Ìsìn Ha Lè Mú Àlàáfíà Kárí Ayé Wá Bí?
ÀWỌN aṣojú tó lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] láti orílẹ̀-èdè mẹ́tàléláàádọ́rin [73] ló kóra wọn jọ sí New York City láti August 28 sí August 31, 2000. Wọ́n pàdé pọ̀ ní ilé Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè fún “Àpérò Lórí Ẹgbẹ̀rúndún Àlàáfíà Kárí Ayé ti Àwọn Aṣáájú Ẹ̀sìn Àtàwọn Olùdásílẹ̀.” Àwọn aṣáájú náà—tí ọ̀pọ̀ nínú wọ́n wé láwàní, tàbí tí wọ́n wọ aṣọ aláwọ ìyeyè, tàbí tí wọ́n lo ìbòrí oníyẹ̀ẹ́ múlọ́múlọ́, tàbí tí wọ́n wọ aṣọ dúdú gẹ̀rẹ̀jẹ̀—ń ṣojú fún onírúurú ẹ̀sìn. Lára ìwọ̀nyí ni ìsìn Baha’i, Búdà, Híńdù, Ìsìláàmù, Jain, ìsìn àwọn Júù, àtàwọn ìsìn Kirisẹ́ńdọ̀mù, Sikh, Ṣintó, Tao, àti Zoroaster.
Àwọn aṣojú náà pàdé pọ̀ ní ilé Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè fún ọjọ́ méjì àkọ́kọ́ àpérò ọlọ́jọ́ mẹ́rin náà. Àmọ́, kì í ṣe àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ló ṣètò àpérò yìí, kì í sì í ṣe òun ló ni owó tí wọ́n ná sí i, bí kò ṣe onírúurú àjọ. Síbẹ̀síbẹ̀, àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè àti àwọn aṣáájú ìsìn jùmọ̀ sọ̀rọ̀ lórí ìjẹ́pàtàkì fífọwọ́sowọ́pọ̀ láti fòpin sí ipò òṣì, kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà, àwọn ìṣòro àyíká, ogun, àti ohun ìjà tí wọ́n ń lò fún ìparun runlérùnnà.
Àwọn aṣojú náà fọwọ́ sí ìwé kan tí wọ́n pe àkọlé rẹ̀ ní “Ẹ̀jẹ́ Láti Wá Àlàáfíà Kárí Ayé.” Bí wọ́n tilẹ̀ mọ̀ pé ìwà ipá àti ogun “sábà máà ń wáyé nítorí ìsìn,” síbẹ̀ ìwé náà sọ pé àwọn tí ó fọwọ́ sí i yóò “pawọ́ pọ̀ pẹ̀lú àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè . . . láti lépa àlàáfíà.” Àmọ́, wọn ò ṣe ìpinnu pàtó tó fi bí èyí ṣe lè ṣeé ṣe hàn.
Ní ọjọ́ kejì, Bawa Jain, alága àpérò náà, parí ọ̀rọ̀ tó fi ṣí ìpàdé náà nípa ṣíṣàlàyé pé òun kíyè sí àwòrán kan ní Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè lọ́dún bíi mélòó kan sẹ́yìn. Àwòrán náà jẹ́ àwòrán ọkùnrin kan tó ga ju ilé iṣẹ́ Ọ̀gá Àgbà ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè. Ó ń kan ilé náà koko bí ẹní ń kanlẹ̀kùn. Àkọlé tó wà lábẹ́ àwòrán náà ni: “Ọmọ Aládé Àlàáfíà.” Ọ̀gbẹ́ni Jain sọ pé: “[Àwòrán náà] nípa tó lágbára lórí mi ní gbàrà tí mo rí i. Mo bi onírúurú èèyàn nípa ohun [tó] túmọ̀ sí. Mo wá rí i pé mo ti rí ìdáhùn gbà lónìí. Pípé tí gbogbo yín pé jọ pọ̀ síbí, ẹ̀yin olùdásílẹ̀ àti aṣáájú ẹ̀sìn nínú ayé, ti fi hàn mí pé [ẹni] yìí ni ọmọ aládé àlàáfíà tó ń kan ilẹ̀kùn ilé Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè.”
Bíbélì ní èrò tó yàtọ̀. Ó fi hàn pé Jésù Kristi ni Ọmọ Aládé Àlàáfíà. Òun ni yóò mú àlàáfíà wá, kì í ṣe nípasẹ̀ ìsapá àwọn òṣèlú ayé tàbí àwọn aṣáájú ẹ̀sìn, bí kò ṣe nípasẹ̀ Ìjọba Ọlọ́run. Ìjọba yìí—ìyẹn ìjọba ọ̀run ti Ọlọ́run—ni yóò so ìran ènìyàn onígbọràn pọ̀ ṣọ̀kan, tí yóò sì mú kí ìfẹ́ Ọlọ́run di ṣíṣe lórí ilẹ̀ ayé.—Aísáyà 9:6; Mátíù 6:9, 10.