Bí Ìgbésí Ayé Àti Àsìkò Àwọn Kristẹni Àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ Ṣe Rí
Ìrìn Àjò sí Apá Ibi Jíjìnnà Jù Lọ ní Ilẹ̀ Ayé
“Ní ọjọ́ kejì, òun pẹ̀lú Bánábà lọ sí Déébè. Àti pé lẹ́yìn pípolongo ìhìn rere fún ìlú ńlá yẹn àti sísọ àwọn púpọ̀ díẹ̀ di ọmọ ẹ̀yìn, wọ́n padà sí Lísírà àti Íkóníónì àti sí Áńtíókù.”—ÌṢE 14:20, 21.
AFẸ́FẸ́ ń fẹ́ yẹ́ẹ́ láàárọ̀ ọjọ́ náà, bí arìnrìn-àjò náà ṣe ń gbára dì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti rẹ̀ ẹ́, ó wọ bàtà rẹ̀ tó ti jẹ. Ó fẹ́ gbéra ìrìn àjò ti ọjọ́ yẹn.
Bó ṣe ń rìn lọ nígbà tí oòrùn ṣẹ̀ṣẹ̀ yọ láàárọ̀, ó gba ọ̀nà eléruku tó wà nítòsí ọgbà àjàrà, ọ̀nà ọ̀hún gba àárín oko ólífì kọjá, ó sì forí lé ibi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè kékeré. Bó ṣe ń lọ lójú ọ̀nà, ó ń pàdé àwọn àgbẹ̀ tí wọ́n ń lọ sí oko wọn, àwọn oníṣòwò tí wọ́n mú àwọn ẹran tí wọ́n di ẹrù lé lórí dání àtàwọn arìnrìn-àjò ẹ̀sìn tó ń lọ sí Jerúsálẹ́mù. Arìnrìn-àjò yìí àtàwọn tí wọ́n ń bá a rìn ń bá ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá rí lọ́nà sọ̀rọ̀. Kí nìdí tí wọ́n fi ń rìnrìn àjò yìí? Ìdí ni pé wọ́n fẹ́ pa àṣẹ Jésù mọ́ pé kí wọ́n jẹ́ ẹlẹ́rìí òun “títí dé apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé.”—Ìṣe 1:8.
Arìnrìn-àjò yìí lè jẹ́ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tàbí Bánábà tàbí èyíkéyìí lára àwọn akíkanjú tí wọ́n jẹ́ míṣọ́nnárì ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní. (Ìṣe 14:19-26; 15:22) Wọ́n ti pinnu ohun tí wọ́n máa ṣe, wọn kò sì jẹ́ kó rẹ àwọn. Ìrìn àjò náà kò rọrùn rárá. Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń ṣàlàyé ohun tójú rẹ̀ rí lórí òkun, ó kọ̀wé pé: “Ìgbà mẹ́ta ni mo ní ìrírí ọkọ̀ rírì, òru kan àti ọ̀sán kan ni mo ti lò nínú ibú.” Ìrìn àjò orí ilẹ̀ pàápàá kò rọrùn rárá. Pọ́ọ̀lù sọ pé òun sábà máa ń ṣalábàápàdé “ewu lójú òkun” àti “ewu dánàdánà.”—2 Kọ́ríńtì 11:25-27.
Báwo ló ṣe máa ń rí téèyàn bá ń bá àwọn míṣọ́nnárì yìí rìnrìn àjò? Ibo lèèyàn lè rìn dé lójúmọ́? Kí lèèyàn ní láti mú dání, ibo lèèyàn sì máa wọ̀ sí lójú ọ̀nà?
Ìrìn Àjò Orí Ilẹ̀ Nígbà tó fi máa di ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, àwọn ará Róòmù ti ṣe àwọn ọ̀nà tó já sí àwọn ibi pàtàkì-pàtàkì ní ilẹ̀ ọba náà. Wọ́n fara balẹ̀ ṣe àwọn ọ̀nà náà, ó sì lágbára, wọ́n tún rí rèǹtè-rente. Ọ̀pọ̀ lára wọn fẹ̀ tó ẹsẹ̀ bàtà mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, òkúta ni wọ́n fi ṣe é, wọ́n fi òkúta gbá eteetí ọ̀nà náà, wọ́n sì ri òkúta tí wọ́n fi ń sàmì ibùsọ̀ sí ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà. Ní irú àwọn ọ̀nà yìí, míṣọ́nnárì kan bíi Pọ́ọ̀lù lè fẹsẹ̀ rin nǹkan bíi kìlómítà méjìlélọ́gbọ̀n lọ́jọ́ kan.
Àmọ́ ní Palẹ́sínì, ọ̀pọ̀ jù lọ ọ̀nà ló jẹ́ ọ̀nà eléruku tó sì léwu, igbó àti ọ̀gbun sì wà lọ́tùn-ún lósì. Arìnrìn-àjò kan lè bá ẹranko ẹhànnà tàbí àwọn dánàdánà pàdé, ó sì lè kan ọ̀nà tó ti dí.
Kí ni arìnrìn-àjò kan máa mú dání? Lára àwọn nǹkan pàtàkì tó máa mú dání ni, ọ̀pá láti dáàbò bo ara rẹ̀ (1), ohun tó lè tẹ́ sùn (2), àpamọ́wọ́ (3), ìpààrọ̀ bàtà kan (4), àpò oúnjẹ kan (5), ìpààrọ̀ aṣọ kan (6), korobá awọ kan tó lè fi fa omi inú kànga lójú ọ̀nà (7), ṣáágo omi kan (8), àti àpò awọ ńlá kan tó máa fi kó àwọn nǹkan tó nílò sí (9).
Àwọn míṣọ́nnárì máa ń pàdé àwọn oníṣòwò tó ń tajà láwọn ọjà tó wà ládùúgbò. Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ni àwọn oníṣòwò yìí máa ń lò, ẹsẹ̀ àwọn ẹranko yìí sì ṣe gírí nílẹ̀. Kò sí ẹranko míì tó lè rìn láwọn ọ̀nà tó dà gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ àtàwọn ọ̀nà olókùúta bí àwọn ẹran yìí. Wọ́n sọ pé, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ara rẹ̀ le tí wọ́n di ẹrù lé lórí lè rin ìrìn ọgọ́rin kìlómítà lọ́jọ́ kan. Àwọn akọ màlúù tó ń fa kẹ̀kẹ́ ẹrù kì í yára, wọn kì í lè rìn ju kìlómítà mẹ́jọ sí ogún lọ. Àmọ́, akọ màlúù lè gbé ẹrù tó wúwo, wọ́n sì dára fún ìrìn àjò ọ̀nà tí kò jìn. Arìnrìn-àjo kan lè kọjá lára àwọn ràkúnmí tàbí àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí wọ́n tò tẹ̀ lé ara wọn, tí wọ́n ń gbé ẹrù tó wá láti onírúurú ilẹ̀. Òjíṣẹ́ tó ń kó lẹ́tà, tó sì tún ń lọ jẹ́ iṣẹ́ ọba láwọn ibi tó jìnnà ní ilẹ̀ ọba náà máa ń gun ẹṣin sáré kọjá.
Nígbà tí ilẹ̀ bá ṣú, àwọn arìnrìn-àjò máa ń sùn sẹ́bàá ọ̀nà nínú àwọn àgọ́ tí wọ́n pa. Àwọn kan lè sùn sí àwọn ilé tó ní àgbàlá láàárín, àmọ́ tí wọ́n kò ṣe ohun ọ̀ṣọ́ sínú wọn. Ibẹ̀ dọ̀tí, wọn ò lè fi bẹ́ẹ̀ gba èèyàn lọ́wọ́ òjò àti òtútù tàbí lọ́wọ́ àwọn olè. Nígbàkigbà tó bá ṣeé ṣe, ọ̀dọ̀ àwọn ìdílé tàbí àwọn míì tó jẹ́ onígbàgbọ́ làwọn míṣọ́nnárì máa ń dé sí.—Ìṣe 17:7; Róòmù 12:13.
Ìrìn Àjò Orí Òkun Ọkọ̀ ojú omi kékeré máa ń gbé ẹrù àtàwọn èèyàn gba etíkun, wọ́n sì tún máa ń kọjá lórí Òkun Gálílì. (Jòhánù 6:1, 2, 16, 17, 22-24) Ọ̀pọ̀ ọkọ̀ òkun ńlá ló ń ná Òkun Mẹditaréníà, tí wọ́n máa ń gbé ẹrù lọ, gbé ẹrù bọ̀ láti àwọn èbúté tó jìnnà. Àwọn ọkọ̀ yìí máa ń kó oúnjẹ wá sí ilẹ̀ Róòmù, òun sì ni àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba máa ń wọ̀, ó sì tún máa ń gbé ìsọfúnni lọ láti èbúté kan sí òmíràn.
Ohun tó ṣeé fojú rí làwọn atukọ̀ òkun ń fi darí ọkọ̀ wọn, wọ́n máa ń lo àmì èbúté lójú mọmọ, wọ́n sì máa ń lo ìràwọ̀ lálẹ́. Nítorí náà, ìrìn àjò orí òkun kò fi bẹ́ẹ̀ léwu lóṣù May sí September, ìyẹn láwọn àkókò tó jọ pé ojú ọjọ́ túbọ̀ máa ń pa rọ́rọ́. Láyé ìgbà yẹn, ọkọ̀ òkun sábà máa ń rì.—Ìṣe 27:39-44; 2 Kọ́ríńtì 11:25.
Àwọn èèyàn kì í sábà rin ìrìn àjò orí òkun nítorí pé ó léwu ju ìrìn àjò orí ilẹ̀ lọ. Ọkọ̀ òkun akẹ́rù lèèyàn lè bá rin ìrìn àjò lórí òkun, àmọ́ ìrọ̀rùn àwọn èèyàn tó wá wọ ọkọ̀ kò kan àwọn ọlọ́kọ̀. Òkè ọkọ̀ làwọn arìnrìn-àjò máa ń wà, ibẹ̀ ni wọ́n sì máa ń sùn sí, òjò ì báà máa rọ̀ tàbí kí òtútù máa mú. Àwọn ohun iyebíye ni wọ́n máa ń kó sí ìsàlẹ̀ ọkọ̀ níbi tí omi kò lè dé. Oúnjẹ táwọn èrò ọkọ̀ gbé dání ni wọ́n máa ń jẹ. Omi mímu nìkan làwọn ọlọ́kọ̀ máa ń fún wọn. Nígbà míì, ojú ọjọ́ máa ń yí pa dà láìrò tẹ́lẹ̀. Ààrá máa ń sán, òkun máa ń ru gùdù láìdáwọ́ dúró, èyí máa ń mú káwọn èèyàn ṣàìsàn, ó sì máa ń ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọjọ́.
Láìka bí ìrìn àjò orí ilẹ̀ àti ti orí òkun ṣe nira tó, àwọn míṣọ́nnárì bíi Pọ́ọ̀lù wàásù “ìhìn rere ìjọba” náà jákèjádò ayé ìgbà yẹn. (Mátíù 24:14) Lẹ́yìn ọgbọ̀n ọdún tí Jésù pàṣẹ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n wàásù nípa òun, Pọ́ọ̀lù kọ̀wé nípa ìhìn rere náà pé, wọ́n ti wàásù rẹ̀ “nínú gbogbo ìṣẹ̀dá tí ń bẹ lábẹ́ ọ̀run.”—Kólósè 1:23.