Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn Ti Ilẹ̀ Yúróòpù Dá Wọn Láre
LỌ́JỌ́ kọkànlá oṣù kìíní ọdún 2007, gbogbo àwọn adájọ́ ní Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù, tó wà nílùú Strasbourg nílẹ̀ Faransé, panu pọ̀ dá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ilẹ̀ Rọ́ṣíà láre lórí ẹjọ́ tí wọ́n pe ìjọba ilẹ̀ Rọ́ṣíà. Ẹjọ́ tí ilé ẹjọ́ yìí dá fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pẹ̀lú lẹ́tọ̀ọ́ sí òmìnira ìsìn, àti pé ó jẹ́ ẹ̀tọ́ wọn pé kí ilé ẹjọ́ gbọ́ wọn láìsí ojúsàájú. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó tiẹ̀ mú káwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yẹn pẹjọ́.
Ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan wà nílùú Chelyabinsk lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà. Àwọn adití ló pọ̀ jù nínú ìjọ náà. Gbọ̀ngàn tí wọ́n háyà ní ilé ẹ̀kọ́ ẹ̀kọ́ṣẹ́ kan ni wọ́n ti máa ń ṣèpàdé. Lọ́jọ́ Sunday, ọjọ́ kẹrìndínlógún oṣù kẹrin ọdún 2000, ọ̀gá àgbà ilé iṣẹ́ Àjọ Tó Ń Rí Sọ́ràn Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn àtàwọn ọlọ́pàá mẹ́ta kan tí ọ̀kan lára wọn ò wọṣọ ọlọ́pàá, lọ dá ìpàdé tí ìjọ náà ń ṣe lọ́wọ́ dúró. Wọ́n ní wọ́n ń ṣèpàdé láìgbàṣẹ. Ẹ̀sùn irọ́ sì ni. Ẹ̀tanú ló mú kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀, pàápàá ọ̀gá àgbà náà. Nígbà tó wá di ọjọ́ kìíní oṣù karùn-ún ọdún 2000, àwọn tó ni gbọ̀ngàn náà fagi lé àdéhùn tí wọ́n bá àwọn Ẹlẹ́rìí náà ṣe, wọ́n ní kí wọ́n má lo ibẹ̀ mọ́.
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ fẹjọ́ sun olùpẹ̀jọ́ tó wà nílùú Chelyabinsk, àmọ́ nǹkan kan ò tẹ̀yìn rẹ̀ yọ. Bẹ́ẹ̀ kẹ̀, Àdéhùn Àjọṣe fún Ìgbélárugẹ Ẹ̀tọ́ àti Òmìnira Ọmọnìyàn àti Òfin Ilẹ̀ Rọ́ṣíà sọ pé àwọn èèyàn lómìnira láti ṣẹ̀sìn kí wọ́n sì pé jọ pọ̀. Nítorí náà, àwọn Ẹlẹ́rìí gbé ẹjọ́ náà lọ sílé ẹjọ́ ìbílẹ̀ àti ti ìpínlẹ̀. Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, ilé ẹjọ́ gíga jù lọ nílẹ̀ Rọ́ṣíà ti dá ẹjọ́ kan ní ọgbọ̀n ọjọ́ oṣù keje ọdún 1999, pé: “Níbàámu pẹ̀lú Òfin Ilẹ̀ Rọ́ṣíà lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀rí ọkàn àti ìpéjọpọ̀ àwọn ẹlẹ́sìn, gbólóhùn náà tó sọ pé, ‘láìsí ìdílọ́wọ́ kankan,’ túmọ̀ sí pé, kò pọn dandan káwọn ẹlẹ́sìn gba àṣẹ lọ́dọ̀ ìjọba tàbí kí ìjọba fún wọn láṣẹ kí wọ́n tó lè ṣe ayẹyẹ ìsìn wọn níbi tí wọ́n dìídì yà sọ́tọ̀ [fún ayẹyẹ náà].” (Fúnra wọn ni wọ́n fi ọ̀rọ̀ yìí sínú àkámọ́.) Pẹ̀lú ìdájọ́ tí ilé ẹjọ́ gíga jù lọ ti ṣe yìí náà, ńṣe ni ilé ẹjọ́ ìbílẹ̀ àti ti ìpínlẹ̀ tú ẹjọ́ táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pè ká.
Lọ́jọ́ kẹtàdínlógún oṣù kejìlá ọdún 2001, àwọn Ẹlẹ́rìí gbé ẹjọ́ náà lọ sí Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù. Ọjọ́ kẹsàn-án oṣù kẹsàn-án ọdún 2004 ni ilé ẹjọ́ yẹn kọ́kọ́ gbọ́ ẹjọ́ náà. Díẹ̀ lára ìdájọ́ tí ilé ẹjọ́ náà wá ṣe lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn rèé:
“Ilé ẹjọ́ yìí rí i pé bí àwọn aláṣẹ ṣe lọ dá ìpàdé àwọn tó gbé ẹjọ́ wá dúró nígbà tí ìpàdé náà ṣì ń lọ lọ́wọ́ ní ọjọ́ kẹrìndínlógún oṣù kẹrin ọdún 2000, ńṣe ni wọ́n fi ẹ̀tọ́ àwọn èèyàn náà dù wọ́n, ìyẹn òmìnira tí wọ́n ní láti máa jọ́sìn.”
“Kò sófin kankan tó fàyè gba ẹnikẹ́ni láti lọ dá ìpàdé ìsìn táwọn kan ń ṣe níbi tí wọn háyà lọ́nà tó bófin mu dúró.”
“[Ilé ẹjọ́ yìí] rí i pé ilé ẹjọ́ gíga jù lọ ilẹ̀ Rọ́ṣíà ti dá àwọn ẹjọ́ kan tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, pé kò pọn dandan káwọn onísìn gba àṣẹ lọ́dọ̀ ìjọba tàbí kí ìjọba fún wọn láṣẹ kí wọ́n tó lè pé jọ pọ̀ láti jọ́sìn.”
“Nítorí náà, ọ̀gá àgbà náà àtàwọn tí wọ́n jọ dá ìpàdé àwọn tó gbé ẹjọ́ wá lọ́jọ́ kẹrìndínlógún oṣù kẹrin ọdún 2000 dúró, rú Òfin Kẹsàn-án [òmìnira ìsìn] tó wà nínú ìwé òfin tí wọ́n ṣe nígbà Àdéhùn Àjọṣe fún Ìgbélárugẹ Ẹ̀tọ́ àti Òmìnira Ọmọnìyàn.”
“Ilé ẹjọ́ yìí rí i pé ilé ẹjọ́ ìbílẹ̀ àti ti ìpínlẹ̀ ní ilẹ̀ Rọ́ṣíà kò ṣe ojúṣe wọn . . . wọn ò fẹ̀rí hàn pé àwọn ti gbọ́ ẹjọ́ ìhà méjèèjì láìsí ojúsàájú. Wọ́n rú Òfin Kẹfà [ìgbẹ́jọ́ láìsí ojúsàájú jẹ́ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn] tó wà nínú ìwé òfin tí wọ́n ṣe nígbà Àdéhùn Àjọṣe fún Ìgbélárugẹ Ẹ̀tọ́ àti Òmìnira Ọmọnìyàn.”
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run tó jẹ́ kí wọ́n borí ní Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù. (Sáàmù 98:1) Ibo ni ìdájọ́ ilé ẹjọ́ náà máa ṣàǹfààní dé? Ọ̀gbẹ́ni Joseph K. Grieboski tó jẹ́ ọ̀gá àgbà Àjọ Tó Ń Rí Sọ́ràn Ìsìn àti Ti Aráàlú sọ pé: “Èyí jẹ́ ìdájọ́ pàtàkì mìíràn tó máa mú kí òmìnira ìsìn wà jákèjádò ilẹ̀ Yúróòpù, nítorí pé ìdájọ́ náà máa mú káwọn èèyàn ní òmìnira ìsìn ní gbogbo orílẹ̀-èdè tó wà lábẹ́ Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù.”