Bíbélì Máa Ń Yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà
BÁWO ni ìyá kan tó ń dá tọ́mọ ní orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà tí oògùn olóró ti di bárakú fún ṣe jáwọ́ nínú àṣà yìí, tó sì jẹ́ kí àárín òun àtàwọn ọmọ rẹ̀ dára sí i? Báwo ni ọkùnrin asùnta kan ní ìlú Kyoto, lórílẹ̀-èdè Japan, ṣe di ẹni tó ní okun àti ìgboyà láti jáwọ́ nínú ìwà tó sọ ọ́ di òtòṣì? Kí ló ran darandaran ọmọ orílẹ̀-èdè Ọsirélíà kan lọ́wọ́ tó fi jáwọ́ nínú ọtí àmujù? Jẹ́ ká gbọ́ ohun tí wọ́n sọ.
“Mo kẹ́kọ̀ọ́ pé ojúṣe mi ni láti gbọ́ bùkátà ara mi àti tàwọn ọmọ mi.”—NELLY BAYMATOVA
ỌJỌ́ ORÍ: 45
ORÍLẸ̀-ÈDÈ: RỌ́ṢÍÀ
IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀: ẸNI TÓ Ń LO OÒGÙN OLÓRÓ
ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ: Ìlú Vladikavkaz, tó jẹ́ olú ìlú Republic of North Ossetia (tó ń jẹ́ Alania ní báyìí) ni mo dàgbà sí. Ìdílé wa lówó lọ́wọ́ níwọ̀nba. Àmọ́, láìka gbogbo àwọn nǹkan ìní tá a ní sí, mi ò láyọ̀ ní ìgbésí ayé mi. Nígbà tí mo fi máa pé ẹni ọdún mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n [34], mo ti lọ́kọ méjì, a sì ti jà tú ká. Oògùn olóró ti di bárakú fún mi fún ọdún mẹ́wàá, láàárín àkókò yìí, ìgbà méjì ni mo gba ìtọ́jú nílé ìwòsàn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ní ọmọ méjì, mi ò nífẹ̀ẹ́ wọn, mi ò sì ráyè fún àwọn ọ̀rẹ́ tàbí ìdílé mi.
Màmá mi ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà yẹn, mo sì sábà máa ń gbọ́ nígbà tó bá ń sunkún nítorí mi, táá sì máa gbàdúrà pé kí Jèhófà ràn mí lọ́wọ́. Mo máa ń ronú pé: ‘Báwo ni màmá mi ṣe ń ṣe bí òpè báyìí? Báwo ni Jèhófà ṣe lè ràn mí lọ́wọ́?’ Mo gbìyànjú láti jáwọ́ nínú oògùn olóró. Àmọ́, agbára mi kò gbé e láti jáwọ́ nínú àṣà yìí fúnra mi. Lákòókò kan, ọjọ́ méjì gbáko ni mi ò fi lo oògùn olóró. Lẹ́yìn náà, mo pinnu láti jáde lọ, ni mo bá fo gba ojú fèrèsé. Mo ti gbàgbé pé àjà kejì ilé ni mo wà. Nígbà tí mo balẹ̀, apá àti ẹsẹ̀ mi kán, mo tún fi ẹ̀yìn ṣèṣe. Ohun tí mo lò lórí ibùsùn nílé ìwòsàn ju oṣù kan lọ.
Màmá mi dúró tì mí ní gbogbo àkókò tí mo fi ń gba ìtọ́jú, kò sì pẹ̀gàn mi. Ó mọ̀ pé nǹkan kan ló ń ṣe mí tí ìrònú mi kò fi já geere. Àmọ́, ó kó ìwé ìròyìn Jí!a bíi mélòó kan sẹ́gbẹ̀ẹ́ ibùsùn mi. Mo ka gbogbo rẹ̀ tán láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin, àwọn ìwé náà gbádùn mọ́ni, àwọn ìsọfúnni pàtàkì sì wà nínú wọn. Torí náà, mo pinnu láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí.
BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ: Ohun kan tí Bíbélì jẹ́ kí n mọ̀ ni pé mo ní ojúṣe tèmi. Dípò tí màá fi máa retí pé kí màmá mi máa gbọ́ bùkátà mi, mo kẹ́kọ̀ọ́ pé ojúṣe mi ni láti gbọ́ bùkátà ara mi àti tàwọn ọmọ mi. Lẹ́yìn tí mo ti fi ọ̀pọ̀ ọdún ṣe ìfẹ́ tara mi, kò mọ́ mi lára láti máa ṣe iṣẹ́ lójoojúmọ́.
Ìmọ̀ràn tó wà nínú Diutarónómì 6:5-7, tó sọ fún àwọn òbí pé kí wọ́n kọ́ àwọn ọmọ wọn nípa Ọlọ́run tún ràn mí lọ́wọ́ gan-an. Mo gbà pé mo máa jíhìn fún Ọlọ́run nípa bí mo bá ṣe tọ́ àwọn ọmọ mi méjèèjì. Kókó yìí mú kí n bẹ̀rẹ̀ sí í lo àkókò pẹ̀lú wọn, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í ní ìfẹ́ wọn bó ṣe yẹ.
Mo dúpẹ́ gan-an pé Jèhófà ti jẹ́ kí n láǹfààní láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nípa òun. Torí náà, mo ya ara mi sí mímọ́ fún un, mo ṣe ìrìbọmi, mo sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO TI RÍ: Nítorí pé mo ti kẹ́kọ̀ọ́ láti máa káwọ́ ìbínú mi, àjọṣe èmi àti màmá mi ti dára sí i. Àárín èmi àtàwọn ọmọ mi náà tún dára sí i.
Nítorí pé mo ti wá kórìíra àwọn nǹkan tí inú Ọlọ́run kò dùn sí, ọ̀pọ̀ ìṣòro tí mo ní nítorí ìgbésí ayé tí mò ń gbé tẹ́lẹ̀ ti pòórá. Ní báyìí, mò ń láyọ̀ tó pọ̀ nítorí pé mò ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nípa Jèhófà Ọlọ́run wa onífẹ̀ẹ́.
“Mo kíyè sí i pé mo ti rí ààbò ní ìgbésí ayé mi.”—MINORU TAKEDA
ỌJỌ́ ORÍ: 54
ORÍLẸ̀-ÈDÈ: JAPAN
IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀: ASÙNTA
ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ: Ìlú Yamaguchi ni mo dàgbà sí lọ́dọ̀ bàbá mi àti ìyá bàbá mi. Mi ò mọ màmá mi. Nígbà tí mo wà ní ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún, ìyá bàbá mi kú, èmi àti bàbá mi sì jọ ń gbé nìṣó. Iṣẹ́ alásè ni mò ń ṣe nílé iṣẹ́ oúnjẹ kan, wọ́n sì gba bàbá mi sí ilé iṣẹ́ náà. Àkókò iṣẹ́ wa yàtọ̀ síra, torí náà a kì í sábà rí ara wa. Ó wá mọ́ mi lára láti máa fi àkókò gígùn ṣiṣẹ́, èmi àtàwọn ọ̀rẹ́ mi sì máa ń mutí.
Bí ọjọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, iṣẹ́ mi sú mi. Èmi àti ọ̀gá mi sọ̀rọ̀ síra wa, mo túbọ̀ wá ń mu ọtí lámujù. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, nígbà tó kù díẹ̀ kí n pé ọmọ ọgbọ̀n ọdún, mo pinnu láti kúrò nílé lọ sí ibòmíì. Nígbà tí owó tán lọ́wọ́ mi, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ ní ilé tẹ́tẹ́ kan. Mo pàdé ọmọbìnrin kan, a sì ṣègbéyàwó. Àmọ́ lẹ́yìn ọdún méjì ààbọ̀, a fi ara wa sílẹ̀.
Ìbànújẹ́ dorí mi kodò, mi ò sì lè ṣe ìpinnu mọ́, mo sì jẹ gbèsè rẹpẹtẹ. Mo sá kúrò nítòsí àwọn tí mo jẹ lówó, mo sì lọ gbé ní ìlú ìbílẹ̀ mi fún ìgbà díẹ̀ lọ́dọ̀ bàbá mi, mo máa ń parọ́ fún bàbá mi, ìyẹn sì ba àárín wa jẹ́. Mo jí owó nínú yàrá bàbá mi, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í ta tẹ́tẹ́ láti máa fi gbọ́ bùkátà ara mi. Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, owó tán lọ́wọ́ mi pátápátá, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ní ibùdókọ̀ ojú irin fún àkókò díẹ̀. Mo kó lọ sí ìlú Hakata, nígbà tó sì yá, mo kó lọ sí ìlú Himeji, lásẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, mo lọ sí ìlú Kyoto. Mo sun ìta fún ọdún mélòó kan.
BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ: Ní ọdún 1999, nígbà tí mo wà níbi ìgbọ́kọ̀sí kan tó wà nítòsí Odò Kamogawa ní ìlú Kyoto, àwọn obìnrin méjì kan wá bá mi. Ọ̀kan lára wọn bi mí pé, “Ṣé wàá fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?” Mo gbà láti kẹ́kọ̀ọ́. Kristẹni kan nínú ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò náà tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú rẹ̀ kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́, ó sì jẹ́ kí n rí bó ṣe ṣe pàtàkì tó láti máa fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò. Wọ́n gbà mí nímọ̀ràn pé kí n wá iṣẹ́ kan ṣe àti ibi tí màá máa gbé. Láti tẹ́ wọn lọ́rùn, mo lọ sí ibi ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò bíi mélòó kan kí n lè rí iṣẹ́, bo tilẹ̀ jẹ́ pé níbẹ̀rẹ̀ kò ti ọkàn mi wá. Àmọ́ nígbà tó yá, mo bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà pé kí Ọlọ́run ràn mí lọ́wọ́, mo sì wá iṣẹ́ gan-an, títí mo fi rí i.
Àdúrà tún ràn mí lọ́wọ́ láti borí àdánwò tó le. Àwọn tí mo jẹ lówó wá mi kàn, wọ́n sì ní kí n san owó àwọn. Ìbànújẹ́ dorí mi kodò. Nínú ètò Bíbélì kíkà ojoojúmọ́ tí mo ṣe, mo ka ohun tó wà nínú Aísáyà 41:10. Nínú ẹsẹ yẹn, Ọlọ́run ṣèlérí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ pé: “Èmi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ ní ti tòótọ́.” Ìlérí yẹn fún mi lókun, ó sì jẹ́ kí n ní ìgboyà. Mo sapá gan-an láti máa fi ohun tí mọ kọ́ sílò, nígbà tó sì yá, mo yanjú gbèsè tí mo jẹ. Ní ọdún 2000, mo kúnjú ìwọ̀n láti ṣe ìrìbọmi, mo sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO TI RÍ: Ohun tí mo kọ́ nínú Bíbélì mú kí n sapá láti mú kí àárín èmi àti bàbá mi gún régé pa dà, bàbá mi sì dárí ohun tí mo ti ṣe jì mí. Inú rẹ̀ dùn gan-an pé mo ti kọ́ láti máa fi ìlànà Bíbélì ṣèwà hù. Mo kíyè sí i pé mo ti rí ààbò ní ìgbésí ayé mi torí pé mò ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì.
Síwájú sí i, mo ti lè ṣiṣẹ́ láti gbọ́ bùkátà ara mi. (Éfésù 4:28; 2 Tẹsalóníkà 3:12) Mo tún ti ní àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́ nínú ìjọ Kristẹni. (Máàkù 10:29, 30) Mo dúpẹ́ mo tún ọpẹ́ dá fún ohun tí Jèhófà ti kọ́ mi.
“Kò rọrùn fún mi láti ṣe àwọn àyípadà tó pọn dandan.”—DAVID HUDSON
ỌJỌ́ ORÍ: 72
ORÍLẸ̀-ÈDÈ: ỌSIRÉLÍÀ
IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀: Ọ̀MÙTÍPARA
ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ: Èmi ni ọmọ kọkànlá nínú àwọn ọmọ táwọn òbí mi Willie àti Lucy bí. Àárín àwọn ọmọ ìbílẹ̀ wa là ń gbé, ní agbègbè Aurukun, tó wà ní apá àríwá Queensland. Ẹ̀gbẹ́ Odò Archer tó jẹ́ agbègbè ẹlẹ́wà ni Aurukun wà, kò sì jìnnà sí òkun. Àwọn òbí wa kọ́ wa bí a ṣe lè ṣe ọdẹ àti bí a ṣe lè pa ẹja láti gbọ́ bùkátà ara wa. Lákòókò yẹn, a wà lábẹ́ òfin ìjọba tó sọ pé owó wọn nìkan ni ká máa ná, èyí kò sì jẹ́ ká lè ṣe káràkátà pẹ̀lú àwọn orílẹ̀-èdè míì.
Àwọn òbí mi rí i pé àwọn kọ́ mi ní ìwà rere, wọ́n sì kọ́ gbogbo àwa ọmọ wọn láti máa bọ̀wọ̀ fún àwọn àgbàlagbà tó wà lágbègbè wa, ká sì máa fún àwọn èèyàn lára ìwọ̀nba nǹkan tá a bá ní. Èyí mú ká máa wo àwọn àgbàlagbà tó wà lágbègbè wa gẹ́gẹ́ bíi bàbá, màmá àti ẹ̀gbọ́n wa.
Nígbà tí mo wà ní ọmọ ọdún méje, bàbá mi kú, a sì kó lọ sí àárín àwọn ọmọ ìbílẹ̀ wa tó wà ní Mapoon, ìyẹn sì jẹ́ nǹkan bí àádọ́jọ kìlómítà sí apá àríwá Aurukun. Nígbà tí mo di ọmọ ọdún méjìlá, mo bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ béèyàn ṣe ń da ẹṣin àti màlúù, mo sì ṣe iṣẹ́ darandaran ní ọ̀pọ̀ ọgbà màlúù títí di ìgbà tó kù díẹ̀ kí n pé àádọ́ta ọdún. Ìgbésí ayé darandaran kò rọrùn rárá. Lọ́pọ̀ ìgbà, mo máa ń mutí para. Èyí sì fa ọ̀pọ̀ ìrora bá mi.
Lákòókò kan tí mo ti mutí yó, mo ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́ jáde nínú òtẹ́ẹ̀lì kan, mo sì bọ́ sẹ́nu ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kan tó ń sáré bọ̀. Ọdún méjì gbáko ni mo lò lágọ̀ọ́ tí wọ́n ti ń kọ́ni láti jáwọ́ nínú àṣà búburú yìí àti lọ́dọ̀ àwọn tó ń to ara, bí iṣẹ́ darandaran mi ṣe parí nìyẹn
BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ: Nígbà tí mo wà nínú àgọ́ tí wọ́n ti ń kọ́ni láti jáwọ́ nínú àṣà búburú, ọ̀rẹ́ mi obìnrin mú àwọn ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! wá fún mi láti kà. Àmọ́, nítorí pé ọdún tí mo lò nílé ẹ̀kọ́ kò tó nǹkan, mi ò lè kàwé dáadáa. Lọ́jọ́ kan, bàbá àgbàlagbà ẹni ọdún mẹ́tàlélọ́gọ́rin [83] wá sọ́dọ̀ mi, oòrùn ń mú gan-an lọ́jọ́ náà. Mo ní kó wá mu omi tútù. Ó fún mi ní ìwé mélòó kan téèyàn fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó bi mí bóyá òun lè pa dà wá ṣàlàyé ohun tó wà nínú rẹ̀ fún mi. Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé. Mo wá ń rí i pé mo ní láti ṣe àwọn àtúnṣe kan tó pọn dandan nínú ìgbésí ayé mi tí mo bá fẹ́ rí ojú rere Ọlọ́run.
Kò rọrùn fún mi láti ṣe àwọn àyípadà tó pọn dandan yẹn. Àmọ́, nítorí ohun tí màmá mi kọ́ mi, mo bọ̀wọ̀ fún bàbá àgbàlagbà tó ń kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yìí gan-an, mo sì mọyì òye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó fi ń yé mi. Síbẹ̀ náà, mi ò tètè ya ara mi sí mímọ́ fún Ọlọ́run. Èrò mi ni pé mo ní láti kọ́kọ́ mọ gbogbo nǹkan tó wà nínú Bíbélì.
Àmọ́, ẹnì kan tá a jọ ń ṣiṣẹ́ ràn mí lọ́wọ́ láti tún èrò mi ṣe lórí ọ̀rọ̀ yìí. Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni, ó sì pe àfiyèsí mi sí ọ̀rọ̀ ìṣírí tó wà nínú Kólósè 1:9, 10. Ẹsẹ yẹn sọ pé a ní láti máa “pọ̀ sí i nínú ìmọ̀ pípéye nípa Ọlọ́run.” Ẹni tá a jọ ń ṣiṣẹ́ yìí jẹ́ kí n mọ̀ pé gbogbo ìgbà ni màá máa kẹ́kọ̀ọ́, nítorí náà mi ò nídìí láti jẹ́ kí ìwọ̀nba ohun tí mo mọ̀ báyìí fà mí sẹ́yìn.
Orí mi wú gan-an nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í dara pọ̀ mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Mo rí onírúurú èèyàn tí àṣà ìbílẹ̀ wọn yàtọ̀ tí wọ́n wà ní ìṣọ̀kan bí wọ́n ṣe ń jọ́sìn Ọlọ́run. Ìṣọ̀kan yìí ló jẹ́ kí n gbà pé mo ti rí ìsìn tòótọ́, nítorí náà, mo ṣe ìrìbọmi lọ́dún 1985, mo sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO TI RÍ: Mo ti mọ ìwé kà dáadáa, mo sì ti ń lo èyí tó pọ̀ nínú àkókò mi lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ láti kọ́ àwọn èèyàn bí wọ́n ṣe lè mọ ìwé kà, kí wọ́n sì lè kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Síwájú sí i, ọ̀rẹ́ mi obìnrin tó kọ́kọ́ mú ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! wá fún mi pé kí n kà á náà kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí, ó sì ṣe ìrìbọmi, ní báyìí, òun ni aya mi tí mo nífẹ̀ẹ́. Àwa méjèèjì ń ní ojúlówó ayọ̀ bá a ṣe ń ran àwọn ọmọ ìbílẹ̀ lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà Ọlọ́run.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 21]
Èmi àti ìyàwó mi ti ní ojúlówó ayọ̀ bá a ṣe ń ran àwọn ọmọ ìbílẹ̀ lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run