Ìwọ Ha Rántí Bí?
Ǹjẹ́ o mọrírì kíka àwọn ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ ti lọ́ọ́lọ́ọ́? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, wò ó bóyá o lè dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e wọ̀nyí:
• Kí ló mú kó rọrùn fún àwọn ará Kòríà láti tẹ́wọ́ gba Kérésìmesì?
Ìgbàgbọ́ kan tó ti wà ní Kòríà àtàwọn orílẹ̀-èdè bíi mélòó kan látọjọ́ tó ti pẹ́ ni ìgbàgbọ́ nípa ọlọ́run ilé ìdáná tí wọ́n gbà pé ó máa ń gba ihò èéfín wá ní December, tó sì ń kó àwọn ẹ̀bùn wá. Àti pé lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kejì, àwọn sójà Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà máa ń pín àwọn ẹ̀bùn àti owó ìrànwọ́ láwọn ṣọ́ọ̀ṣì àdúgbò.—12/15, ojú ìwé 4, 5.
• Ní ìmúṣẹ Aísáyà orí kọkànlélógún, ẹsẹ ìkẹjọ, “olùṣọ́” wo ni Ọlọ́run ti yàn lákòókò tiwa?
Àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró, tí wọ́n ń sìn gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ olùṣọ́ kan, ti jẹ́ kí àwọn ènìyàn mọ ìtumọ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ inú ayé tó mú àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ṣẹ. Wọ́n tún ti ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́wọ́ láti dá àwọn ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ àti àṣà tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu mọ̀, kí wọ́n sì yàgò fún wọn.—1/1, ojú ìwé 8, 9.
• Àwọn wo ni wọ́n ń pè ní “Àwọn Ará ní Poland”?
Àwọn ni ẹgbẹ́ onísìn kékeré kan tó wà ní Poland ni ọ̀rúndún kẹrìndínlógún àti ìkẹtàdínlógún, wọ́n rọ̀ mọ́ Bíbélì tímọ́tímọ́, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ kọ àwọn òpómúléró ẹ̀kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì sílẹ̀, àwọn bí ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan, ìbatisí àwọn ọmọ ọwọ́, àti iná ọ̀run àpáàdì. Bí àkókò ti ń lọ, wọ́n ṣe inúnibíni líle koko sí wọn, wọ́n sì fọ́n wọn ká sí àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn.—1/1, ojú ìwé 21-23.
• Èé ṣe tó fi yẹ kí a gbẹ́kẹ̀ lé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì dípò àsọtẹ́lẹ̀ àwọn alákìíyèsí ìgbà tàbí àwọn awòràwọ̀?
Àwọn aláfẹnujẹ́ wòlíì kò ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé nítorí pé wọn ò ka Jèhófà àti Bíbélì sí. Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì nìkan ló lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti mọ bí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ṣe bá ète Ọlọ́run mu, òun lo lè fi ṣe ara rẹ àti ìdílé rẹ láǹfààní tí yóò wà pẹ́ títí.—1/15, ojú ìwé 3.
• Kí ni àwọn ẹ̀rí díẹ̀ tó fi hàn pé àwọn ọjọ́ ìkẹyìn là ń gbé?
A lè rí àbájáde lílé tí a lè Sátánì kúrò ní ọ̀run. (Ìṣípayá 12:9) A ń gbé ní àkókò “ọba” tí ó kẹ́yìn nínú àwọn táa mẹ́nu kan nínú Ìṣípayá 17:9-11. Iye àwọn ojúlówó Kristẹni ẹni àmì òróró ń dín kù, síbẹ̀ ó dà bí ẹni pé àwọn kan lára wọn ṣì máa wà lórí ilẹ̀ ayé nígbà tí ìpọ́njú ńlá náà bá bẹ̀rẹ̀.—1/15, ojú ìwé 12, 13.
• Ìgbà wo ni a kọ ìwé Hábákúkù, èé sì ti ṣe tó fi yẹ kí a nífẹ̀ẹ́ sí i?
A kọ ìwé Bíbélì yìí ní nǹkan bí ọdún 628 ṣááju Sànmánì Tiwa. Ó ní ìdájọ́ Jèhófà lòdì sí Júdà àti Bábílónì ìgbàanì nínú. Ó tún sọ̀rọ̀ nípa ìdájọ́ Ọlọ́run tí yóò dé sórí ètò búburú ìsinsìnyí láìpẹ́.—2/1, ojú ìwé 8.
• Ibo nínú Bíbélì la ti lè rí ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n látọ̀dọ̀ ìyá kan fún aya tó dáńgájíá?
Orí tí ó kẹ́yìn nínú ìwé Òwe, orí kọkànlélọ́gbọ̀n, jẹ́ orísun kan tí ó tayọ lọ́lá fún irú ìmọ̀ràn bẹ́ẹ̀.—2/1, ojú ìwé 30, 31.
• Èé ṣe táa fi lè dúpẹ́ pé Jèhófà ti ṣí “èrò inú Kristi” payá fún wa? (1 Kọ́ríńtì 2:16)
Nípasẹ̀ ìwé Ìhìn Rere, Jèhófà ti jẹ́ kí a mọ̀ nípa èrò, ìṣesí, ìgbòkègbodò, àti àwọn ohun àkọ́múṣe Jésù. Èyí lè ràn wá lọ́wọ́ láti túbọ̀ dà bíi Jésù, pàápàá nínú bí a ṣe ń mú iṣẹ́ ìwàásù tí ń gbẹ̀mí là náà lọ́kùn-únkúndùn.—2/15, ojú ìwé 25.
• Ṣé Ọlọ́run ń gbọ́ àdúrà lónìí?
Bẹ́ẹ̀ ni. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì fi hàn pé kì í ṣe gbogbo àdúrà ni Ọlọ́run máa ń gbọ́, àwọn ìrírí òde òní fi hàn pé ọ̀pọ̀ ìgbà ló máa ń dáhùn àdúrà àwọn tó ń wá ìtùnú àti ìrànlọ́wọ́ lórí àwọn ọ̀ràn bíi yíyanjú ìṣòro ìdílé.—3/1, ojú ìwé 3-7.
• Kí la lè ṣe láti rí okun gbà látọ̀dọ̀ Ọlọ́run?
A lè béèrè fún un nínú àdúrà, a lè gba okun tẹ̀mí látinú Bíbélì, a tún ń gba okun nípasẹ̀ ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ Kristẹni.—3/1, ojú ìwé 15, 16.
• Báwo làwọn òbí ṣe lè ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti túbọ̀ jàǹfààní nínú àwọn ìpàdé Kristẹni?
Wọ́n lè ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti wà lójúfò, bóyá kí wọ́n jẹ́ kí wọ́n sùn díẹ̀ ṣáájú ìpàdé. A lè fún àwọn ọmọ níṣìírí láti kọ “àkọsílẹ̀,” irú bíi kí wọ́n máa sàmì sórí bébà ní gbogbo ìgbà tí a bá lo àwọn ọ̀rọ̀ tàbí àwọn orúkọ tí wọ́n ti gbọ́ tẹ́lẹ̀.—3/15, ojú ìwé 17, 18.
• Kí ni díẹ̀ lára nǹkan tí a lè kọ́ nínú àpẹẹrẹ Jóòbù?
Jóòbù fi ìbátan rẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run sí ipò kìíní, kò fi ojúsàájú bá àwọn ènìyàn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ lò, ó tiraka láti jẹ́ olóòótọ́ sí aya rẹ̀, ipò tẹ̀mí ìdílé rẹ̀ jẹ ẹ́ lógún, ó sì fara da àdánwò láìyẹsẹ̀.—3/15, ojú ìwé 25 sí 27.
• Ǹjẹ́ Bíbélì ní àwọn ọ̀rọ̀ tó jẹ́ ẹnà láti fún wa ní ìjìnlẹ̀ òye sí àwọn ìsọfúnni tó díjú?
Rárá o. Nítorí àwọn èèyàn sọ pé bákan náà ni àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n rò pé ó jẹ́ ẹnà wà nínú àwọn ìwé kan tó jẹ́ tayé pàápàá. Ohun táwọn kan lè pè ní ẹnà nínú Bíbélì lè di èyí tí kò já mọ́ nǹkan kan nípa yíyí ètò àwọn ẹyọ ọ̀rọ̀ inú ìwé àfọwọ́kọ ti Hébérù padà.—4/1, ojú ìwé 30, 31.