Àwọn Iṣẹ́ Rere Ń Mú Ògo Wá fún Ọlọ́run
ÀWỌN tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run ń là kàkà láti tan ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí tó wà nínú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Wọ́n sì ń tipa báyìí tẹ̀ lé àṣẹ Jésù tó sọ pé: “Kí ìmọ́lẹ̀ yín máa tàn níwájú àwọn ènìyàn, kí wọ́n lè rí àwọn iṣẹ́ àtàtà yín, kí wọ́n sì lè fi ògo fún Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run.” (Mátíù 5:16) Ọ̀rọ̀ ẹnu wa àti ìwà rere wa lè mú ògo wá fún Ọlọ́run.
Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń gbìyànjú láti mú inú Ọlọ́run dùn nípa híhùwà ní ìbámu pẹ̀lú Bíbélì àti nípa sísakun láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí. Wọ́n ń ṣe bẹ́ẹ̀, kódà láwọn ilẹ̀ tí iṣẹ́ òjíṣẹ́ ìta gbangba wọn kò tíì di èyí tí a fìdí rẹ̀ múlẹ̀ lábẹ́ òfin. Àwọn Ẹlẹ́rìí tiẹ̀ ń ṣe àpéjọpọ̀ ọdọọdún ní olú ìlú ọ̀kan lára àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí, tó sì jẹ́ pé àwọn tó máa ń wá sáwọn àpéjọpọ̀ náà máa ń tó ẹgbẹ̀rún mẹ́fà sí ẹgbẹ̀rún mẹ́sàn-án ènìyàn. Wọ́n ti háyà àwọn gbọ̀ngàn tó wà níbi tí wọ́n ti máa ń ṣe ìpàtẹ ọjà àgbáyé fún irú ìpàdé bẹ́ẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe láwọn ọdún tó ṣáájú, kó tó di pé wọ́n bẹ̀rẹ̀ àpéjọpọ̀ ti ọdún 1999, ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn Ẹlẹ́rìí ló ṣe iṣẹ́ àṣekára láti gbá àwọn gbọ̀ngàn náà mọ́ tónítóní, tí wọ́n sì to àwọn ohun èlò ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ àti ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn àga síbẹ̀.
Gbogbo ìpalẹ̀mọ́ yìí làwọn èèyàn ń kíyè sí. Àwọn alábòójútó ibẹ̀ kíyè sí ìgbòkègbodò wọ̀nyí. Wọ́n tún rí i pé bí àwọn èrò ti pọ̀ tó, tó fi jẹ́ pé wọ́n pé ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, ọgọ́rùn-ún méje ó dín mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n [15,666] lọ́jọ́ térò pọ̀ jù lọ, síbẹ̀ ṣe ni gbogbo nǹkan lọ lẹ́sẹẹsẹ, àwọn Ẹlẹ́rìí náà sì wà létòlétò. Inú àwọn òṣìṣẹ́ náà tún dùn gan-an sí gbígbá tí wọ́n gbá ibẹ̀ mọ́ tónítóní nígbà tí wọ́n lò ó tán.
Àwọn alábòójútó ibẹ̀ fi ìmọrírì hàn fún gbogbo ohun tí wọ́n rí yìí nípa fífi àwọn Ẹlẹ́rìí sí ipò kìíní lára àwọn tí wọn óò kọ́kọ́ fún láǹfààní àtilo ilé náà lọ́dún tó ń bọ̀. Àní àwọn alábòójútó náà tiẹ̀ tún ṣe ju ìyẹn lọ. Ní July 15, 1999, wọ́n fún ìgbìmọ̀ àpéjọpọ̀ náà ní ẹ̀bùn kan láti fi ìmọrírì wọn hàn. Ohun tí wọ́n kọ sí ara àmì ẹ̀yẹ náà ni “ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà”—èyí jẹ́ ohun kan tí wọn kò retí rárá ní orílẹ̀-èdè kan tí wọ́n ti fi òfin de iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wọn.
Jákèjádò ayé, ní ọdún 2000 sí 2001, a retí pé kí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn wá sí ọgọ́rọ̀ọ̀rún Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Àwọn Olùṣe Ohun Tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Wí” ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Tóo bá wà níbẹ̀, wàá lè fojú ara rẹ rí i bí àwọn tó ń fi taratara ṣe ohun tí Bíbélì wí ṣe ń lọ́wọ́ nínú àwọn iṣẹ́ rere tí ń mú ògo wá fún Ọlọ́run.