Sún Mọ́ Ọlọ́run
Ó Mọbi Tágbára Wa Mọ
OBÌNRIN kan tó ti ń sapá láti múnú Ọlọ́run dùn sọ pé: “Mo sapá gidi gan-an, àmọ́ ó ṣì ń ṣe mí bíi pé mi ò tíì ṣe tó.” Ṣénú Jèhófà Ọlọ́run máa ń dùn sí ìsapá àtọkànwá táwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ bá ṣe? Ṣó máa ń ro ti pé agbára wọn ò tó nǹkan àti bí nǹkan ṣe máa ń rí fún wọn? Ká lè dáhùn àwọn ìbéèrè yìí, jẹ́ ká wo ohun tí Òfin Mósè sọ nípa àwọn ẹbọ kan táwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń rú bó ṣe wà nínú ìwé Léfítíkù 5:2-11.
Òfin yẹn sọ pé kí Ọlọ́run tó lè dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ji àwọn èèyàn, wọ́n gbọ́dọ̀ rú oríṣiríṣi ẹbọ. Nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ohun tí ẹsẹ Bíbélì yìí sọ nípa ẹ̀, ó ní láti jẹ́ pé onítọ̀hún ò mọ̀ lójú ẹsẹ̀ pé òun ti dẹ́ṣẹ̀. (Ẹsẹ 2-4) Tó bá ti wá mọ̀, ó gbọ́dọ̀ jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, kó sì rú ẹbọ ẹ̀bi, ohun tó sì máa fi rúbọ náà ni “abo ọ̀dọ́ àgùntàn tàbí abo ọmọ ewúrẹ́.” (Ẹsẹ 5, 6) Àmọ́ tónítọ̀hún bá jẹ́ tálákà tí kò lágbára láti fi àgùntàn tàbí ewúrẹ́ rúbọ ńkọ́? Ṣé Òfin yẹn fi dandan lé e pé kónítọ̀hún lọ yá ẹran yẹn, tíyẹn á sì wá di gbèsè sí i lọ́rùn? Ṣé dandan ni kó ṣiṣẹ́ kó lè rówó ra àgùntàn tàbí ewúrẹ́, kó sì máa wá tipa bẹ́ẹ̀ fi ètùtù tó yẹ kó ṣe fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ falẹ̀?
Òfin yẹn jẹ́ ká mọ bí àánú Jèhófà ṣe pọ̀ tó, ó ní: “Síbẹ̀síbẹ̀, bí agbára rẹ̀ kò bá ká àgùntàn, nígbà náà, kí ó mú oriri méjì tàbí ọmọ ẹyẹlé méjì wá fún Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ ẹ̀bi rẹ̀ fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti dá.” (Ẹsẹ 7) A tún lè tún gbólóhùn tó sọ pé, “bí agbára rẹ̀ kò bá ká” sọ lọ́nà yìí, “bí owó ọwọ́ rẹ̀ kò bá ká.” Tọ́mọ Ísírẹ́lì kan bá tálákà débi pé agbára rẹ̀ ò ká àgùntàn, nígbà náà inú Ọlọ́run dùn sóhun tí owó ọwọ́ rẹ̀ bá ká, ó lè jẹ́ oriri méjì tàbí ọmọ ẹyẹlé méjì.
Tó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹnì kan ò tiẹ̀ wá lágbára láti ra àwọn ẹyẹ méjì yẹn ńkọ́? Òfin náà sọ pé: “Nígbà náà, kí ó mú ìdá mẹ́wàá òṣùwọ̀n eéfà [kọ́ọ́bù mẹ́jọ tàbí mẹ́sàn-án] ìyẹ̀fun kíkúnná fún ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ wá, gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti dá.” (Ẹsẹ 11) Jèhófà gba àwọn tálákà láyè lábẹ́ Òfin láti rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ láìlo ẹ̀jẹ̀.a Torí pé ẹnì kan jẹ́ tálákà nílẹ̀ Ísírẹ́lì ò ní kó má lè rúbọ tàbí kò máà láǹfààní láti wà lálàáfíà pẹ̀lú Ọlọ́run.
Kí la kọ́ nípa Jèhófà látinú òfin tó ṣe lórí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀? Ó kọ́ wa pé ó jẹ́ Ọlọ́run aláàánú tó lóye wa, tó sì máa ń mọbi tágbára àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ mọ. (Sáàmù 103:14) Ó fẹ́ ká sún mọ́ òun, ká sì ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú òun bá a bá tiẹ̀ láwọn ìṣòro tá à ń bá yí, irú bí ọjọ́ ogbó, àìlera, bùkátà ìdílé àtàwọn bùkátà míì. Ara máa tù wá tá a bá mọ̀ pé inú Jèhófà Ọlọ́run máa dùn sí wa tá a bá ṣe gbogbo ohun tágbára wa ká.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ohun tó jẹ́ kí wọ́n máa lo ẹran láti fi rúbọ ni ìtóye ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, èyí tí Ọlọ́run kà sóhun mímọ́. (Léfítíkù 17:11) Ṣéyẹn wá túmọ̀ sí pé ìyẹ̀fun táwọn tálákà fi ń rúbọ ò já mọ́ nǹkan kan nìyẹn? Rárá o. Ó dájú pé Jèhófà mọrírì ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àti ẹ̀mí ìmúratán táwọn tó fi ìyẹ̀fun rúbọ ní. Yàtọ̀ síyẹn, ẹ̀jẹ̀ àwọn ẹran tí wọ́n bá fi rúbọ sí Ọlọ́run ní Ọjọ́ Ètùtù tí wọ́n máa ń ṣe lọ́dọọdún máa kó ẹ̀ṣẹ̀ tí gbogbo orílẹ̀-èdè náà dá pa pọ̀, títí kan tàwọn tálákà.—Léfítíkù 16:29, 30.