Ohun Tí Jíjẹ́ Opó Sọ Àwọn Obìnrin Méjì Kan Dà
SANDRA jẹ́ opó kan tí ń gbé ní Ọsirélíà. Nígbà tí ọkọ rẹ̀ kú ní nǹkan bí ọdún méjì sẹ́yìn, ṣe ni òtútù kọ́kọ́ bo Sandra. “Bí ikú ṣe mú ọkọ mi tí ó tún jẹ́ ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n lọ lójijì mú ọkàn mi gbọgbẹ́. Mi ò tilẹ̀ rántí bí mo ṣe padà délé láti ọsibítù lọ́jọ́ yẹn mọ́ tàbí ohun tí mo fi ìyókù ọjọ́ yẹn ṣe. Láàárín ọ̀sẹ̀ díẹ̀ tó tẹ̀ lé e, hílàhílo tó bá mi wá fa ìrora gógó nínú àgọ́ ara mi.”
Sandra ní ọ̀rẹ́ kan tó dàgbà jù ú lọ tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Elaine, tó ti jẹ́ opó fún nǹkan bí ọdún mẹ́fà. Elaine ló tọ́jú David, ọkọ rẹ̀, fún oṣù mẹ́fà kó tó wá di pé àrùn jẹjẹrẹ tó ṣe é gbẹ̀mí rẹ̀. Àròdùn Elaine pọ̀ débi pé kò pẹ́ lẹ́yìn ikú ọkọ rẹ̀ tí kò fi ríran mọ́ fún sáà kan. Ọdún méjì lẹ́yìn náà, ńṣe ló dìgbò lulẹ̀ nígboro. Dókítà rẹ̀ kò rí àmì kankan pé àìsàn ń ṣe é. Àmọ́, ó rí i pé ńṣe ni Elaine ń pa àròdùn rẹ̀ mọ́nú, fún ìdí yìí dókítà náà sọ fún un pé kí ó lọ sílé, kí ó sì sa gbogbo ipá rẹ̀ láti sunkún. Elaine sọ pé: “Ó gba àkókò gan-an kí n tó lè borí àròdùn mi,” ó sì tún sọ ohun tó máa ń ṣe láwọn ìgbà tó bá dá wà pé, “mo tilẹ̀ máa ń wọnú yàrá lọ, tí màá sì da ẹ̀wù David borí.”
Ká sòótọ́, ikú olólùfẹ́ ẹni lè fa onírúurú ìmọ̀lára, nítorí pé jíjẹ́ opó kì í kàn-án ṣe ọ̀ràn wíwà láìsí ọkọ. Bí àpẹẹrẹ, fún sáà kan, Sandra kò mọ irú ẹ̀dá tóun jẹ́ mọ́. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ àwọn mìíràn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di opó, òun náà ka ara rẹ̀ sí ẹni tí kò ní olùgbèjà, tí kò ní alábàárò. Sandra rántí pé: “Tẹ́lẹ̀, ọkọ mi ló máa ń ṣe ìpinnu, ṣùgbọ́n ó kàn ṣàdédé ku èmi nìkan láti máa ṣe ìpinnu wọ̀nyẹn. Mi ò fi bẹ́ẹ̀ rí oorun sùn mọ́. Ó wá ń rẹ̀ mí, mi ò sì ní ìmí mọ́. Àtimọ ohun tó yẹ ní ṣíṣe wá di ìṣòro.”
Ojoojúmọ́ ni àwọn ìrírí tó jọ ti Sandra àti Elaine ń ṣẹlẹ̀ kárí ayé. Àìsàn, jàǹbá, ogun, pípa odindi ẹ̀yà run, àti onírúurú ìwà ipá ń jẹ́ kí iye àwọn opó máa pọ̀ sí i.a Ọ̀pọ̀ àwọn opó wọ̀nyí ló ń rún àròdùn wọn mọ́ra láìsọ̀rọ̀ síta, nítorí pé wọn ò mọ ohun tí wọn ì bá ṣe. Ìrànlọ́wọ́ wo làwọn ẹbí àti ọ̀rẹ́ lè ṣe fáwọn opó tí ń wá ọ̀nà láti kojú ipò wọn? Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e pèsè àwọn ìmọ̀ràn tó lè ṣèrànwọ́.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwọn obìnrin míì wà ní ipò tó jọ ti àwọn opó nítorí pé ọkọ wọn ti fi wọ́n sílẹ̀. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀tọ̀ tún làwọn ìṣòro tí títúká àti jíjáwèé ìkọ̀sílẹ̀ máa ń fà, ṣùgbọ́n àwọn ìlànà kan táa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e tún lè ran àwọn obìnrin tó wà ní ipò wọ̀nyí lọ́wọ́.