Ǹjẹ́ O Mọ̀?
Kí nìdí tó fi jẹ́ pé ọgbọ̀n owó fàdákà làwọn olórí àlùfáà fún Júdásì kó lè fi Jésù lé wọn lọ́wọ́?
Nígbà tí Júdásì lọ bi àwọn olórí àlùfáà pé kí ni wọ́n máa fún òun kóun lè fi Jésù lé wọn lọ́wọ́, “ọgbọ̀n ẹyọ fàdákà” ni wọ́n láwọn máa fún un. (Mátíù 26:14, 15) Ó jọ pé iye yìí fi hàn pé wọ́n kórìíra Jésù gan-an àti pé kò já mọ́ nǹkan kan lójú wọn.
Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ṣékélì fàdákà ni owó tí ẹsẹ Bíbélì yẹn ń sọ, torí irú owó yẹn làwọn Júù ń ná nígbà yẹn. Kí lèèyàn lè fi ọgbọ̀n ṣékélì rà láyé ìgbà yẹn? Òfin Mósè sọ pé, iye yẹn ni kí wọ́n máa ta ẹrú. Wọ́n sì tún lè fi ra ilẹ̀ kékeré kan.—Ẹ́kísódù 21:32; Mátíù 27:6, 7.
Nígbà tí wòlíì Sekaráyà ní káwọn ọmọ Ísírẹ́lì aláìṣòótọ́ san owó iṣẹ́ tóun ṣe gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn àwọn èèyàn Ọlọ́run fóun, “ọgbọ̀n ẹyọ fàdákà” ni wọ́n san fún un. Ṣe ni wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ láti fi tẹ́ wòlíì Ọlọ́run yìí, kí wọ́n lè fi hàn pé kò ju ẹrú kan lásán lójú wọn. Nítorí náà, Jèhófà pàṣẹ fún Sekaráyà pé: “Sọ ọ́ sí ibi ìṣúra—iye owó ọlọ́lá ńlá tí a fi díye lé mi ní ojú ìwòye wọn.” (Sekaráyà 11:12, 13) Irú ohun tí Sekaráyà ṣe ní ìgbọràn sí àṣẹ tí Ọlọ́run pa fún un yìí ni Júdásì náà ṣe sí owó tó gbà nígbà tó fi Ẹni tí Jèhófà yàn ṣe olùṣọ́ àgùntàn Ísírẹ́lì hàn.—Mátíù 27:5.
Kí ni “ìwé ẹ̀rí ìkọ̀sílẹ̀” tí Bíbélì sọ?
Òfin Mósè sọ pé: “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ọkùnrin kan mú obìnrin kan . . . tí ó sì fi í ṣe aya, yóò sì ṣẹlẹ̀ pé bí obìnrin náà kò bá rí ojú rere ní ojú rẹ̀ nítorí pé ọkùnrin náà rí ohun àìbójúmu kan níhà ọ̀dọ̀ rẹ̀, kí ọkùnrin náà kọ ìwé ẹ̀rí ìkọ̀sílẹ̀ fún un, kí ó sì fi í lé e lọ́wọ́, kí ó sì rán an lọ kúrò ní ilé rẹ̀.” (Diutarónómì 24:1) Kí ni ìwúlò ìwé ẹ̀rí ìkọ̀sílẹ̀ yẹn? Lóòótọ́, Ìwé Mímọ́ kò sọ ohun tí wọ́n máa kọ sínú ìwé ẹ̀rí náà, àmọ́ ó dájú pé ó máa jẹ́ ààbò fún obìnrin tí wọ́n kọ̀ sílẹ̀ náà, á sì jẹ́ kó rí ẹ̀tọ́ rẹ̀ gbà.
Lọ́dún 1951 sí ọdún 1952, wọ́n rí àwọn ohun àtayébáyé nínú hòrò kan lápá àríwá àgbègbè tí wọ́n ń pè ní Wadi Murabbaat, tó jẹ́ ojú odò kan tó ti gbẹ ní aṣálẹ̀ ilẹ̀ Júdà. Ìwé ẹ̀rí ìkọ̀sílẹ̀ tí wọ́n kọ lédè Árámáíkì lọ́dún 71 tàbí lọ́dún 72 Sànmánì Kristẹni sì wà lára onírúurú àwọn ìwé àfọwọ́kọ tí wọ́n rí níbẹ̀. Ìwé ẹ̀rí náà sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ kìíní oṣù Marheshvan, ìyẹn ọdún kẹfà táwọn Júù ti wà lẹ́nu ìdìtẹ̀ sí ìjọba Róòmù. Ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé, Jósẹ́fù ọmọ Naqsan tó ń gbé ìlú Màsádà kọ ìyàwó rẹ̀ Míríámù ọmọ Jónátánì láti ìlú Hanablata sílẹ̀. Obìnrin náà wá tipa bẹ́ẹ̀ lómìnira láti fẹ́ Júù èyíkéyìí tó bá wù ú. Jósẹ́fù dá nǹkan ìdána tí Míríámù kó wá sílé rẹ̀ padà fún un, ó sì san owó àwọn ohun ìní rẹ̀ tó bà jẹ́ padà ní ìlọ́po mẹ́rin. Jósẹ́fù fúnra rẹ̀ fọwọ́ sí ìwé ìkọ̀sílẹ̀ náà àtàwọn ẹlẹ́rìí mẹ́ta míì, ìyẹn Élíésérì ọmọ Malka; Jósẹ́fù ọmọ Malka àti Élíásárì ọmọ Hanana.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Àwọn hòrò tó wà ní Wadi Murabbaat
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Ìwé ẹ̀rí ìkọ̀sílẹ̀ tí wọ́n kọ lọ́dún 71 sí ọdún 72 Sànmánì Kristẹni
[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 25]
Àwọn hòrò: Todd Bolen/Bible Places.com; ìwé ẹ̀rí: Clara Amit, Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda Israel Antiquities Authority