Ìpàdé Ọdọọdún October 7, 2000
ÌPÀDÉ ỌDỌỌDÚN ti àwọn mẹ́ńbà Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania yóò wáyé ní October 7, 2000, ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ní 2932 Kennedy Boulevard, Jersey City, New Jersey. A ó ṣe ìpàdé àṣeṣáájú ti àwọn mẹ́ńbà nìkan ní agogo mẹ́sàn-án kọjá ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún láàárọ̀, ìpàdé ti gbogbo gbòò yóò tẹ̀ lé e ní agogo mẹ́wàá òwúrọ̀.
Kí àwọn mẹ́ńbà Àjọ náà jọ̀wọ́ fi ìyípadà èyíkéyìí nínú àdírẹ́sì ìfìwéránṣẹ́ wọn nínú ọdún tó kọjá tó Ọ́fíìsì Akọ̀wé létí nísinsìnyí, kí àwọn lẹ́tà ìfitónilétí tí a ń lò déédéé àti ìwé àṣẹ ìṣojúfúnni bàa lè dé ọ̀dọ̀ wọn ní oṣù July.
Ẹ jọ̀wọ́ ẹ tètè dá àwọn ìwé àṣẹ ìṣojúfúnni, tí a ó fi ránṣẹ́ sí àwọn mẹ́ńbà pẹ̀lú ìfitónilétí nípa ìpàdé ọdọọdún náà padà, kí ó bàa lè dé Ọ́fíìsì Akọ̀wé Society, ó pẹ́ tán ní August 1. Kí mẹ́ńbà kọ̀ọ̀kan tètè kọ ọ̀rọ̀ kún ìwé àṣẹ ìṣojúfúnni tirẹ̀ ní kíá mọ́sá, kí ó sì dá a padà, kí ó sọ bóyá òun fúnra òun yóò wà níbi ìpàdé náà tàbí pé òun kò ní sí níbẹ̀. Kí ìsọfúnni tí a kọ sórí ìwé àṣẹ ìṣojúfúnni kọ̀ọ̀kan ṣe pàtó lórí kókó yìí, níwọ̀n bí a ó ti gbára lé e fún pípinnu àwọn tí yóò wà níbẹ̀.
A retí pé gbogbo ìpàdé náà, títí kan ìpàdé àmójútó iṣẹ́ àti àwọn ìròyìn, yóò parí ní agogo kan ọ̀sán tàbí kó kọjá díẹ̀. Kò ní sí ìpàdé mìíràn ní ọ̀sán. Nítorí ìwọ̀nba àyè tí ó wà, àwọn tó bá ní tíkẹ́ẹ̀tì lọ́wọ́ nìkan ni yóò lè wọlé. Kì yóò sí ètò kankan fún lílo tẹlifóònù láti so ìpàdé ọdọọdún náà pọ̀ mọ́ àwọn gbọ̀ngàn àpéjọ mìíràn.