Àsọtẹ́lẹ̀ 4. Kò Sí Ìfẹ́ Nínú Ìdílé Mọ́
‘Àwọn èèyàn kì yóò ní ìfẹ́ tó yẹ fún àwọn ìdílé wọn.’—2 TÍMÓTÌ 3:1-3, God’s Word Bible
● Obìnrin kan tó ń jẹ́ Chris jẹ́ òṣìṣẹ́ àwùjọ tó ń ṣèrànwọ́ fún àwọn tí wọ́n hùwà ipá sí nínú ilé ní North Wales. Ọ̀gbẹ́ni Chris sọ pé, “Mo rántí ọmọbìnrin kan tó wọlé wá, wọ́n ti lù ú nílùkulù débi pé, mi ò dá a mọ̀ mọ́. Ẹ̀dùn ọkàn àwọn obìnrin míì pọ̀ débi pé, wọn kò ní lè gbójú sókè wo ìwọ tó ò ń bá wọn sọ̀rọ̀.”
KÍ NI Ẹ̀RÍ FI HÀN? Ní orílẹ̀-èdè kan nílẹ̀ Áfíríkà, nǹkan bí obìnrin kan nínú mẹ́ta ni wọ́n ti bá ṣèṣekúṣe láti kékeré. Nínú ìwádìí kan tí wọ́n ṣe ní orílẹ̀-èdè yìí kan náà, ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ ìdajì àwọn ọkùnrin tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò ló gbà pé kò burú láti lu ìyàwó wọn. Àmọ́, kì í ṣe àwọn obìnrin nìkan ni wọ́n ń hùwà ipá sí nínú ilé. Bí àpẹẹrẹ, ní orílẹ̀-èdè Kánádà nǹkan bí ọkùnrin mẹ́ta nínú mẹ́wàá ni ìyàwó wọ́n ti lù nílùkulù tàbí hùwà ìkà sí.
ÀTAKÒ TÁWỌN ÈÈYÀN Ń ṢE Ó ti pẹ́ tí ìwà ipá ti ń ṣẹlẹ̀ nínú ilé. Àmọ́ ìyàtọ̀ tó wà níbẹ̀ lóde òní ni pé, wọ́n ń jẹ́ káwọn èèyàn gbọ́ nípa rẹ̀ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.
ṢÉ ÀTAKÒ YÌÍ LẸ́SẸ̀ NÍLẸ̀? Wọ́n ń jẹ́ káwọn èèyàn gbọ́ gan-an nípa ìwà ipá inú ilé láti ohun tó lé lógún ọdún sí àkókò yìí. Àmọ́, ṣé bí wọ́n ṣe ń kéde ìṣòro yìí fáyé gbọ́ ti jẹ́ kí ìwà ipá inú ilé dín kù? Rárá o. Ńṣe ni àìsí ìfẹ́ nínú ìdílé túbọ̀ ń pọ̀ sí i.
KÍ NI ÈRÒ RẸ? Ṣé ohun tó wà nínú ìwé 2 Tímótì 3:1-3 ló ń ṣẹ? Ṣé òótọ́ ni pé ọ̀pọ̀ èèyàn kò ní ìfẹ́ tó yẹ fún àwọn ìdílé wọn?
Àsọtẹ́lẹ̀ karùn-ún tó ń ṣẹ lákòókò yìí kan ayé tó jẹ́ ilé wa. Ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò ohun tí Bíbélì sọ nípa rẹ̀.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 7]
“Wọ́n sọ pé, ìwà ipá inú ilé jẹ́ ìwà ọ̀daràn tí wọn kì í sọ síta láwùjọ wa lónìí. Ìwádìí fi hàn pé ó máa ń tó ìgbà márùndínlógójì [35] ni ọkọ kan máa ń hùwà ìkà sí ìyàwó rẹ̀ kí obìnrin náà tó sọ fún ọlọ́pàá.”—AGBỌ̀RỌ̀SỌ ÀWÙJỌ TÓ Ń ṢÈRÀNWỌ́ FÚN ÀWỌN TÍ WỌ́N HÙWÀ IPÁ SÍ NÍNÚ ILÉ NÍLẸ̀ WALES.