Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Ǹjẹ́ Júù oníṣègùn ti ọ̀rúndún kẹrìnlá náà, Shem-Tob ben Isaac Ibn Shaprut, ṣàdàkọ Tetragrammaton (lẹ́tà Hébérù mẹ́rin tí ó dúró fún orúkọ Ọlọ́run) tí a rí nínú ìwé Mátíù tí a fi èdè Hébérù kọ?
Rárá, kò ṣe bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n, ìwé Mátíù yí lo hash·Shem’ (tí a kọ tán tàbí tí a ké kúrú) ní ìgbà 19, gẹ́gẹ́ bí a ti sọ nínú Ilé Ìṣọ́ August 15, 1996, ní ojú ìwé 13.
Ọ̀rọ̀ Hébérù náà, hash·Shem’, túmọ̀ sí “Orúkọ náà,” tí ó tọ́ka sí orúkọ àtọ̀runwá náà láìsí àní-àní. Fún àpẹẹrẹ, nínú àkọsílẹ̀ Shem-Tob, ìkékúrú ẹ̀yà ọ̀rọ̀ hash·Shem’ fara hàn nínú Mátíù 3:3, ẹsẹ tí Mátíù ti fa ọ̀rọ̀ inú Aísáyà 40:3 yọ. Ó bọ́gbọ́n mu láti dé ìparí èrò náà pé, nígbà tí Mátíù fa ọ̀rọ̀ inú ẹsẹ kan yọ nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, níbi ti Tetragrammaton wà, ó fi orúkọ àtọ̀runwá náà sínú Ìhìn Rere rẹ̀. Nítorí náà, bí àkọsílẹ̀ Hébérù tí Shem-Tob gbé kalẹ̀ kò tilẹ̀ lo Tetragrammaton, lílò tí ó lo “Orúkọ náà,” gẹ́gẹ́ bí a ti lò ó nínú Mátíù 3:3, ti lílo “Jèhófà” lẹ́yìn nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì.
Shem-Tob ṣàdàkọ ìwé Mátíù lédè Hébérù nínú iṣẹ́ alátakò gbígbóná janjan rẹ̀ náà, ʼEʹven boʹchan. Ṣùgbọ́n, kí ni orísun ìwé Hébérù náà? Ọ̀jọ̀gbọ́n George Howard, tí ó ti ṣèwádìí jinlẹ̀ lórí ọ̀ràn yí, dábàá pé “Ọjọ́ orí Ìwé Mímọ́ Mátíù Lédè Hébérù ti Shem-Tob tó nǹkan bí àárín ọ̀rúndún mẹ́rin àkọ́kọ́ ti sànmánì Kristẹni.”a Àwọn ẹlòmíràn lè ṣàìfohùn ṣọ̀kan pẹ̀lú rẹ lórí èyí.
Howard sọ pé: “Ìwé Mátíù Lédè Hébérù, tí a lò nínú àkọsílẹ̀ yí ní pàtàkì ni a fi ọ̀pọ̀ ohun tí ó fi yàtọ̀ sí ìwé Mátíù Lédè Gíríìkì dá mọ̀ yàtọ̀.” Fún àpẹẹrẹ, gẹ́gẹ́ bí ohun tí àkọsílẹ̀ Shem-Tob sọ, Jésù sọ nípa Jòhánù pé: “Ní òótọ́ ni mo wí fún yín pé, láàárín àwọn tí obìnrin bí kò sí ẹni kan tí ó dìde tí ó tóbi ju Jòhánù Oníbatisí lọ.” Ó fo ọ̀rọ̀ Jésù tí ó tẹ̀ lé e pé: “Ṣùgbọ́n ẹni kan tí ó jẹ́ ẹni tí ó kéré jù nínú ìjọba àwọn ọ̀run tóbi jù ú.” (Mátíù 11:11) Ní ọ̀nà tí ó jọra, ọ̀pọ̀ ìyàtọ̀ wà láàárín ẹsẹ Hébérù ti Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù tí kò sọnù àti ọ̀rọ̀ inú ẹsẹ kan náà nínú ìtumọ̀ ti Septuagint Lédè Gíríìkì. Bí a tilẹ̀ mọ̀ nípa ìyàtọ̀ tí ó wà láàárín wọn, irú àwọn ìwé àtijọ́ bẹ́ẹ̀ ní àyè tiwọn nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ ìfiwéra.
Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ ṣáájú, àkọsílẹ̀ Shem-Tob lórí Mátíù ní “Orúkọ náà” níbi tí a ní ẹ̀rí tí ó pọ̀ tó láti gbà gbọ́ pé Tetragrammaton gan-an ni Mátíù lò níbẹ̀. Nípa báyìí, láti 1950, a ti ń lo àkọsílẹ̀ Shem-Tob gẹ́gẹ́ bí ìtìlẹ́yìn fún lílo orúkọ àtọ̀runwá náà nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, a sì tọ́ka sí i nínú The New World Translation of the Holy Scriptures—With References.b
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
b Tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde ní 1984.