wúrà bò ńkọ́? Ó dùn mọ́ni pé, irú lílo wúrà lọ́nà bẹ́ẹ̀ kì í ṣe ohun àjèjì ní ayé ìgbàanì. Ìwé ìròyìn Biblical Archaeology Review ṣàkíyèsí pé, Amenophis Kẹta ti Íjíbítì “fi tẹ́ḿpìlì kan ‘tí a fi wúrà bò látòkèdélẹ̀, tí a fi fàdákà ṣe ilẹ̀ rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́, tí a [sì] fi àdàlù wúrà òun fàdákà ṣẹwà sí gbogbo ilẹ̀kùn rẹ̀’ ní Thebes, bọlá fún ọlọ́run títóbi lọ́lá náà, Amun.”. Síwájú sí i, Esar-haddon ti Ásíríà (ọ̀rúndún keje ṣááju Sànmánì Tiwa) fi wúrà bo ilẹ̀kùn àti ògiri ojúbọ Ashur. Nípa tẹ́ḿpìlì Sin ní Harran, Nábónídọ́sì ti Bábílónì (ọ̀rúndún kẹfà ṣááju Sànmánì Tiwa) kọ ọ́ pé: “Mo fi wúrà àti fàdákà bo ògiri rẹ̀, mo sì mú kí wọ́n máa tàn bí oòrùn.”
Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn àkọsílẹ̀ ìtàn fi hàn pé àkọsílẹ̀ Bíbélì nípa ọrọ̀ Ọba Sólómọ́nì kì í ṣe àsọdùn.