‘A Kò Ṣe Sólómọ́nì Lọ́ṣọ̀ọ́ Bí Ọ̀kan Lára Ìwọ̀nyí’
ÀWỌN òdòdó ẹgàn bí irú àwọn tá à ń wò yìí pọ̀ gan-an láwọn òpópónà ìhà gúúsù Áfíríkà. Òdòdó cosmos làwọn èèyàn máa ń pè wọ́n, àwọn ilẹ̀ olóoru ní Amẹ́ríkà la sì ti kọ́kọ́ rí wọn. Irú òdòdó rírẹwà bẹ́ẹ̀ tó ń hù fúnra rẹ̀ tó sì ń pọ̀ sí i lè mú wa rántí ẹ̀kọ́ kan tí Jésù fi kọ́ni. Ọ̀pọ̀ lára àwọn olùgbọ́ rẹ̀ ló jẹ́ tálákà, tí wọ́n sì ń ṣàníyàn nípa àwọn ohun tí wọ́n nílò, àti nípa oúnjẹ àti aṣọ wọn pẹ̀lú.
“Ní ti ọ̀ràn ti aṣọ,” Jésù béèrè pé, “èé ṣe tí ẹ fi ń ṣàníyàn? Ẹ kọ́ ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n lára àwọn òdòdó lílì pápá, bí wọ́n ṣe ń dàgbà; wọn kì í ṣe làálàá, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í rànwú; ṣùgbọ́n mo wí fún yín pé, Sólómọ́nì pàápàá nínú gbogbo ògo rẹ̀ ni a kò ṣe ní ọ̀ṣọ́ bí ọ̀kan lára àwọn wọ̀nyí.”—Mátíù 6:28, 29.
Onírúurú nǹkan làwọn èèyàn ti sọ nípa irú òdòdó ẹgàn tí Jésù ní lọ́kàn gan-an. Àmọ́, Jésù wá fi í wé ewéko lásánlàsàn, ó ní: “Wàyí o, bí Ọlọ́run bá wọ ewéko pápá láṣọ báyìí, èyí tí ó wà níhìn-ín lónìí, tí a sì sọ sínú ààrò ní ọ̀la, òun kì yóò ha kúkú wọ̀ yín láṣọ jù bẹ́ẹ̀ lọ, ẹ̀yin tí ẹ ní ìgbàgbọ́ kíkéré?”—Mátíù 6:30.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé òdòdó cosmos ò wọ́pọ̀ ní Ísírẹ́lì, ó dájú pé wọ́n jẹ́ kí ẹ̀kọ́ tí Jésù fi kọ́ni ṣe kedere. Ẹwà wọn máa ń fani mọ́ra gan-an, yálà nígbà téèyàn bá ń wò wọ́n láti ọ̀nà jíjìn tàbí nígbà téèyàn bá wà nítòsí wọn, àwọn ayàwòrán sì máa ń fẹ́ràn láti yà wọ́n. Ní ti tòótọ́, Jésù ò sàsọdùn nígbà tó sọ pé, “Sólómọ́nì pàápàá nínú gbogbo ògo rẹ̀ ni a kò ṣe ní ọ̀ṣọ́ bí ọ̀kan lára àwọn wọ̀nyí.”
Ẹ̀kọ́ wo nìyẹn kọ́ wa lóde òní? Àwọn tó ń sin Ọlọ́run lè ní ìdánilójú pé yóò ran àwọn lọ́wọ́ láti ní àwọn ohun tó jẹ́ kòṣeémáàní ìgbésí ayé kódà láwọn àkókò líle koko pàápàá. Jésù ṣàlàyé pé: “Ẹ máa wá ìjọba [Ọlọ́run] nígbà gbogbo, a ó sì fi nǹkan wọ̀nyí [bí oúnjẹ àti aṣọ téèyàn nílò] kún un fún yín.” (Lúùkù 12:31) Bẹ́ẹ̀ ni o, inú wíwá Ìjọba Ọlọ́run ni ojúlówó àǹfààní ti máa ń wá. Ṣùgbọ́n ǹjẹ́ o mọ ohun tí Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ àti ohun tí yóò ṣe fún aráyé? Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò dùn láti ràn ọ́ lọ́wọ́ kó o lè rí ìdáhùn látinú Bíbélì.