Ǹjẹ́ Ó Ṣeé Ṣe Láti Ní Ìtẹ́lọ́rùn?
“Tálákà tó ní ìtẹ́lọ́rùn, ọlọ́rọ̀ ni; ọlọ́rọ̀ tí kò ní ìtẹ́lọ́rùn, tálákà ni.”—Benjamin Franklin.
ÒÓTỌ́ ni òwe tí ọ̀gbẹ́ni yìí pa yẹn, ọ̀pọ̀ èèyàn ti rí i pé ìtẹ́lọ́rùn kò ṣeé fowó rà. Abájọ tí ìtẹ́lọ́rùn fi dà bí àléèbá nínú ayé táwọn èèyàn ti nífẹ̀ẹ́ ohun ìní rẹpẹtẹ, tí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ òkìkí tàbí ìgbé ayé gbẹdẹmukẹ táwọn ẹlòmíì ń gbé! Ǹjẹ́ èyíkéyìí lára àwọn nǹkan tó wà nísàlẹ̀ yìí ti nípa lórí rẹ?
• Àwọn tó ń polówó ọjà máa ń fi ọ̀pọ̀ ìpolówó ọjà rọni pé ríra ọ̀pọ̀ nǹkan ló lè mú kéèyàn ní ìtẹ́lọ́rùn.
• Bíbá èèyàn díje níbi iṣẹ́ tàbí nínú ìmọ̀ ẹ̀kọ́ máa ń jẹ́ kéèyàn níyì, ìyẹn téèyàn bá lè ṣe ohun táwọn ẹlòmíì gbé ṣe.
• Àwọn èèyàn kì í mọyì ohun téèyàn bá ṣe fún wọn.
• Àwọn ọ̀rẹ́ rẹ ń mú kó o ṣe ìlara ohun tí wọ́n ní.
• O kò rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè pàtàkì tó o ní nípa ìgbésí ayé.
Ṣé ó ṣeé ṣe fẹ́ni tó ní irú ìṣòro wọ̀nyí láti ní ìtẹ́lọ́rùn? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ ohun tó jẹ́ ‘àṣírí ìtẹ́lọ́rùn.’ Nígbà míì, nǹkan máa ń pọ̀ lọ́wọ́ rẹ̀, nígbà míì, kì í fi bẹ́ẹ̀ ní nǹkan lọ́wọ́. Àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ máa gbóríyìn fún un, àmọ́ àwọn ẹlòmíì máa ń pẹ̀gàn rẹ̀. Síbẹ̀, ó sọ pé òun ti “kọ́ lati ni itẹlọrùn ninu rẹ̀.”—Ìkọ̀wé wínníwínní jẹ́ tiwa; Fílípì 4:11, 12, Bibeli Mimọ.
Àwọn tí kò tíì múra tán láti ní ìtẹ́lọ́rùn kò lè mọ ohun tí ìtẹ́lọ́rùn jẹ́, àmọ́ gẹ́gẹ́ bí Pọ́ọ̀lù ti sọ, èèyàn lè kọ́ láti ní ìtẹ́lọ́rùn. A ké sí ọ láti ṣàgbéyẹ̀wò ọ̀nà márùn-ún tí Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé èèyàn lè gbà ní ìtẹ́lọ́rùn.