Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
A kà á nínú 1 Pétérù 4:3, pé àwọn Kristẹni kan lọ́wọ́ sí “ìbọ̀rìṣà tí ó lódì sí òfin” rí. Ṣé kì i ṣe gbogbo ìbọ̀rìṣà ló lòdì sófin ni, tí Ọlọ́run sì kà wọ́n léèwọ̀?
Bẹ́ẹ̀ ni, lójú Ọlọ́run, gbogbo ìbọ̀rìṣà ló lòdì sófin. Àwọn tó bá fẹ́ rí ojú rere rẹ̀ kò gbọ́dọ̀ bọ̀rìṣà.—1 Kọ́ríńtì 5:11; Ìṣípayá 21:8.
Àmọ́, ó jọ pé ọ̀tọ̀ ni àlàyé tí àpọ́sítélì Pétérù ń ṣe níhìn-ín nípa ìbọ̀rìṣà. Kókó kan ni pé, ìbọ̀rìṣà wọ́pọ̀ gan-an ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ayé ọjọ́un, àwọn aláṣẹ kò sì kà á léèwọ̀ lábẹ́ òfin. Ohun táà ń sọ ni pé kò sófin tó de irú ìbọ̀rìṣà bẹ́ẹ̀. Àwọn ìbọ̀rìṣà kan tilẹ̀ wà lára ìlànà tí orílẹ̀-èdè tàbí ìjọba gbé kalẹ̀. Táa bá fojú ìyẹn wò ó, àwọn kan ti lọ́wọ́ sí ‘àwọn ìbọ̀rìṣà tí òfin kò kà léèwọ̀,’ kí wọ́n tó di Kristẹni. (New World Translation, ẹ̀dà ti 1950) Fún àpẹẹrẹ, ó yẹ fún àfiyèsí pé Nebukadinésárì Ọba Bábílónì gbé òrìṣà wúrà kan kalẹ̀, àmọ́ Ṣádírákì, Méṣákì, àti Àbẹ́dínígò, tí wọ́n jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà, kọ̀ láti bọ ọ́.—Dáníẹ́lì 3:1-12.
Báa bá tún gba ibòmíì wò ó, ọ̀pọ̀ ààtò ìbọ̀rìṣà ló lòdì pátápátá sí gbogbo òfin àdánidá tàbí òfin ìwà rere tó bá ẹ̀rí ọkàn ẹ̀dá mu. (Róòmù 2:14, 15) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé nípa àwọn ìwà pálapàla kan tó “lòdì sí ìwà ẹ̀dá,” tó sì jẹ́ ìwà “ìbàjẹ́.” Nǹkan wọ̀nyí sì máa ń ṣẹlẹ̀ dáadáa nígbà tí wọ́n bá ń ṣe àwọn ààtò ẹ̀sìn kan. (Róòmù 1:26, 27) Àwọn ọkùnrin àtobìnrin tó ń lọ́wọ́ sí ìbọ̀rìṣà tó lòdì sófin, kò kọbi ara sí ààlà tí òfin àdánidá gbé kalẹ̀. Dájúdájú, àwọn tó bá fẹ́ di Kristẹni gbọ́dọ̀ jáwọ́ nínú gbogbo ìwà ìbàjẹ́ wọ̀nyẹn.
Láfikún sí ohun táa sọ lókè yìí, Jèhófà Ọlọ́run kórìíra irú àwọn ìbọ̀rìṣà yẹn tó wọ́pọ̀ láàárín àwọn tí kì í ṣe Júù. Fún ìdí yìí, wọn ò bófin mu.a—Kólósè 3:5-7.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ohun tí èdè Gíríìkì táa lò nínú 1 Pétérù 4:3 túmọ̀ sí ní ṣáńgílítí ni “àwọn ìbọ̀rìṣà tí kò bófin mu.” Onírúurú ọ̀nà la ti gbà túmọ̀ gbólóhùn yìí nínú àwọn Bíbélì èdè Gẹ̀ẹ́sì, a ti túmọ̀ rẹ̀ sí àwọn gbólóhùn bí “ìbọ̀rìṣà tó tàpá sófin,” “àwọn ìbọ̀rìṣà táa kà léèwọ̀,” àti “àwọn ìbọ̀rìṣà aláìlófin.”