Wọ́n Ń jà Nítorí Ibi “Mímọ́”
NÍ July 15, 1099, Ogun Ẹ̀sìn Àkọ́kọ́, tí póòpù Róòmù fàṣẹ sí, lé góńgó rẹ̀ bá, ìyẹn ni láti gba Jerúsálẹ́mù. Ìpakúpa náà le kú! Gómìnà àti ẹ̀ṣọ́ rẹ̀ nìkan ni olùgbé ìlú náà tó là á já, àmọ́ ìyẹn jẹ́ lẹ́yìn tí wọ́n ti san àbẹ̀tẹ́lẹ̀ rẹpẹtẹ. Nínú ìwé rẹ̀, The Crusades, àlùfáà Antony Bridge, ròyìn itú tí wọ́n fi àwọn ẹlẹ́sìn Mùsùlùmí àti àwọn Júù tí ń gbé ìlú náà pa, ó wí pé: “Gbàrà tí a ti fún àwọn Ajagun Ẹ̀sìn náà lómìnira láti ṣe ohunkóhun tó bá wù wọ́n nínú ìlú náà, ni wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ ìtàjẹ̀sílẹ̀ ńláǹlà tó kó jìnnìjìnnì báni. . . . Gbogbo ọkùnrin, obìnrin, àti ọmọdé tí wọ́n rí ní ìlú náà ni wọ́n pa . . . Nígbà tí kò sí ẹni tí wọ́n tún lè rí pa, ni wọ́n bá tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́ rìn kiri ìgboro ìlú náà . . . títí lọ dé Ṣọ́ọ̀ṣì Ibojì Mímọ́ láti fọpẹ́ fún Ọlọ́run.”
Láti ìgbà tí àwọn ajagun ẹ̀sìn ti ṣẹ́gun Jerúsálẹ́mù ni wíwà tí Kirisẹ́ńdọ̀mù wà nínú ìlú náà ti ń dá wàhálà sílẹ̀ láàárín àwọn ẹlẹ́sìn Roman Kátólíìkì, Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ti Ìlà Oòrùn, àti àwọn ẹlẹ́sìn mìíràn tí wọ́n pè ní ti Kristẹni. Ní ọdún 1850, awuyewuye tó wáyé láàárín àwọn onírúurú aṣáájú ẹ̀sìn nítorí àwọn ibi tó jẹ́ ibi mímọ́ ní Jerúsálẹ́mù àti àgbègbè rẹ̀ ni kókó pàtàkì tó fa Ogun Crimean. Ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [500,000] ẹ̀mí ló ṣègbé sínú ogun tí ilẹ̀ England, Faransé, àti Ìjọba Ilẹ̀ Ottoman bá Rọ́ṣíà jà.
Ogun náà kò fòpin sí ìjà tó wà láàárín Kirisẹ́ńdọ̀mù nítorí Jerúsálẹ́mù àti àwọn ibi mímọ́ rẹ̀. Àwọn ará Ottoman, tí ń ṣàkóso orílẹ̀-èdè náà nígbà yẹn, gbìyànjú láti pẹ̀tù sí ọ̀ràn náà nípa pípín àwọn ibi mímọ́ náà fún gbogbo ẹ̀sìn tó wà níbẹ̀. Ọ̀mọ̀wé Menashe Har-el nínú ìwé rẹ̀, This Is Jerusalem, ṣàlàyé pé: “Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè tẹ́wọ́ gba ìlànà yìí, . . . nípa gbígbé Ìpinnu Pípín Ibi Mímọ́ ti November 1947 kalẹ̀. Ó sì tipa bẹ́ẹ̀ di apá kan òfin àgbáyé.” Ìyọrísí rẹ̀ ni pé, Ṣọ́ọ̀ṣì Ibojì Mímọ́ di èyí tí a pín láàárín àwọn ẹlẹ́sìn Roman Kátólíìkì, Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ti ilẹ̀ Gíríìsì, àwọn ará Áméníà, àwọn ará Síríà, àti àwọn ẹlẹ́sìn Copt. Níkẹyìn, àwọn ará Etiópíà fi hàn pé àwọn pẹ̀lú ní ẹ̀tọ́ láti pín nínú ṣọ́ọ̀ṣì yìí, wọ́n sì ní kí àwọn mẹ́ńbà wọn kan máa gbé inú ahéré tó wà lórí òrùlé ṣọ́ọ̀ṣì náà. Ọ̀pọ̀ ka Ṣọ́ọ̀ṣì Ibojì Mímọ́ sí ibi mímọ́ jù lọ ní Kirisẹ́ńdọ̀mù. Àwọn ojúbọ, ère, àti àwòrán ló sì kún inú rẹ̀ o. Ibi mímọ́ mìíràn tún ni èyí tí a ń pè ní, Gordon’s Calvary, tí àwọn ẹlẹ́sìn Pùròtẹ́sítáǹtì kan ń bọ gẹ́gẹ́ bí ibi tí wọ́n rò pé a ti pa Jésù, tí a sì sin ín sí.
Àmọ́ tipẹ́tipẹ́ sẹ́yìn ni Jésù ti sọ fún obìnrin kan tó nígbàgbọ́ nínú àwọn ibi mímọ́ pé: “Wákàtí náà ń bọ̀ nígbà tí kì í ṣe ní òkè ńlá yìí tàbí ní Jerúsálẹ́mù ni ẹ ó ti máa jọ́sìn Baba. . . . Àwọn olùjọsìn tòótọ́ yóò máa jọ́sìn Baba ní ẹ̀mí àti òtítọ́.” (Jòhánù 4:21-24) Ìdí rèé tí àwọn Kristẹni tòótọ́ kì í fi í júbà àwọn ibi mímọ́. Ìparun Jerúsálẹ́mù aláìṣòótọ́ látọwọ́ àwọn ọmọ ogun Róòmù ní ọdún 70 Sànmánì Tiwa jẹ́ ìkìlọ̀ fún Kirisẹ́ńdọ̀mù. Ìbọ̀rìṣà rẹ̀, ìpínyà tó wà nínú rẹ̀, àti ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ tó wà lọ́rùn rẹ̀ fi hàn pé gbogbo ariwo tó ń pa pé Kristẹni lòun, irọ́ gbuu ni kì í ṣe Kristẹni. Nítorí náà, yóò kàgbákò tí Ọlọ́run ti sọ tẹ́lẹ̀ pé yóò dé bá gbogbo ẹ̀sìn tó para pọ̀ jẹ́ Bábílónì Ńlá.—Ìṣípayá 18:2-8.