Báwo La Ṣe Lè Jẹ́ Aláàánú Nínú Ayé Oníwà-Ìkà Yìí?
ÀÌSÀN ibà tó lágbára dá ọ̀gbẹ́ni kan dùbúlẹ̀ nílùú Bùrúńdì. Àfi kí wọ́n yáa tètè gbé e lọ sí Ọsibítù. Ṣùgbọ́n, báwo ló ṣe máa débẹ̀? Kò sí mọ́tò kankan tó lè gbé e lọ nítòsí. Àmọ́, àwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ méjì kan wá ràn án lọ́wọ́. Wọ́n gbé ọ̀gbẹ́ni yìí sórí kẹ̀kẹ́, ó sì ju wákàtí márùn-ún lọ tí wọ́n fi ń tì í lọ lórí òkè, láìka bó ṣe rẹ̀ wọ́n tó sí. Nígbẹ̀yìn gbẹ́yín, wọ́n gbé e dé ìdí bọ́ọ̀sì kan tó wá gbé e dé ọsibítù tó sún mọ́ wọn jù lọ. Kò pẹ́ sígbà yẹn tára ẹ̀ fi yá.
Lẹ́yìn tí ìjì líle kan jà ní August 2005 lágbègbè tókun ti pín ààlà ilẹ̀ sí méjì níbi kan báyìí lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, àwọn ọkùnrin kan tí wọ́n yọ̀ǹda ara wọn láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ ṣàdédé rí ilé kan tí igi wó bò mọ́lẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ò mọ ẹni tó ni ilé yẹn, ọjọ́ kan gbáko làwọn ọkùnrin yẹn fi bá wọn gbé àwọn igi tó wó lu ilé náà kúrò tí wọ́n sì ń báwọn palẹ̀ àwọn pàǹtí tó wà níbẹ̀ mọ́. Onílé náà sọ pé: “Ẹnu mi ò gbọpẹ́ fóhun táwọn [èèyàn] wọ̀nyí ṣe. Mo mọrírì ẹ̀ gan-an ni.”
Ìròyìn kàyéfì nípa ìwà ìkà tó burú jáì la sábà máa ń gbọ́ lórí rédíò àti tẹlifíṣọ̀n. Èyí ló jẹ́ káwọn èèyàn máa sọ pé ojú àánú ti fọ́ tìkà ló kù. Síbẹ̀, àwọn èèyàn níbi gbogbo ṣì ń wá ẹni tó máa nífẹ̀ẹ́ wọn lójú méjèèjì, tó máa kó wọn mọ́ra, tá á sì máa bá wọn kẹ́dùn. Áà, ojú àánú mà ṣọ̀wọ́n o! Táwọn èèyàn bá bẹ̀rẹ̀ sí kọrin ‘àlàáfíà àti ìfẹ́ inú rere sí ènìyàn’ lákòókò Kérésìmesì, ńṣe lẹ máa rò pé wọ́n lójú àánú.—Lúùkù 2:14, Bibeli Mimọ.
Ká sòótọ́, ó lè má rọrùn láti jẹ́ aláàánú láyé oníwà-ìkà táwọn èèyàn ti kórìíra ara wọn yìí. Èrò tó wọ́pọ̀ láwùjọ ni pé ẹní bá ń hùwà ìkà ló lè rọ́wọ́ yọ. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà pé ó sàn kéèyàn jẹ́ oníwà ìkà ju kó jẹ́ aláàánú lọ. Ìwọra àti ìgbéra ẹni lárugẹ ni ò jẹ́ káwọn èèyàn lójú àánú mọ́.
Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi ń kọrin bámúbámú ni mo yó, tí wọn ò sì fẹ́ mọ́ bóyá ebi ń pa ẹnì kankan. Àwọn ọkùnrin tó gbajúmọ̀ nídìí eré ìdárayá àti eré ìnàjú làwọn èèyàn máa ń wò bí “akọni ẹ̀dá” tó rorò bí ataare. Báwọn olóṣèlú kan sì ṣe rí nìyẹn.
Torí náà ó yẹ ká béèrè pé: Kí nìdí tó fi yẹ ká jẹ́ ẹlẹ́yinjú àánú? Àǹfààní wo ló wà nínú kéèyàn jẹ́ olójú àánú? Àti pé, kí ló lè jẹ́ ká máa ṣojú àánú? Àpilẹ̀kọ tó kàn ló máa jíròrò àwọn ìbéèrè wọ̀nyí.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 3]
•Ṣé ìwà òmùgọ̀ ni kéèyàn jẹ́ aláàánú?
•Àǹfààní wo ló wà nínú kéèyàn jẹ́ olójú àánú?
•Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà máa fojú àánú hàn?