Ǹjẹ́ Ó Yẹ Kó O Jẹ́ Ẹni Tó Tutù Lẹ́dàá?
Ó ṢEÉ ṣe kí ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn gbà pé ọ̀rọ̀ àpọ́nlé ni tá a bá sọ pé wọ́n jẹ́ ẹni tó tutù lẹ́dàá, ẹni tí ara rẹ̀ balẹ̀, tó níwà jẹ́jẹ́, tó sì rára gba nǹkan. Àmọ́, ànímọ́ yẹn sábà ń sọ èèyàn di ẹni tó dẹra dẹngbẹrẹ. Bíbélì sọ pé: “Ìdẹra dẹngbẹrẹ àwọn arìndìn sì ni ohun tí yóò pa wọ́n run.” (Òwe 1:32) Kí nìyẹn túmọ̀ sí?
Àwọn ìtumọ̀ Bíbélì mìíràn túmọ̀ ọ̀rọ̀ Hébérù ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà sí àwọn gbólóhùn bíi “jọ̀gọ nù” (American Standard Version), “àìka-nǹkan-sí” (The New American Bible), àti “àìbìkítà.” (The New English Bible) Nítorí náà, ìdẹra dẹngbẹrẹ so pọ̀ mọ́ ìwà ọ̀lẹ àti àìbìkítà tó sì tipa bẹ́ẹ̀ jẹ mọ́ ìwà arìndìn tàbí ìwà òmùgọ̀.
Ní ọ̀rúndún kìíní, ìwà àìbìkítà àwọn Kristẹni tó wà nínú ìjọ Laodíkíà kò jẹ́ kí wọ́n mọ ibi tí wọ́n ti kù díẹ̀ káàtó nípa tẹ̀mí tàbí pé kò jẹ́ kí wọ́n fura sí i. Wọ́n ń fọ́nnu pé àwọn “kò . . . nílò ohunkóhun rárá.” Jésù Kristi tọ́ wọn sọ́nà, ó ní kí wọ́n tún padà di Kristẹni tó nítara.—Ìṣípayá 3:14-19.
Àìbìkítà náà ni ìṣòro àwọn èèyàn ayé ọjọ́ Nóà. Àwọn nǹkan ti ara inú ayé ló gbà wọ́n lọ́kàn, ìyẹn ni pé “wọ́n ń jẹ, wọ́n sì ń mu, àwọn ọkùnrin ń gbéyàwó, a sì ń fi àwọn obìnrin fúnni nínú ìgbéyàwó . . . , wọn kò sì fiyè sí i títí ìkún omi fi dé, tí ó sì gbá gbogbo wọn lọ.” Jésù wá fi kún un pé: “Bẹ́ẹ̀ náà ni wíwàníhìn-ín Ọmọ ènìyàn yóò rí.”—Mátíù 24:37-39.
Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tó ti ṣẹ fi hàn pé àkókò “wíwàníhìn-ín Ọmọ ènìyàn,” ìyẹn Jésù Kristi, là ń gbé. Ǹjẹ́ kí a má ṣe di aláìka-nǹkan-sí, aláìbìkítà, ká má sì jọ ara wa lójú jù—ìyẹn ni pé ká má ṣe jẹ́ ẹni tó tutù jù láé.—Lúùkù 21:29-36.