Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Ròyìn
Lẹ́tà Tí Alejandra Kọ
Ó TI pẹ́ tí lẹ́tà kíkọ ti jẹ́ ọ̀nà tó gbéṣẹ́ gan-an láti jẹ́rìí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìgbà mìíràn wà téèyàn ò ní mọ ohun tó máa jẹ́ àbájáde lẹ́tà tóun kọ, àmọ́ àwọn tí ò yéé fi lẹ́tà kíkọ wàásù ti rí ìbùkún yàbùgà-yabuga gbà. Wọ́n rántí ìmọ̀ràn ọlọ́gbọ́n tí Bíbélì fúnni pé: “Ní òwúrọ̀, fún irúgbìn rẹ àti títí di ìrọ̀lẹ́, má ṣe jẹ́ kí ọwọ́ rẹ sinmi; nítorí ìwọ kò mọ ibi tí èyí yóò ti ṣe àṣeyọrí sí rere, yálà níhìn-ín tàbí lọ́hùn-ún, tàbí kẹ̀, bóyá àwọn méjèèjì ni yóò dára bákan náà.”—Oníwàásù 11:6.
Alejandra, ọmọbìnrin Ẹlẹ́rìí kan tó ti ń sìn ní ẹ̀ka ilé iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Mẹ́síkò láti nǹkan bí ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn, ń gba ìtọ́jú oníkẹ́míkà nítorí àrùn jẹjẹrẹ tó ní. Àìsàn náà ti wọ̀ ọ́ lára gan-an débi pé kò lágbára láti ṣe àwọn nǹkan tó máa ń ṣe lójoojúmọ́ tẹ́lẹ̀ mọ́. Àmọ́, nítorí pé Alejandra ò fẹ́ pa iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ tì, ó wá pinnu láti máa kọ lẹ́tà. Ó kọ nípa ètò ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tá a máa ń ṣe nílé àwọn èèyàn lọ́fẹ̀ẹ́ sínú lẹ́tà náà, ó si kọ nọ́ńbà tẹlifóònù màmá rẹ̀ sí i. Ó wá kó àwọn lẹ́tà náà fún màmá rẹ̀ pé kó máa fi há ẹnu ọ̀nà àwọn tí kò bá bá nílé nígbà tó bá ń wàásù láti ilé dé ilé.
Láàárín àkókò yẹn, Diojany, ọ̀dọ́mọbìnrin kan láti Guatemala, lọ ṣe ọmọ ọ̀dọ̀ nílùú Cancún, lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò. Nígbà tó wà níbẹ̀, ó bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pàdé, ó sì ń gbádùn bí òun àtàwọn ṣe jọ máa ń jíròrò Bíbélì. Nígbà tó yá, àwọn ọ̀gá rẹ̀ pinnu láti kó lọ sí Ìlú Mẹ́síkò, wọ́n sì fẹ́ kí ọmọbìnrin yìí tẹ̀ lé àwọn lọ. Diojany lóun ò lọ nítorí pé ìyẹn ò ní jẹ́ kó rí àwọn Ẹlẹ́rìí bá sọ̀rọ̀ mọ́.
Àwọn ọ̀gá rẹ̀ wá fi í lọ́kàn balẹ̀, wọ́n sọ fún un pé: “Má fòyà, ibi gbogbo làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wà. Bá a bá ṣe ń débẹ̀ la máa wá wọn kàn.” Ohun tí wọ́n sọ yẹn múnú Diojany dùn, ó sì gbà láti bá wọn lọ. Gbára tí wọ́n dé Ìlú Mẹ́síkò làwọn ọ̀gá Diojany bẹ̀rẹ̀ sí í wá àwọn Ẹlẹ́rìí. Àmọ́ nítorí àwọn ìdí kan, wọn ò rí wọn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà nílùú náà lákòókò yẹn lé ní ọ̀kẹ́ méjì ó lé ẹgbẹ̀rún [41,000], ìjọ àádọ́rin dín lẹ́gbẹ̀rin [730] ló sì wà níbẹ̀.
Láìpẹ́, Diojany bẹ̀rẹ̀ sí í rẹ̀wẹ̀sì nítorí pé kò rí àwọn Ẹlẹ́rìí kí wọ́n lè máa bá ìjíròrò Bíbélì náà lọ. Ní ọjọ́ kan, aya ọ̀gá rẹ̀ wá bá a, ó ní: “Diojany! Ọlọ́run rẹ ti gbọ́ àdúrà rẹ.” Ó fi lẹ́tà kan lé e lọ́wọ́, ó sì sọ pé: “Àwọn Ẹlẹ́rìí ti fi lẹ́tà yìí sílé dè ọ.” Alejandra ló kọ lẹ́tà náà.
Diojany wá ìyá Alejandra àti Blanca, àbúrò rẹ̀ obìnrin kàn, ó sì gbà pé kí wọ́n máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ bíi mélòó kan, ó rí Alejandra, inú àwọn méjèèjì sì dùn láti fojú kan ara wọn. Alejandra gbà á níyànjú pé kó tẹra mọ́ ẹ̀kọ́ Bíbélì tó ń kọ́ kó lè tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí.
Ní oṣù díẹ̀ lẹ́yìn ìgbà yẹn, Alejandra kú ní July 2003, àpẹẹrẹ rere sì ni ìgbàgbọ́ àti ìgboyà rẹ jẹ́ fún àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́. Orí ọ̀pọ̀ èèyàn wú nígbà tí wọ́n rí Diojany níbi ìsìnkú náà, tí wọ́n sì gbọ́ nígbà tó sọ pé: “Àpẹẹrẹ àtàtà ni Alejandra àti ìdílé rẹ̀ jẹ́ fún mi. Mo ti pinnu láti máa sin Jèhófà kí n sì ṣe ìrìbọmi láìpẹ́. Inú mi á má dùn o, nígbà tí mo bá rí Alejandra nínú Párádísè tó ń bọ̀!”
Bẹ́ẹ̀ ni o, lẹ́tà kan lè má jọ èèyàn lójú. Àmọ́, ẹ ò ri pé ó lè ní ipa rere tí yóò wà pẹ́ títí!