Òfin Mẹ́wàá
BÍṢỌ́Ọ̀BÙ Gloucester ti ilẹ̀ England ṣàwárí pé èyí tí ó ju ìdajì àwọn àlùfáà abẹ́ rẹ̀ ni kò lè ka Òfin Mẹ́wàá sórí, ìpín 10 nínú ọgọ́rùn-ún wọn kò sì mọ ibi tí ó wà nínú Bíbélì. Ṣùgbọ́n, nǹkan bí 450 ọdún sẹ́yìn ni ìyẹn. Ipò nǹkan ha ti sàn sí i láti ìgbà náà wá bí? Rárá o—gẹ́gẹ́ bí ìwádìí àṣekárí tí ìwé agbéròyìnjáde Sunday Times ṣe láàárín àwọn àlùfáà Áńgílíkà ti ṣí i payá.
Nínú gbogbo àlùfáà 200 tí a fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò, kìkì ìpín 34 nínú ọgọ́rùn-ún ni ó lè ka gbogbo Òfin Mẹ́wàá náà sórí. Lára àwọn tí ó kù, ọ̀kan rò pé wọ́n ti le jù, òmíràn sì kà wọ́n sí òfin tí kò yanjú ìṣòro ìwà híhù òde òní.
Ìwọ ha mọ Òfin Mẹ́wàá náà tàbí ibi tí a ti lè rí wọn? A ṣàkọsílẹ̀ wọn sínú Ẹ́kísódù, ìwé kejì nínú Bíbélì, ní àwọn ẹsẹ 17 àkọ́kọ́ nínú orí 20. Èé ṣe tí o kò fi kà wọ́n? Ọ̀nà rírọrùn láti gbà pín wọn nìyí. Mẹ́rin àkọ́kọ́ ní í ṣe pẹ̀lú ìjọsìn wa sí Ọlọ́run, ìkarùn-ún tẹnu mọ́ ìgbésí ayé ìdílé, ìkẹfà sí ìkẹsàn-án ní í ṣe pẹ̀lú ipò ìbátan wa pẹ̀lú àwọn ènìyàn ẹlẹgbẹ́ wa, ìkẹwàá sì jẹ́ àrà ọ̀tọ̀, ó ń mú kí a ṣàwárí ohun tí ń bẹ nínú ọkàn wa fínnífínní, kí a gbé ìsúnniṣe wa yẹ̀ wò. Àkópọ̀ kúkúrú nípa bí àwọn Kristẹni ṣe lè lo àwọn ìlànà rẹ̀ nìyí.
Àkọ́kọ́: Fún Ẹlẹ́dàá wa ní ìfọkànsìn tí a yà sọ́tọ̀ gédégbé. Ìkejì: Má lo ère nínú ìjọsìn. Ìkẹta: Bọ̀wọ̀ fún orúkọ Ọlọ́run, kí o sì bọlá fún un nígbà gbogbo. Ìkẹrin: Wá àkókò láti pọkàn pọ̀ sórí àwọn ọ̀ràn tẹ̀mí, láìsí ìpínyà ọkàn. Ìkarùn-ún: Ẹ̀yin ọmọ, ẹ bọ̀wọ̀ fún àwọn òbí yín. Ìkẹfà: Má ṣe pànìyàn. Ìkeje: Yẹra fún panṣágà. Ìkẹjọ: Má jalè. Ìkẹsàn-án: Sọ òtítọ́. Ìkẹwàá: Yẹra fún ojúkòkòrò.
Òfin Mẹ́wàá jẹ́ ara àkójọ òfin tí a fún Mósè. Ṣùgbọ́n àwọn ìlànà inú wọn wà títí ayé. (Róòmù 6:14; Kólósè 2:13, 14) Fún ìdí yìí, àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù fa ọ̀rọ̀ yọ láti inú Òfin Mẹ́wàá, wọ́n sì tọ́ka sí i. (Róòmù 13:8-10) Ẹ wo bí ìgbésí ayé ì bá ti láyọ̀ tó—tí ì bá sì ti wà láìséwu tó—lónìí, ká ní gbogbo ènìyàn bọ̀wọ̀ fún àwọn ìlànà tí Ọlọ́run mí sí wọ̀nyí, tí wọ́n sì gbé ní ìbámu pẹ̀lú wọn!