Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Ǹjẹ́ ó bọ́gbọ́n mu kí Kristẹni tòótọ́ lọ bá wọn ṣètò ìsìnkú tàbí ìgbéyàwó nínú ṣọ́ọ̀ṣì?
Lílọ́wọ́ sí ìjọsìn èyíkéyìí tó jẹ mọ́ ẹ̀sìn èké jẹ́ ohun tí kò dára lójú Jèhófà, a sì gbọ́dọ̀ yàgò fún un. (2 Kọ́ríńtì 6:14-17; Ìṣípayá 18:4) Ètò ìsìnkú nínú ṣọ́ọ̀ṣì jẹ́ ààtò ìsìn tó sábà máa ń wé mọ́ ìwàásù tó dá lórí àwọn ẹ̀kọ́ tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu, bí àìleèkú ọkàn àti sísọ pé ọ̀run ni gbogbo ẹni rere ń lọ. Ó tún lè wé mọ́ àwọn àṣà bíi ṣíṣe àmì àgbélébùú àti wíwà níbi tí àlùfáà yóò ti máa ṣáájú àwọn èèyàn nínú àdúrà. Àdúrà àti àwọn ààtò ẹ̀sìn mìíràn tó lòdì sí ẹ̀kọ́ Bíbélì tún lè jẹ́ apá kan ayẹyẹ ìgbéyàwó tó wáyé nínú ṣọ́ọ̀ṣì tàbí níbòmíràn. Wíwà láàárín ọ̀pọ̀ èrò, níbi tí gbogbo wọn ti ń kópa nínú ààtò ìsìn èké lè jẹ́ kó nira fún Kristẹni kan láti dá yàtọ̀. Ẹ ò rí i pé kò bọ́gbọ́n mu rárá láti kó ara ẹni sínú irú ìṣòro bẹ́ẹ̀!
Bí Kristẹni kan bá rí i pé lílọ síbi ìsìnkú tàbí ìgbéyàwó kan tí yóò wáyé nínú ṣọ́ọ̀ṣì kò ṣeé yẹ̀ ńkọ́? Bí àpẹẹrẹ, ọkọ kan tó jẹ́ aláìgbàgbọ́ lè fẹ́ kí aya òun tó jẹ́ Kristẹni bá òun lọ síbi irú ayẹyẹ bẹ́ẹ̀. Ṣé ó lè bá a lọ, kí ó kàn máa wò wọ́n níran ní tiẹ̀? Aya náà lè pinnu pé òun máa lọ, bóyá nítorí pé ọkọ rẹ̀ sọ pé òun fẹ́ kó wà níbẹ̀, ṣùgbọ́n kí ó pinnu lọ́kàn ara rẹ̀ pé òun ò ní lọ́wọ́ sí ìkankan lára ààtò ẹ̀sìn tí wọ́n máa ṣe níbẹ̀. Àmọ́, ó tún lè pinnu pé òun ò ní lọ, nítorí pé àyíká yẹn lè kó òun sínú ìṣòro, kí ó jẹ́ kí òun fi àwọn ìlànà Ọlọ́run báni dọ́rẹ̀ẹ́. Ọwọ́ rẹ̀ ni ìpinnu náà wà. Dájúdájú, kò ní fẹ́ ṣe ohunkóhun tá a máa da ọkàn rẹ̀ láàmú, tí kò ní jẹ́ kó ní ẹ̀rí ọkàn rere.—1 Tímótì 1:19.
Bó ti wù kó rí, á dáa kó ṣàlàyé fún ọkọ rẹ̀ pé ẹ̀rí ọkàn òun kò ní jẹ́ kóun lọ́wọ́ sí èyíkéyìí lára ààtò ìsìn tó máa wáyé níbẹ̀ tàbí kóun bá wọn kọrin tàbí kóun tẹrí ba nígbà tí wọ́n bá ń gbàdúrà. Nígbà tó bá ṣàlàyé fún ọkọ rẹ̀, ọkọ rẹ̀ lè wá rí i pé tí ìyàwó òun bá lọ, ó ṣeé ṣe kí wíwà tó máa wà níbẹ̀ fa àwọn nǹkan kan tí inú òun ò ní dùn sí. Ó lè yàn láti dá lọ, nítorí ìfẹ́ tó ní sí aya rẹ̀, tàbí nítorí ọ̀wọ̀ tó ní fún ìgbàgbọ́ aya rẹ̀, tàbí nítorí kí wọ́n má lọ kó ara wọn síta láàárín èrò. Àmọ́ tí ọkọ rẹ̀ bá ní dandan-ǹ-dan kí ó bá òun lọ, ó lè lọ bí òǹwòran lásán.
Ohun tí a ò tún ní gbàgbé ni ipa tí lílọ síbi ààtò ìsìn nínú ilé ìjọsìn lè ní lórí àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa. Ṣé kò lè pa ẹ̀rí ọkàn àwọn kan lára? Ṣé kò lè jẹ́ kó wá túbọ̀ nira fún wọn láti yàgò fún ìbọ̀rìṣà? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣí wa létí pé: “Ẹ . . . máa wádìí dájú àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù, kí ẹ lè jẹ́ aláìní àbààwọ́n, kí ẹ má sì máa mú àwọn ẹlòmíràn kọsẹ̀ títí di ọjọ́ Kristi.”—Fílípì 1:10.
Bí ayẹyẹ náà bá jẹ́ ti ìbátan kan tó sún mọ́ wa pẹ́kípẹ́kí, àwọn ẹbí lè máa sọ pé dandan ni ká wà níbẹ̀. Bó ti wù kó rí, Kristẹni kan ní láti fara balẹ̀ gbé gbogbo ọ̀ràn náà yẹ̀ wò. Nínú àwọn ipò kan, ó lè pinnu pé ìṣòro kankan ò ní tìdí rẹ̀ yọ bóun bá lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì fún ìsìnkú tàbí ìgbéyàwó gẹ́gẹ́ bí òǹwòran. Ṣùgbọ́n, ó lè jẹ́ pé tó bá lọ, ìpalára tí lílọ rẹ̀ máa ṣe fún ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ tàbí ti àwọn ẹlòmíràn lè pọ̀ ju àǹfààní tí wíwà níbẹ̀ rẹ̀ máa ṣe. Ní ipòkípò tó bá yọjú, Kristẹni gbọ́dọ̀ máa rí i dájú pé ìpinnu tí òun ṣe kò ní jẹ́ kí òun pàdánù ẹ̀rí ọkàn rere níwájú Ọlọ́run àti ènìyàn.