Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Ǹjẹ́ Òwe 22:6 mú un dáni lójú pé táwọn òbí tó jẹ́ Kristẹni bá tọ́ àwọn ọmọ wọn dáadáa wọn ò ní kúrò ní ọ̀nà Jèhófà?
Ẹsẹ yìí kà pé: “Tọ́ ọmọdékùnrin ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀nà tí yóò tọ̀; nígbà tí ó bá dàgbà pàápàá, kì yóò yà kúrò nínú rẹ̀.” Ibi tí wọ́n bá tẹ igi kékeré kan sí máa ń nípa lórí bí igi náà ṣe máa dàgbà, bẹ́ẹ̀ náà làwọn ọmọ tí wọ́n tọ́ dáadáa ṣe sábà máa ń bá a lọ láti sin Jèhófà nígbà tí wọ́n bá dàgbà. Gbogbo òbí ló mọ̀ pé títọ́ ọmọ lọ́nà yìí máa ń gba àkókò àti ọ̀pọ̀ ìsapá. Káwọn òbí tó lè sọ àwọn ọmọ wọn di ọmọ ẹ̀yìn Kristi, wọ́n ní láti fara balẹ̀ kọ́ wọn, kí wọ́n máa gbà wọ́n níyànjú, kí wọ́n sì máa fi ìbáwí tọ́ wọn sọ́nà. Àwọn òbí sì tún ní láti fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fáwọn ọmọ. Wọ́n ní láti fìfẹ́ ṣe èyí fún ọ̀pọ̀ ọdún láìdáwọ́dúró.
Àmọ́, tọ́mọ kan ò bá sin Jèhófà mọ́, ǹjẹ́ èyí túmọ̀ sí pé àwọn òbí ni kò tọ́ ọ dáadáa? Nígbà mìíràn, ìsapá àwọn òbí lè kù díẹ̀ káàtó bí wọ́n ṣe ń tọ́ ọmọ wọn nínú ìbáwí àti èrò Jèhófà. (Éfésù 6:4) Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe pé òwe yìí ń sọ pé téèyàn bá tọ́ ọmọ rẹ̀ dáadáa, ó di dandan kọ́mọ náà jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run. Àwọn òbí kò lè sọ àwọn ọmọ wọn di ohunkóhun tí wọ́n bá fẹ́. Bíi tàwọn àgbà, àwọn ọmọ lómìnira, àwọn ló sì máa fúnra wọn yan ohun tí wọ́n máa fi ayé wọn ṣe. (Diutarónómì 30:15, 16, 19) Kò sí bí àwọn òbí ṣe lè sapá tó, àwọn ọmọ kan máa ń di aláìṣòótọ́ bíi ti Sólómọ́nì tó kọ ẹsẹ ìwé mímọ́ tá à ń gbé yẹ̀ wò yìí. Kódà Jèhófà láwọn ọmọ tí wọ́n di aláìṣòótọ́.
Nítorí náà, ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí kò túmọ̀ sí pé gbogbo ìgbà ni ọmọ “kì yóò yà kúrò nínú rẹ̀,” ṣùgbọ́n lọ́pọ̀ ìgbà bó ṣe máa ń rí ni pé àwọn ọmọ kì í yà kúrò nínú ẹ̀kọ́ náà. Ìṣírí ńlá gbáà mà lèyí jẹ́ fáwọn òbí o! Ó yẹ kínú àwọn òbí máa dùn pé táwọn bá tọ́ ọmọ wọn dáadáa ní ọ̀nà Jèhófà, ìsapá wọn yóò yọrí sí rere. Níwọ̀n bí iṣẹ́ àwọn òbí ti ṣe pàtàkì, tí ipa tí wọ́n ń ní lórí àwọn ọmọ wọn kò sì kéré, a gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n fọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́ wọn.—Diutarónómì 6:6, 7.
Kódà nígbà táwọn ọmọ ò bá sin Jèhófà mọ́, àwọn òbí tí wọ́n fi tọkàntọkàn tọ́ àwọn ọmọ wọn ṣì lè nírètí pé tó bá yá orí àwọn ọmọ náà á padà wálé. Nítorí pé ẹ̀kọ́ Bíbélì lágbára, àwọn ọmọ kì í sì tètè gbàgbé ẹ̀kọ́ táwọn òbí wọn bá kọ́ wọn.—Sáàmù 19:7.