“Ẹ Sún Mọ́ Ọlọ́run, Yóò Sì Sún Mọ́ Yín”
Nígbà kan Rí àti Nísinsìnyí—Ó Rí Okun Gbà Láti Yí Padà
OBÌNRIN kan tó ń jẹ́ Sandra nílùú Mẹ́síkò sọ pé ẹni ìtanù lòun jẹ́ nínú ìdílé òun. Kíkọ̀ ni wọ́n kọ̀ ọ́ sílẹ̀ tí wọn ò sì bójú tó o ní gbogbo ìgbà tó wà ní ọ̀dọ́langba. Ó sọ pé: “Kò sí èrò méjì lọ́kàn mi ní gbogbo ìgbà tí mo fi wà léwe ju pé mi ò já mọ́ ohunkóhun lọ tí mo sì máa ń ṣe kàyéfì nípa ìdí tí mo fi wà láàyè àti nípa ìgbésí ayé lápapọ̀.”
Nígbà tí Sandra wà ní ilé ẹ̀kọ́ gíga, ó bẹ̀rẹ̀ sí yọ́ ọtí tí bàbá rẹ̀ bá rà sílé mu. Nígbà tó yá, òun fúnra rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ra ọtí mu ó sì tibẹ̀ di òkú ọ̀mùtí. Ó sọ pé: “Kò sóhun tó mú kí wíwàláàyè wù mí.” Nígbà tí gbogbo nǹkan sì wá tojú sú Sandra, ó bẹ̀rẹ̀ sí lo oògùn olóró. Ó sọ pé: “Kìkì ohun tó ń jẹ́ kí n gbàgbé àwọn ìṣòro mi làwọn nǹkan tí mo máa ń kó sínú àpamọ́wọ́ mi: ìgò ọtí kan, oògùn olóró díẹ̀ tàbí igbó díẹ̀.”
Lẹ́yìn tí Sandra jáde ní ilé ẹ̀kọ́ nípa ìṣègùn, ńṣe ló túbọ̀ wá dọ̀gá sí i nínú ọtí àmuyíràá. Ó gbìyànjú láti gbẹ̀mí ara rẹ̀. Àmọ́ ó yè é.
Sandra wá ìrànlọ́wọ́ nípa tẹ̀mí àti nípa tara lọ sínú oríṣiríṣi ẹ̀sìn, àmọ́ pàbó ni gbogbo rẹ̀ já sí. Ó ti ro ara rẹ̀ pin pé tòun ti tán, ó sì ké pe Ọlọ́run lọ́pọ̀ ìgbà pé: “Ibo gan-an lo tiẹ̀ wà? Kí ló dé tó ò ràn mí lọ́wọ́?” Àkókò tí èrò pé òun ò já mọ́ ohunkóhun yìí wá dorí rẹ̀ kodò gan-an ni ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá a sọ̀rọ̀. Bó ṣe bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìyẹn. Sandra kẹ́kọ̀ọ́ pé “Jèhófà sún mọ́ àwọn oníròbìnújẹ́ ní ọkàn-àyà,” èyí sì wú u lórí gan-an.—Sáàmù 34:18.
Ẹni tó ń kọ́ Sandra ní Bíbélì jẹ́ kó mọ̀ pé Jèhófà Ọlọ́run mọ̀ pé ẹ̀ṣẹ̀ àti àìpé tá a jogún látọ̀dọ̀ Ádámù ló máa ń mú ká sọ̀rètí nù. Sandra wá rí i pé Ọlọ́run mọ̀ dáadáa pé a ò lè kúnjú ìwọ̀n àwọn ìlànà òdodo rẹ̀. (Sáàmù 51:5; Róòmù 3:23; 5:12, 18) Inú rẹ̀ dùn gan-an nígbà tó kẹ́kọ̀ọ́ pé kì í ṣe ibi tá a kù díẹ̀ káàtó sí ni Jèhófà máa ń wò, àti pé kì í béèrè ohun tó ju agbára wa lọ lọ́wọ́ wa. Onísáàmù náà béèrè pé: “Bí ó bá jẹ́ pé àwọn ìṣìnà ni ìwọ ń ṣọ́, Jáà, Jèhófà, ta ni ì bá dúró?”—Sáàmù 130:3.
Òtítọ́ pàtàkì kan nínú Bíbélì tó mórí Sandra wú gan-an ni ti ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi. Nípa ẹbọ yìí, Jèhófà lo àánú láti mú kí ẹ̀dá èèyàn onígbọràn lè ní ìdúró rere lọ́dọ̀ òun láìka àìpé wọn sí. (1 Jòhánù 2:2; 4:9, 10) Dájúdájú, a lè rí “ìdáríjì àwọn àṣemáṣe wa” gbà ká sì tipa bẹ́ẹ̀ borí èrò náà pé a ò já mọ́ ohunkóhun.—Éfésù 1:7.
Sandra kọ́ àwọn ẹ̀kọ́ ṣíṣeyebíye látinú àpẹẹrẹ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Ẹni tó mọrírì inú rere Ọlọ́run gan-an pẹ̀lú bó ṣe dárí àwọn àṣìṣe rẹ̀ àtẹ̀yìnwá jì í tó sì tì í lẹ́yìn láti borí àìlera tó ní. (Róòmù 7:15-25; 1 Kọ́ríńtì 15:9, 10) Pọ́ọ̀lù ṣàtúnṣe ìgbésí ayé rẹ̀, ‘o lu ara rẹ̀ kíkankíkan ó sì ń darí rẹ̀ bí ẹrú’ kó bà a lè dúró sójú ọ̀nà tí Ọlọ́run fọwọ́ sí. (1 Kọ́ríńtì 9:27) Kò jẹ́ káwọn nǹkan bí ẹ̀ṣẹ̀ bí ẹ̀ṣẹ̀ tó ń wá sọ́kàn rẹ̀ sọ ọ́ dẹrú.
Àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ Sandra fojú rẹ̀ rí màbo, àmọ́ òun náà kò gbojú bọ̀rọ̀ fún wọn. Ó gbàdúrà tọkàntọkàn pé kí Jèhófà ran òun lọ́wọ́ láti borí wọn ó sì wá àánú rẹ̀. (Sáàmù 55:22; Jákọ́bù 4:8) Nígbà tí Sandra wá rí i pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ òun, ó yí ọ̀nà tó gbà ń gbé ìgbésí ayé rẹ̀ padà. Ó sọ pé: “Mo láyọ̀ pé mò ń fi gbogbo àkókò mi kọ́ àwọn ẹlòmíràn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.” Sandra ní àǹfààní láti ran ẹ̀gbọ́n rẹ̀ obìnrin àti àbúrò rẹ̀ obìnrin lọ́wọ́ láti mọ Jèhófà. Bó ṣe ń bá a lọ ní ‘ṣíṣe ohun rere,’ bẹ́ẹ̀ náà ló tún ń yọ̀ǹda láti fi ìmọ̀ ìṣègùn tó ní ṣèrànwọ́ láwọn àpéjọ àgbègbè àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà.—Gálátíà 6:10.
Àwọn nǹkan tí Sandra ti jingíri sínú rẹ̀ tẹ́lẹ̀ wá ńkọ́? Ó fi ìgboyà sọ pé: “Ọkàn mi ti mọ́ báyìí. N kì í mutí mọ́, n kì í mu sìgá tàbí lo oògùn olóró mọ́. Kò sóhun tí mo fẹ́ fi wọ́n ṣe. Ọwọ́ mi ti ba ohun tí mò ń wá.”
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 9]
“Ọwọ́ mi ti ba ohun tí mò ń wá”
[Box on p̣age 9]
Àwọn Ìlànà Bíbélì Tó Ṣe É Mú Lò
Díẹ̀ lára àwọn ìlànà Bíbélì tó ti ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ láti jáwọ́ nínú àwọn ohun tó ń sọni di ẹlẹ́gbin tó ti mọ́ wọn lára rèé:
“Ẹ jẹ́ kí a wẹ ara wa mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀gbin ti ẹran ara àti ti ẹ̀mí, kí a máa sọ ìjẹ́mímọ́ di pípé nínú ìbẹ̀rù Ọlọ́run.” (2 Kọ́ríńtì 7:1) Àwọn tó ti wẹ ara wọn mọ́ kúrò nínú àwọn ohun tó ń sọni di ẹlẹ́gbin, tí wọ́n ń yẹra fún àwọn ìwà tí kò mọ́ ni Ọlọ́run ń bù kún.
“Ìbẹ̀rù Jèhófà túmọ̀ sí kíkórìíra ohun búburú.” (Òwe 8:13) Ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ fun Ọlọ́run ń ranni lọ́wọ́ láti jáwọ́ nínú àwọn ìwà tí kò dára, títí kan lílo oògùn olóró. Yàtọ̀ sí pé èyí á múnú Jèhófà dùn, ẹni náà tó yí padà kò ní lè kó àwọn àrùn burúkú tó máa ń dáyà foni.
‘Ẹ wà ní ìtẹríba kí ẹ sì jẹ́ onígbọràn sí àwọn ìjọba àti àwọn aláṣẹ gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso.’ (Títù 3:1) Ọ̀pọ̀ ibi ló ti lòdì sófin láti lo àwọn oògùn kan tàbí kéèyàn ní wọn lọ́wọ́. Àwọn Kristẹni tòótọ́ kì í ní àwọn oògùn tí òfin kà léèwọ̀ lọ́wọ́ wọn kì í sì í lò wọ́n.