Ìwòsàn Ìyanu Ha Ṣì Ń Ṣẹlẹ̀ Bí?
“GBA Jésù gbọ́, kí o sì rí ìwòsàn!” Irú ọ̀rọ̀ amóríwú bì èyí sún Alexandre, ọmọ ìjọ Evangelical kan, láti gbà gbọ́ pé lílo oògùn sí àìsàn òun yóò fi hàn pé òun kò nígbàgbọ́. Ó gbà gbọ́ pé ìgbàgbọ́ òun nìkan ni yóò mú ìwòsàn ìyanu tí òun ń fẹ́ wá. A ru ìmọ̀lára Benedita, Kátólíìkì onítara, sókè nígbà tí ó gbọ́ nípa àwọn ìwòsàn ìyanu tí ń ṣẹlẹ̀ ní ibi mímọ́ Aparecida do Norte, ní ìpínlẹ̀ São Paulo ní Brazil. Ní lílo àwọn àfọ̀ṣẹ tí ẹ̀gbọ́n ìyá rẹ̀ obìnrin kọ́ ọ, Benedita gbàdúrà sí Obìnrin Aparecida Wa, Anthony, àti àwọn “ẹni mímọ́” mìíràn, fún agbára láti mú àwọn aláìsàn lára dá.
Lọ́nà tí ó ṣe kedere, àní títí di apá ìparí ọ̀rúndún ogún yìí, ọ̀pọ̀ ènìyàn ṣì gbà gbọ́ nínú ìwòsàn ìyanu—ṣùgbọ́n, kí nìdìí rẹ̀? Ó ṣeé ṣe pé àwọn kan máa ń ní ìjákulẹ̀ nígbà tí kò bá ṣeé ṣe fún àwọn dókítà láti dín àìsàn, ìrora, àti ìjìyà àwọn olólùfẹ́ wọn kù, pàápàá ti àwọn ọmọ wọn. Àwọn tí àrùn tí kì í lọ bọ̀rọ̀ ń pọ́n lójú lè ronú pé, lójú ìwòye bí ìtọ́jú òde òni tí gbówó lórí tó, kò burú láti wá ìtọ́jú onígbàgbọ́ wò-ó-sàn. Àwọn kan ń rí onírúurú ìjọ àti ẹnì kọ̀ọ̀kan lórí tẹlifíṣọ̀n tí ń sọ pé àwọn lè wo àrùn AIDS, ìsoríkọ́, àrùn jẹjẹrẹ, àrùn ọpọlọ, ẹ̀jẹ̀ ríru, àti onírúurú àìsàn míràn sàn. Yálà wọ́n gba irú àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ gbọ́ tàbí wọn kò gbà á gbọ́, wọ́n lè yíjú sí wọn gẹ́gẹ́ bí ìrètí kan ṣoṣo tí ó ṣẹ́ kù. Síbẹ̀, àwọn mìíràn tí wọ́n gbà gbọ́ pé àwọn ẹ̀mí búburú ni ó fi àìsàn sí àwọn lára lè ronú pé oògùn òyìnbó kò lè ran àwọn lọ́wọ́.
Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, àwọn kan wà tí wọ́n ta ko èrò náà pé “àwọn ẹni mímọ́” tí ó ti kú tàbí àwọn amúniláradá tí ó ṣì wà láàyè ń ṣe ìwòsàn ìyanu, wọ́n tilẹ̀ dẹ́bi fún un pàápàá. Gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde Jornal da Tarde ti sọ, onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ìgbékalẹ̀ adènà àrùn, Dráusio Varella, lérò pé ìgbàgbọ́ náà “ń já ìgbàgbọ́ àwọn tí ó rọrùn láti tàn jẹ àti àwọn tí ó ti gbékútà kulẹ̀.” Ó fi kún un pé: “Nítorí tí wọ́n ń retí iṣẹ́ ìyanu, ọ̀pọ̀ lè kọ ìtọ́jú ìṣègùn ṣíṣe pàtàkì sílẹ̀ nítorí àwọn ẹlẹ́tàn wọ̀nyí.” Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The New Encyclopædia Britannica ṣàlàyé pé: “Ní ìgbà àtijọ́, a ti sọ pé àwọn ibi mímọ́ àti ààtò ìsìn ní í ṣe pẹ̀lú ìmúláradá tí kò bá ti gbogbogbòò mu, ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ìṣègùn sì máa ń tètè ka gbogbo irú ìmúláradá bẹ́ẹ̀ sí ọ̀nà tí a gbà ń múni níyè tí ń ṣiṣẹ́ lábẹ́ ipò tí ó bára dé.” Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ wà tí wọ́n gbà gbọ́ pé iṣẹ́ ìyanu wo àwọn sàn ní tòótọ́. Fún wọn, ìwòsàn náà ṣiṣẹ́!
Àwọn tí wọ́n mọ Bíbélì dáradára mọ̀ pé Jésù Kristi mú àwọn aláìsàn lára dá ní ọ̀pọ̀ ìgbà, ní lílo ‘agbára Ọlọ́run’ láti fi ṣe èyí. (Lúùkù 9:42, 43) Nítorí náà, wọ́n lè ṣe kàyéfì pé, ‘Ǹjẹ́ agbára Ọlọ́run ṣì ń ṣiṣẹ́, tí ó sì ń jẹ́ kí ìwòsàn ìyanu ṣẹlẹ̀ lónìí bí?’ Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, èé ṣe tí ìgbìdánwò láti ṣèwòsàn fi kùnà láti mú àbájáde tí a ṣèlérí wá? Ṣe nítorí aláìsàn náà kò ní ìgbàgbọ́ tó ni tàbí nítorí owó tí ó ń dá kò pọ̀ tó? Ó ha tọ̀nà fún Kristẹni kan láti wá ìwòsàn ìyanu nígbà tí ó bá ń ṣàìsàn ríroni lára kan tàbí tí kò tilẹ̀ gbóògùn? Ìwòsàn ìyanu tí kì í kùnà irú èyí tí Jésù ṣe yóò ha tún wáyé mọ́ bí? O lè rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè ṣíṣe kókó wọ̀nyí nínú àpilẹ̀kọ tí ó tẹ̀ lé e.