Ǹjẹ́ Ọlọ́run Tiẹ̀ Bìkítà Nípa Wa?
ǸJẸ́ ìbànújẹ́ máa ń dorí ẹ kodò nítorí àwọn ìṣòro ìdílé, àìlera, ìṣòro iṣẹ́, tàbí àwọn ojúṣe mìíràn tó fakíki? Ohun tó ń ṣe ọ̀pọ̀ èèyàn náà nìyẹn. Àbí ta ló lè sọ pé ìwà ìrẹ́nijẹ, ìwà ọ̀daràn, àti ìwà ipá tó wà nínú ayé lónìí kò kan òun? Láìsí àní-àní, bí Bíbélì ṣe sọ ọ̀rọ̀ náà gẹ́lẹ́ ló rí pé: “Gbogbo ìṣẹ̀dá ń bá a nìṣó ní kíkérora pa pọ̀ àti ní wíwà nínú ìrora pa pọ̀ títí di ìsinsìnyí.” (Róòmù 8:22) Abájọ tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi ń béèrè pé: ‘Ǹjẹ́ Ọlọ́run tiẹ̀ bìkítà? Ṣé ó tiẹ̀ máa ràn wá lọ́wọ́?’
Sólómọ́nì ọlọgbọ́n Ọba nì sọ fún Ọlọ́run nínú àdúrà pé: “Ìwọ fúnra rẹ nìkan ṣoṣo ni ó mọ ọkàn-àyà ọmọ aráyé ní àmọ̀dunjú.” Sólómọ́nì gbà gbọ́ pé kì í ṣe pé Ọlọ́rùn wulẹ̀ mọ̀ wá nìkan, àmọ́ ó tún bìkítà nípa wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan pẹ̀lú. Ìyẹn ló fi lè sọ fún Ọlọ́run pé kí ó “gbọ́ láti ọ̀run” kí ó sì dáhùn àdúrà olúkúlùkù tí ó jẹ́ olùbẹ̀rù Ọlọ́run, ìyẹn ẹni tí ó ṣí “ìyọnu àjàkálẹ̀ tirẹ̀ àti ìrora tirẹ̀” payá fún Ọlọ́run.—2 Kíróníkà 6:29, 30.
Jèhófà Ọlọ́run bìkítà nípa wa lóde òní pẹ̀lú, ó sì ń ké sí wa pé kí a rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí òun nínú àdúrà. (Sáàmù 50:15) Ó ṣèlérí pé òun á dáhùn àwọn àdúrà àtọkànwá tó bá ìfẹ́ òun mu. (Sáàmù 55:16, 22; Lúùkù 11:5-13; 2 Kọ́ríńtì 4:7) Dájúdájú, Jèhófà máa ń fetí sí “àdúrà yòówù, ìbéèrè fún ojú rere yòówù tí ó bá wáyé láti ọ̀dọ̀ ẹnikẹ́ni tàbí láti ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn ènìyàn [rẹ̀].” Nítorí náà, tá a bá gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run, tá a gbàdúrà pé kó ràn wá lọ́wọ́, tá a sì sún mọ́ ọn pẹ́kípẹ́kí, yóò fi ìfẹ́ bójú tó wa, yóò sì máa tọ́ wa sọ́nà. (Òwe 3:5, 6) Jákọ́bù, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó kọ Bíbélì mú un dá wa lójú kedere pé: “Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ yín.”—Jákọ́bù 4:8.