Ǹjẹ́ Ó Yẹ Ká Máa Bẹ̀rù Pé Kristi Ń Bọ̀?
KÍ LÈRÒ ẹ nípa bíbọ̀ Jésù Kristi? Ṣé èrò ẹ ni pé tí Kristi bá dé, ó máa mú ègbé, ìparun àti ìyà wá sórí ọmọ aráyé? Àbí ńṣe lo rò pé ó máa yanjú gbogbo ìṣòro tọ́mọ aráyé ń bá yí? Ṣé ká máa bẹ̀rù bíbọ̀ Kristi ni? Àbí ká máa fojú sọ́nà fún un?
Bíbélì sọ nípa bíbọ̀ Kristi pé: “Wò ó! Ó ń bọ̀ pẹ̀lú àwọsánmà, gbogbo ojú ni yóò sì rí i, . . . gbogbo ẹ̀yà ilẹ̀ ayé yóò sì lu ara wọn nínú ẹ̀dùn-ọkàn nítorí rẹ̀.” (Ìṣípayá 1:7) Bíbọ̀ tí Jésù ń bọ̀ yìí tọ́ka sí ìgbà tó máa wá lọ́jọ́ iwájú láti san èrè fáwọn olódodo kó sì fìyà jẹ àwọn èèyàn búburú.
Àpọ́sítélì Jòhánù ò bẹ̀rù rárá pé Kristi ń bọ̀, kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló ń fojú sọ́nà fún un. Lẹ́yìn tí Jòhánù rí ìran nípa bíbọ̀ Jésù àti nípa ohun tí Jésù máa ṣe tó bá dé, ó gbàdúrà tọkàntọkàn pé: “Máa bọ̀, Jésù Olúwa.” (Ìṣípayá 22:20) Kí wá nìdí tí “gbogbo ẹ̀yà ilẹ̀ ayé [fi] lu ara wọn nínú ẹ̀dùn-ọkàn nítorí rẹ̀”? Báwo ni “gbogbo ojú” ṣe máa rí Jésù? Kí ni Kristi máa ṣe tó bá dé? Tá a bá gbà gbọ́ pé Jésù máa wá, àǹfààní wo nìyẹn máa ṣe fún wa nísinsìnyí? Àpilẹ̀kọ tó kàn máa dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí.