Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Ròyìn
‘Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ń Sa Agbára’
Ọ̀PỌ̀ jù lọ èèyàn ló mọ Bíbélì dáadáa ní erékùṣù kan ní Caribbean ti ilẹ̀ Jàmáíkà tí oòrùn ti máa ń ràn gan-an. Àní, bóyá la fi rí ilé kan tá ò tí ní í rí ẹ̀dà Bíbélì King James Version, àwọn kan lára wọn sì ti rí i pé “ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yè, ó sì ń sa agbára.” (Hébérù 4:12) Agbára yìí sì lè yí ìgbésí ayé ẹni padà, gẹ́gẹ́ bá a ti ṣàpèjúwe rẹ̀ nínú ìrírí tó tẹ̀ lé e yìí.
Bí ọkùnrin kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Cleveland ṣe ń dé láti ibi iṣẹ́ ni Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan wá sílé rẹ̀. Lẹ́yìn tí wọ́n jọ jíròrò àwọn kókó bíi mélòó kan látinú Ìwé Mímọ́, Ẹlẹ́rìí náà fún un ní ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun, èyí tá a máa ń lò fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Cleveland kò mọ bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe máa sa agbára tó nínú ìgbésí ayé òun.
Cleveland ti máa ń gbàdúrà lẹ́ẹ̀mẹ́ta lójúmọ́ tẹ́lẹ̀ pé kí Ọlọ́run ran òun lọ́wọ́ kí òun lè rí ọ̀nà tí ó tọ́ láti jọ́sìn Rẹ̀. Cleveland mọ̀ dájú pé àwọn òbí òun kò jọ́sìn lọ́nà tí ó tọ́, àmọ́ lẹ́yìn tó ṣàyẹ̀wò àwọn ìsìn mìíràn, ńṣe ni gbogbo rẹ̀ wá tojú sú u. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó tí gbọ́ nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ́lẹ̀, síbẹ̀ ó ń kọminú nípa bóyá òtítọ́ ni ìsìn wọn fi ń kọ́ni tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Pẹ̀lú gbogbo ominú tó ń kọ Cleveland, ó gbà pé kí Ẹlẹ́rìí tó wá sílé òun yẹn wá máa bá òun ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Kí nìdí? Nítorí àtimú àwọn Ẹlẹ́rìí lónírọ́ ni!
Kò pẹ́ tí Cleveland fi mọ̀ pé ìbálòpọ̀ tí òun ń ní pẹ̀lú àwọn obìnrin méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ kò dùn mọ́ Ọlọ́run nínú. (1 Kọ́ríńtì 6:9, 10) Lẹ́yìn ìkẹ́kọ̀ọ́ méjì péré, ó lo ìgboyà láti jáwọ́ nínú àjọṣe àárín òun àtàwọn obìnrin náà. Ó tún bẹ̀rẹ̀ sí wá sáwọn ìpàdé Kristẹni ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Àmọ́ àdánwò mìíràn lèyí tún jẹ́ fún un.
Cleveland wà nínú ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù àdúgbò rẹ̀, bọ́ọ̀lù tó ń gbá yìí kò sì jẹ́ kó ráyè wá sípàdé déédéé. Kí ló máa wá ṣe o? Lójú gbogbo bí àwọn tí wọ́n jọ wà nínú ẹgbẹ́ náà, ọ̀gá rẹ̀ àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ṣe ń fúngun mọ́ ọn, Cleveland pinnu láti fi ẹgbẹ́ náà sílẹ̀. Dájúdájú, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti bẹ̀rẹ̀ sí sa agbára tó nípa rere lórí rẹ̀!
Agbára Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tún hàn nígbà tí Cleveland bẹ̀rẹ̀ sí sọ ìmọ̀ Bíbélì tó ní fáwọn ẹlòmíràn. (Ìṣe 1:8) Àbájáde rẹ̀ ni pé, méjì nínú àwọn tí wọ́n jọ wà nínú ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù tẹ́lẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí wá sípàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Nígbà tí Cleveland tóótun láti di akéde ìhìn rere, inú rẹ̀ máa ń dùn gan-an nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà, pẹ̀lú bó ṣe ń fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́.
Agbára Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run túbọ̀ nípa lórí Cleveland, ó sì fi ẹ̀rí pé òun ti ya ara òun sí mímọ́ fún Jèhófà hàn níkẹyìn nípa ṣíṣe ìrìbọmi. Ó tún láǹfààní láti sìn gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ alákòókò kíkún àti gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ nínú ìjọ.
Ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ti wá mọ̀ pé, ní ti tòótọ́, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run “yè, ó sì ń sa agbára” nílẹ̀ Jàmáíkà àti jákèjádò ayé.
[Àwòrán ilẹ̀/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
JÀMÁÍKÀ
[Credit Line]
Àwòrán ilẹ̀ àti àgbáyé: Mountain High Maps® Copyright © 1997 Digital Wisdom, Inc.