Ohun Tó Lè Mú Kí Ẹ̀mí Ẹni Gùn Kéèyàn sì Láyọ̀
“GBOGBO èèyàn ló fẹ́ dàgbà; àmọ́ kò sẹ́ni tó fẹ́ darúgbó.” Àwọn kan ló máa ń pa á lówe bẹ́ẹ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn tí ò ní pẹ́ fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́ rò pé tó bá yá àwọn á túbọ̀ ráyè ṣe ohun tí àwọn bá fẹ́, àwọn ò sì ní fi bẹ́ẹ̀ ní ohun púpọ̀ láti bójú tó. Síbẹ̀, wọ́n máa ń bẹ̀rù pé ó ṣeé ṣe kí àwọn di ẹni tí ò wúlò, tí ò sì já mọ́ nǹkan kan mọ́. Wọ́n tún máa ń ṣàníyàn pé àwọn èèyàn á pa àwọn tì, ìbànújẹ́ á sorí àwọn kodò, àìsàn á sì sọ àwọn dìdàkudà.
Kí wá ni ohun tó lè mú ìgbésí ayé ẹni dùn kó sì lárinrin? Tọmọdé tàgbà ló máa ń láyọ̀ tí wọ́n bá ní àwọn ọ̀rẹ́ gidi tí ìdílé wọn sì fẹ́ràn wọn. Àmọ́, kì í ṣe ohun táwọn ẹlòmíràn ṣe láti múnú àwọn àgbàlagbà dùn ló ṣe pàtàkì jù. Ohun tó ṣe pàtàkì jù ni ohun tí àwọn àgbàlagbà fúnra wọn lè ṣe fún àwọn ẹlòmíràn.
Nínú ìwádìí kan tó gba àkókò gígùn, táwọn olùṣèwádìí ṣe láti ṣàyẹ̀wò àwọn tọkọtaya àgbàlagbà tí iye wọn jẹ́ irínwó ó lé mẹ́tàlélógún [423], wọ́n rí i pé “ṣíṣe ìrànlọ́wọ́ fún àwọn ẹlòmíràn lè mú kí ẹ̀mí àwa fúnra wa gùn sí i.” Stephanie Brown, ẹni tó darí ìwádìí náà ṣàlàyé pé: “Àwọn ẹ̀rí tá a rí yìí fi hàn pé kì í ṣe ohun tí à ń jàǹfààní nínú àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn ló ṣe pàtàkì jù; ohun tó ṣe pàtàkì jù ni ohun tí a bá ṣe fún àwọn ẹlòmíràn.” Ara irú àwọn ohun tá a lè ṣe fún àwọn ẹlòmíràn ni bíbá wọn ṣe iṣẹ́ ilé, bíbá wọn bójú tó ọmọ, lílọ jíṣẹ́ fún wọn, fífi ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ gbé wọn tàbí títẹ́tí sí ẹnì kan tó ń sọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ fún wa.
Ní nǹkan bí ẹgbàá [2,000] ọdún sẹ́yìn, Jésù Kristi sọ pé: “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.” (Ìṣe 20:35) Kì í ṣe jíjẹ́ olówó tabua, tàbí lílo àwọn oògùn tàbí jíjẹ àwọn oúnjẹ tí ń gbógun ti ọjọ́ ogbó ló lè mú kí ẹ̀mí ẹni gùn kéèyàn sì láyọ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó lè jẹ́ kí èyí ṣeé ṣe ni pé kí ọwọ́ ẹni dí, kéèyàn sì máa lo àkókò, agbára àti okun rẹ̀ láti fi ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́.
Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn ohun tá a mẹ́nu kàn wọ̀nyí nìkan kò tó láti gbà wá lọ́wọ́ ọjọ́ ogbó, àìsàn àti ikú. Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló máa fòpin sí àwọn nǹkan wọ̀nyí. Nínú ìjọba náà, kò ní sí àìsàn mọ́, kódà, ‘ikú pàápàá kì yóò sí mọ́.’ (Ìṣípayá 21:3, 4; Aísáyà 33:24) Dájúdájú, tayọ̀tayọ̀ làwọn èèyàn onígbọràn yóò fi máa gbé títí láé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé. (Lúùkù 23:43) Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò dùn láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti mọ ohun tí Bíbélì sọ pé ó lè mú kí ẹ̀mí ẹni gùn kéèyàn sì láyọ̀.