“Ibo Ni Ṣọ́ọ̀ṣì Yín Tilẹ̀ Wà Ná?”
ÀWỌN ẸLẸ́RÌÍ JÈHÓFÀ ní Mòsáḿbíìkì ni a sábà máa ń bi ní ìbéèrè yìí. Ká sọ tòótọ́, títí di ẹnu lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí, ó ti jẹ́ ìbéèrè tí ó ṣòro láti dáhùn. Èyí jẹ́ nítorí pé a kò dá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ̀ lábẹ́ òfin ní orílẹ̀-èdè yìí títí di ọdún 1991. Nítorí náà, kò ṣeé ṣe láti ní àwọn ibi ìjọsìn tí a dá fi hàn yàtọ̀, tí ó sì fìdí múlẹ̀.
Ṣùgbọ́n, ipò yẹ́n yí padà ní February 19, 1994. Ní ọjọ́ yẹn tí ó móoru, tí oòrùn mú, a ya Gbọ̀ngàn Ìjọba méjì tí a óò kọ́kọ́ kọ́ sí Mòsáḿbíìkì sí mímọ́. Àròpọ̀ 602 ènìyàn ni ó wá sí ibi ìyàsímímọ́ àwọn ibi ìpàdé tí ó lẹ́wà wọ̀nyí ní ìlú èbúté Béírà, tí ó wà ní nǹkan bí àárín gbùngbùn bèbè etíkun Mòsáḿbíìkì. Àwọn ni àwọn ìjọ mẹ́ta tí ń bẹ ní ìlú yẹn yóò máa lò.
Gbogbo iṣẹ́ ìkọ́lé náà látòkè délẹ̀, látorí fífi ìpìlẹ̀ ilé sọlẹ̀ títí dórí píparí àwọn ilé náà, gba ọdún kan àti oṣù méjì tí ó kún fún iṣẹ́ àṣekára. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni 30 tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ láti Zimbabwe tí ó múlé gbè wọ́n wá, wọ́n sì ṣiṣẹ́ ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí tí ó wà níbẹ̀. Níwọ̀n bí àyè kò ti lè gba gbogbo wọn ní ilé míṣọ́nnárì tí ó wà ní Béírà, tí ó jẹ́ ibi ìṣekòkáárí iṣẹ́ náà, àwọn kan pàgọ́ sẹ́gbẹ̀ẹ́ ilé ní àwọn òpin ọ̀sẹ̀ àti ní àwọn àkókò kan fún ọ̀pọ̀ ọ̀sẹ̀ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo.
Òpópónà ńlá Béírà ni Gbọ̀ngàn Ìjọba fún Ìjọ Massamba àti Ìjọ Munhava wà. Míṣọ́nnárì kan sọ pé: “Ní ọjọ́ kan tí ó kún fún ìgbòkègbodò, nígbà tí iṣẹ́ náà ń yá, tí ìtẹ̀síwájú sì fara hàn gbangba, a rí i tí jàm̀bá ọkọ̀ fẹ́rẹ̀ẹ́ ṣẹlẹ̀ bí àwọn awakọ̀ tí ń kọjá lọ tí wọ́n ti gbàgbé pé ìdí ọkọ̀ ni àwọ́n wà ti tẹjú mọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba náà.” Ọ̀pọ̀ dúró láti wo iṣẹ́ náà, ohun tí ó sì wú wọn lórí ní pàtàkì ni bí àwọn ẹ̀yà ìran ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ṣe wá síbẹ̀, tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀ ní ìṣọ̀kan.
Ọ̀pọ̀ ìwéèwé àti ètò ni a ṣe. Láìdà bí ọ̀pọ̀ àwọn iṣẹ́ ìkọ́lé mìíràn ní apá ibí yìí nínú ayé, níbi tí àwọn ohun èlò àti àlùmọ́nì ti ṣọ̀wọ́n, iṣẹ́ lórí àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba náà kò dáwọ́ dúró nítorí àìsí ohun èlò. Ní àkókò kan, a nílò 800 àpò sìmẹ́ǹtì, ilé iṣẹ́ kan ṣoṣo tí ó sì lè pèsè rẹ̀ kò ní àpò tí ó tó láti kó sìmẹ́ǹtì náà sí. Àwọn ará kàn sí ọ́fíìsì ẹ̀ka Watch Tower Society tí ó wà ní olú ìlú, ní Màpútò; a fi ọkọ̀ òfuurufú kó àpò ránṣẹ́, a kó o lọ sí ilé iṣẹ́ sìmẹ́ǹtì náà, a sì dì í kún. Iṣẹ́ náà tẹ̀ síwájú láìsí ìdádúró.
Ní àkókò míràn, nígbà tí a ń ró àjà ilé, irin tí a fi ń gbé àwọn igi àjà ró tán lọ́wọ́ àwọn agbo òṣìṣẹ́. Nítorí ọ̀wọ́n gógó rẹ̀, ń ṣe ni a kó irin fún iṣẹ́ ìkọ́lé náà wọlé láti ibi tí ó jìnnà tó kìlómítà 600! Ọ̀kan lára agbo òṣìṣẹ́ náà tọ ọkùnrin kan tí ó ń wòran lọ, ó sì béèrè bí ó bá mọ ibi tí wọ́n ti lè rí irin tí wọn yóò fi parí iṣẹ́ náà. Ọkùnrin náà fèsì pé: “Mo ti dúró síhìn-ín fún ohun tí ó ju wákàtí kan lọ, kì sì í ṣe pé ó kàn dédé ṣẹlẹ̀. Kò sí ohun mìíràn tí mo lè ṣe ju kí ń gbóṣùbà fún iṣẹ́ tí ẹ ń ṣe àti ẹ̀mí tí ẹ fi ń ṣe iṣẹ́ ìkọ́lé yìí. Mo ní irin tí ẹ nílò gan-an, inú mi yóò sì dùn láti fi ta yín lọ́rẹ.” Ó jẹ́ ìpèsè tí ó tí ì bọ́ sákòókò jù lọ.
Ọ̀pọ̀ àwọn olùṣàkíyèsí ṣe kàyéfì nípa ilé iṣẹ́ kọ́lékọ́lé ńlá tí ń bójú tó iṣẹ́ yìí. Bí a ti lè retí, inú agbo òṣìṣẹ́ náà dùn láti sọ fún wọn pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìwọ̀nyí tí wọ́n ń yọ̀ǹda ara wọn. Kí ni ó wú àwọn olùṣàkíyèsí lórí ní pàtàkì? Ẹnì kán sọ pé: “Ènìyàn tí ó ṣọ̀kan ni yín. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀yà ìran yín yàtọ̀, ẹ ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ọmọ ìyá.” Ìyọrísí rẹ̀ ni pé ọ̀pọ̀ wá ń béèrè fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó ti nípa lórí àwọn ìpàdé pàápàá. Fún àpẹẹrẹ, ìpíndọ́gba àwọn tí ń pésẹ̀ sí ìpàdé ní Ìjọ Manga ju ìlọ́po méjì iye àwọn Ẹlẹ́rìí.
Àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun náà ní tòótọ́ tí jẹ́ ìbùkún ńláǹlà fún àwọn Ẹlẹ́rìí tí ń bẹ níbẹ̀. Púpọ̀ jù lọ wọn tí pàdé nínú àwọn ilé ògbólógbòó, tí a fi koríko tàbí páànù bíi mélòó kan ṣe òrùlé rẹ̀, wọ́n ti pàdé lágbàlá, tàbí nínú yàrá kékeré nínú ilé àdáni ní ìṣáájú. Ọ̀pọ̀ ìgbà tí òjò bá rọ̀ ni ará wọ́n máa ń rẹ gbingbin; síbẹ̀ wọn kì í pa ìpàdé jẹ. Fún ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún, ìwọ̀nyí ni kìkì “àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba” tí àwọn Ẹlẹ́rìí ní Mòsáḿbíìkì mọ̀. Arákùnrin Caetano Gabriel, alàgbà kan ní Ìjọ Massamba, sọ pé: “A dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ará wa kárí ayé, tí wọ́n ṣètọrẹ fún ṣíṣàṣeparí iṣẹ́ yìí.” Ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí kan rántí pé: “Nígbà tí a fi wà ní Carico (“àgọ́ ìtúndálẹ́kọ̀ọ́” níbi tí a há àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ́ fún nǹkan bíi ọdún 12), a máa ń sọ pé, ‘A óò dúró ṣinṣin gẹ́gẹ́ bí olóòótọ́, Jèhófà yóò sì san èrè fún wa.’ Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun náà jẹ́ èrè láti ọ̀dọ̀ Jèhófà.” Àwọn ọ̀rọ̀ wọn fi ìmoore wọn tí ó jinlẹ̀, àti ìpinnu wọn láti yin Jèhófà hàn.
A gbin ẹ̀mí aṣáájú ọ̀nà sínú ọ̀pọ̀ èwe tí wọ́n nípìn-ín nínú iṣẹ́ ìkọ́lé náà, wọ́n sì tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ òjíṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà déédéé lẹ́yìn náà. Bí ó ti ń wo Gbọ̀ngàn Ìjọba tí ó mọ́ tónítóní láìlábàwọ́n náà, ní ọjọ́ ìyàsímímọ́ ku ọ̀la, Isabel tí ó jẹ́ ọ̀dọ́, aṣáájú ọ̀nà déédéé kan ní Ìjọ Manga, sọ pé: “Lójú tèmi, ibí yìí ni ibi tí ó lẹ́wà jù lọ ní ìlú Béírà. Inú mi dùn jọjọ láti wà níhìn-ín.” Adão Costa, míṣọ́nnárì kan, ṣàlàyé pé àwọn aláṣẹ àdúgbò ti fọwọ́ sowọ́ pọ̀ gidigidi láti jẹ́ kí a gbé àwọn ìgbésẹ̀ àkànṣe láti kó àwọn ohun èlò wọlé nítorí wọ́n mọ̀ pé àwọn Ẹlẹ́rìí jẹ́ aláìlábòsí. Lẹ́yìn náà, ó fi kún un pé: “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó rẹ̀ wá gidigidi, ohun ìdùnnú ni láti rí èso iṣẹ́ yìí sí ìyìn àti ògo Jèhófà.”
Nísinsìnyí, nígbàkígbà tí ọ̀rẹ́ kan, tí ń gbé ìlú Béírà bá béèrè pé, “Ibo ni ṣọ́ọ̀ṣì yín tilẹ̀ wà ná?” àwọn Ẹlẹ́rìí máa ń darí rẹ̀ sí ọ̀kan nínú àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun méjì náà, wọ́n sì máa ń fi ìdùnnú fèsì pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ bíi, “Ó wà ní Òpópónà International, Avenida Acordo de Lusaka, ní òdì kejì tí o bá ń bọ̀ láti Àgọ́ Ọlọ́pàá ti Ọ̀wọ́ Kẹrin.” Lẹ́yìn náà, wọn yóò wá fi àtúnṣe kan kún un pé, “Ó kàn jẹ́ pé kì í ṣe ṣọ́ọ̀ṣì. Gbọ̀ngàn Ìjọba ni!”
[Àwòrán ilẹ̀/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
ÁFÍRÍKÀ
Mòsáḿbíìkì
Béírà
Màpútò
[Credit Line]
Àwòrán ilẹ̀: Mountain High Maps® Copyright © 1995 Digital Wisdom, Inc.