Bíbélì Máa Ń Yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà
KÍ LÓ mú kí gbajúmọ̀ olórin kan fi iṣẹ́ orin sílẹ̀ tó wá di òjíṣẹ́ ẹ̀sìn tó ń fi ọ̀pọ̀ àkókò wàásù? Kí ló sì mú kí ọ̀daràn kan tí adájọ́ pè ní ẹni tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ ti kọjá àtúnṣe di ẹni tó wúlò láwùjọ? Ka ìtàn wọ̀nyí kó o lè rí ìdáhùn àwọn ìbéèrè yìí.
“Kò sí ẹnì kan tí ó lè sìnrú fún ọ̀gá méjì.”—ANTOLINA ORDEN CASTILLO
ỌDÚN TÍ WỌ́N BÍ MI: 1962
ORÍLẸ̀-ÈDÈ: SPAIN
IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀: ELÉRÉ ORÍ ÌTÀGÉ ÀTI OLÓRIN
ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ: Wọ́n bí mi ní abúlé kékeré tó ń jẹ́ Tresjuncos, ní ìpínlẹ̀ La Mancha. Iṣẹ́ àgbẹ̀ ni ìdílé wa ń ṣe. Kátólíìkì ni màmá mi, bàbá mi sì jẹ́ ẹlẹ́sìn Pùròtẹ́sítáǹtì. Bàbá mi kọ́ mi láti bọ̀wọ̀ fún Bíbélì, mo sì rí i tó máa ń kà á nígbà gbogbo. Ṣùgbọ́n ẹ̀kọ́ ìsìn Kátólíìkì ni màmá mi fi tọ́ mi, ó sì máa ń mú mi lọ sí Máàsì ní gbogbo ọjọ́ Sunday.
Nígbà tí mo wà ní ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, mo fi abúlé wa sílẹ̀ lọ gbé ní Madrid lọ́dọ̀ ẹ̀gbọ́n mi obìnrin. Àárò àwọn òbí mi sọ mí púpọ̀ àmọ́ nígbà tó yá, ìgbésí ayé ìgboro mọ́ mi lára. Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́tàdínlógún, mo láǹfààní láti bá ẹgbẹ́ olórin Sípáníìṣì kan ṣiṣẹ́ fún oṣù díẹ̀. Mo gbádùn irú ìgbésí ayé yẹn gan-an ni, mo sì fẹ́ láti di eléré orí ìtàgé. Mo kúrò níbi tí mo ti ń gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ iṣẹ́ akọ̀wé, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọrin pẹ̀lú oríṣiríṣi ẹgbẹ́ olórin Sípáníìṣì. Ìgbà yìí náà ni mo bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́ mọ̀lẹ́bí ọ̀kan lára àwọn ọ̀rẹ́ mi obìnrin. Mo rìnnà kore nítorí pé mo ní iṣẹ́ tó dáa, mo ní owó àti ẹni tó nífẹ̀ẹ́ mi.
Mo bẹ̀rẹ̀ sí í rìnrìn àjò pẹ̀lú oríṣiríṣi ẹgbẹ́ olórin Sípáníìṣì jákèjádò orílẹ̀-èdè Sípéènì àtàwọn orílẹ̀-èdè bíi Kòlóńbíà, Costa Rica, Ecuador àti Fẹnẹsúélà. Mo tún kọrin pẹ̀lú oríṣiríṣi àwùjọ olórin “La movida madrileña,” orin yìí sì gbajúmọ̀ nílùú Madrid. Mo jẹ́ aṣáájú fún ọ̀kan lára àwọn àwùjọ tí mò ń bá kọrin, àwùjọ náà sì ṣàṣeyọrí tó pọ̀.
Mo fẹ́ràn iṣẹ́ náà, àmọ́ mo kórìíra ìwà ìṣekúṣe tí àwọn tó ń ṣiṣẹ́ náà máa ń hù. Àmọ́, mo jẹ́ kí ìmúra àti ìtúnraṣe gbà mí lọ́kàn, mo sì fẹ́ máa gba ògo. Mo máa ń ṣọ́ oúnjẹ jẹ gan-an, nítorí náà mi ò lè jẹun dáadáa mọ́, tí mo bá sì jẹun mo máa bì í nítorí kí n má bàa sanra.
Ohun tó ṣì wù mí ni pé, mo fẹ́ di eléré orí ìtàgé. Nígbà tó yá, wọ́n gbà mí sí Ilé Ẹ̀kọ́ Eré Orí Ìtàgé nílùú Madrid. Wọ́n kọ́ wa pé ṣíṣe eré orí ìtàgé gba pé kéèyàn fi ara rẹ̀ sí ipò ẹni tí ìtàn náà ń sọ nípa rẹ̀, kéèyàn sì hùwà bíi ti ẹni náà. Nígbà tí mo fi àmọ̀ràn yìí sílò, mo wá rí i pé mi ò ní ọ̀nà pàtó kan tí mo gbà ń ronú mọ́, ohun tí wọ́n bá sọ pé kí n ṣe ni mò ń ṣe. N kò lè darí ìgbésí ayé mi mọ́, mo sì wá di ẹni tó mọ tara rẹ̀ nìkan.
BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ: Mo mọ̀ pé tí mo bá fẹ́ ní àwọn ìwà rere mo ní láti sapá gan-an. Ṣùgbọ́n n kò mọ bí mo ṣe fẹ́ ṣe é. Mo lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì ajíhìnrere kan ní Madrid, mo ti bá àwọn òbí mi lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì náà lẹ́ẹ̀kan rí. Mo gbàdúrà sí Ọlọ́run, orúkọ rẹ̀ tó ń jẹ́ Jèhófà ni mo sì lò.
Kò pẹ́ tí méjì lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi wá sí ilé mi. Mo fi taratara bá wọn sọ̀rọ̀ nípa ohun tí mo mọ̀ nínú Bíbélì, àmọ́ mo tún sọ ọ̀pọ̀ nǹkan tí n kò fara mọ́ nínú ohun tí wọ́n fi ń kọ́ni. Orúkọ Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó máa ń wá kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ ni Esther, obìnrin yìí ní sùúrù gan-an. Òun àtàwọn ará ilé rẹ̀ nífẹ̀ẹ́ mi gan-an, wọ́n sì máa ń jẹ́ kí ara tù mí. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, kò sì pẹ́ tí mo fi gbà pé mo ti rí òtítọ́ tí mo ti ń wá tipẹ́.
Nígbà tí mo parí ẹ̀kọ́ mi nílé ẹ̀kọ́ eré orí ìtàgé, ọ̀pọ̀ àǹfààní ṣí sílẹ̀ fún mi láti rí iṣẹ́ tí màá fi ìgbésí ayé mi ṣe. Wọ́n gbà mí láti kó ipa kan nínú eré orí ìtàgé tí wọ́n máa fi hàn ní gbọ̀ngàn ìwòran kan tó gbajúmọ̀ nílùú Madrid. Àmọ́ mo tún mọ̀ pé kí n tó lè ṣàṣeyọrí gẹ́gẹ́ bí eléré orí ìtàgé, mo ní láti lo gbogbo àkókò àti okun mi fún eré náà. Nígbà tó yá, mo pinnu pé màá wá iṣẹ́ mìíràn tó máa fún mi láyè láti gbájú mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run. Mo fi ọ̀rọ̀ Jésù sọ́kàn, èyí tó sọ pé: “Kò sí ẹnì kan tí ó lè sìnrú fún ọ̀gá méjì; nítorí yálà òun yóò kórìíra ọ̀kan, kí ó sì nífẹ̀ẹ́ èkejì, tàbí òun yóò fà mọ́ ọ̀kan, kí ó sì tẹ́ńbẹ́lú èkejì. Ẹ kò lè sìnrú fún Ọlọ́run àti fún Ọrọ̀.” (Mátíù 6:24) Ọ̀rẹ́kùnrin mi tá a ti jọ wà fún ọdún mẹ́jọ kò fára mọ́ ohun tí mo gbà gbọ́, nítorí náà mo pinnu láti fòpin sí àjọṣe wa. Kò sí èyí tó rọrùn nínú àwọn àyípadà tí mo ṣe yìí.
ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO TI RÍ: Ní báyìí, àkókò díẹ̀ ni mo fi ń ṣiṣẹ́ lóòjọ́, mo sì máa ń ṣe ohun tó ń dá àwọn àgbàlagbà lára yá. Èyí fún mi láǹfààní láti máa fi ọ̀pọ̀ àkókò mi kọ́ àwọn èèyàn tó ń sọ èdè Lárúbáwá tó wà ládùúgbò mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Iṣẹ́ kékeré kọ́ ni mo ṣe kí n tó lè kọ́ èdè tuntun yìí, àmọ́ mò ń gbádùn bí mo ṣe ń wàásù fún àwọn èèyàn yìí nípa àwọn nǹkan rere tí mo ti kọ́, àwọn èèyàn yìí nífẹ̀ẹ́ àlejò gan-an, wọ́n sì ń fẹ́ mọ̀ nípa Ọlọ́run.
Bí mi ò ṣe ní ọ̀nà pàtó kan tí mo ń gbà ronú nígbà tí mò ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa eré orí ìtàgé ti wá yàtọ̀ báyìí, ìgbésí ayé mi ti ní ìtumọ̀. Mo gbà pé Jèhófà ti mú kí ìgbésí ayé mi sunwọ̀n sí i, mo sì ń láyọ̀ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.
“Mo ti fi hàn pé ohun tí adájọ́ yẹn sọ kì í ṣe òótọ́.”—PAUL KEVIN RUBERY
ỌDÚN TÍ WỌ́N BÍ MI: 1954
ORÍLẸ̀-ÈDÈ: ENGLAND
IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀: Ọ̀DARÀN ONÍWÀ IPÁ
ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ: Ìlú Dudley, ni wọ́n ti bí mi, àgbègbè yìí sì jẹ́ ibi táwọn ilé iṣẹ́ pọ̀ sí ní West Midlands. Láti kékeré ni bàbá mi ti mú kí n nífẹ̀ẹ́ láti máa kàwé. Ó tún mú kí n mọyì àwọn nǹkan bí igi, òdòdó, ẹranko, àwọn nǹkan tó wà lójú ọ̀run àtàwọn nǹkan tó wà nínú omi, àmọ́ ó sọ pé àwọn nǹkan yìí dédé wà ní, kò sí ẹni tó dá wọn. Ó kọ́ mi pé Ọlọ́run kò sí. Síbẹ̀, àwọn òbí mi ní kí n máa lọ sí ilé ẹ̀kọ́ Ọjọ́ Ìsinmi ní ṣọ́ọ̀ṣì Mẹ́tọ́díìsì tó wà ládùúgbò wa.
Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́jọ, mo rí àwọn ọmọkùnrin kan tá a jọ wà ládùúgbò tí wọ́n dáná sun ọkọ̀ ojú omi kan tó wà lórí omi. Nígbà tí àwọn ọlọ́pàá dé, ẹ̀rù bà mí láti sọ àwọn tó ṣe iṣẹ́ ibi náà. Àwọn ọmọkùnrin náà ti halẹ̀ mọ́ mi. Wọ́n fi ẹ̀sùn kàn mí láìtọ́ nítorí ìwà ibi náà, ìyẹn sì múnú bí mi gan-an. Nítorí náà, mo ba àwọn nǹkan jẹ́ nínú ilé ẹ̀kọ́, ṣọ́ọ̀ṣì àtàwọn ilé iṣẹ́ kan tó wà ládùúgbò, àwọn ohun tí mo bà jẹ́ níbẹ̀ tó ẹgbẹẹgbẹ̀rún owó dọ́là. Nígbà tí mo fi máa di ọmọ ọdún mẹ́wàá, mo ti bẹ̀rẹ̀ sí í fọ́ àwọn ilé àtàwọn ṣọ́ọ̀bù láti jí nǹkan. Mo fẹ́ràn láti máa dáná sun nǹkan, mo sì dáná sun ọ̀pọ̀ dúkìá. Nígbà tí mo wà nílé ìwé, ewèlè ọmọ làwọn olùkọ́ ń pè mí.
Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún méjìlá, mo rí ìwé kan tó sọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ awo, mo sì ṣe ọpọ́n ìwoṣẹ́ kan tó ń jẹ́ Ouija. Nítorí pé àwọn òbí mi kò gbà pé Ọlọ́run wà, wọ́n rò pé kò sí ewu nínú bí mo ṣe nífẹ̀ẹ́ sí iṣẹ́ awo, wọ́n sì rò pé ìyẹn á gbà mí kúrò lọ́wọ́ wàhálà. Àmọ́ kí n tó kúrò nílé ẹ̀kọ́, ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n mú mi lọ sílé ẹjọ́ àwọn ọmọ ìpáǹle. Mo dara pọ̀ mọ́ ẹ̀gbẹ́ oníwà ipá kan tí wọ́n ń pè ní afáríkodoro. Ohun ìjà tí mo máa ń mú kiri ni, abẹfẹ́lẹ́ àti ṣéènì kẹ̀kẹ́ tàbí ti alùpùpù. Mo rí iṣẹ́ kan, àmọ́ kò pẹ́ tó fi bọ́ mọ́ mi lọ́wọ́ nítorí pé mo lọ fẹ̀wọ̀n jura fúngbà díẹ̀. Nígbà tí wọ́n dá mi sílẹ̀, mo tún bẹ̀rẹ̀ sí í ba dúkìá àwọn èèyàn jẹ́, ni wọ́n bá tún mú mi, wọ́n sì fi mí sẹ́wọ̀n ọdún méjì gbáko. Adájọ́ sọ pé ọ̀rọ̀ mi ti kọjá àtúnṣe àti pé ewu ni mo jẹ́ fún àwọn ará ìlú.
Nígbà tí wọ́n dá mi sílẹ̀ lẹ́wọ̀n, mo lọ bá Anita tó jẹ́ ọ̀rẹ́bìnrin mi nígbà kan rí. A ṣe ìgbéyàwó, mo sì dáwọ́ olè jíjà tàbí fífa wàhálà dúró fúngbà díẹ̀. Àmọ́ lẹ́yìn ọdún mélòó kan, mo tún bẹ̀rẹ̀ sí í hùwà ọ̀daràn. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í wọ ibi ìṣòwò, mo sì ń fipá jí owó wọn níbi tí wọ́n kó àwọn owó náà pa mọ́ sí. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í lo oògùn olóró, mò ń mu ọtí tó pọ̀ gan-an, mo sì ń gbé ìbọn kiri. Ni wọ́n bá tún mú mi, wọ́n sì sọ mí sẹ́wọ̀n.
Bí mo ṣe ń gbé ìgbé ayé mi kó ìbànújẹ́ tó pọ̀ gan-an bá Anita. Dókítà rẹ̀ sọ fún un pé kó máa lo oògùn tó ń mú ara ẹni balẹ̀, àmọ́ ó sọ fún un pé ohun kan ṣoṣo tó máa yanjú ìṣòro rẹ̀ ni pé kó kọ̀ mí sílẹ̀. Inú mi dùn pé kò tẹ̀ lé ìmọ̀ràn náà.
BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ: Nígbà tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe ìgbéyàwó, Anita kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fúngbà díẹ̀. Nígbà tí mò ń ṣẹ̀wọ̀n, èyí tí mo ṣe kẹ́yìn, ó tún bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pàdé. Ó sì wá jẹ́ ní ọjọ́ kan náà tí mo gbàdúrà sí Ọlọ́run pé, “Jẹ́ kí n mọ̀ tí o bá wà lóòótọ́.”
Nígbà tí wọ́n dá mi sílẹ̀ lẹ́wọ̀n ní oṣù mélòó kan lẹ́yìn náà, mo lọ bá àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì tó wà ládùúgbò wa pé kó kọ́ èmi àti Anita lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó sọ pé ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn nìkan àti àdúrà kan lòun máa kọ́ wa.
Níkẹyìn, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ka Bíbélì. Ó yà mí lẹ́nu láti mọ̀ pé Bíbélì sọ pé kò dára láti máa lọ́wọ́ nínú ìbẹ́mìílò. (Diutarónómì 18:10-12) Nígbà tó yá, mo rí Ilé Ìṣọ́ kan táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fún Anita lọ́jọ́ tí mo gbàdúrà pé kí Ọlọ́run ràn mí lọ́wọ́. Ohun tí mo kà nínú ìwé náà mú kí n wá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà rí.
Inú àwọn ìdílé wa, àwọn ọ̀rẹ́ wa àtàwọn ọ̀daràn ẹlẹgbẹ́ mi kò dùn nígbà tí wọ́n gbọ́ pé à ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àwọn kan sọ pé, wọ́n ti fi ẹ̀kọ́ wọn yí ọpọlọ mi pa dà. Ká sòótọ́, mo ní láti fọ àwọn nǹkan tí kò dára kúrò lọ́pọlọ mi. Mo ní ọ̀pọ̀ kùdìẹ̀kudiẹ, ẹ̀rí ọkàn mi kò ṣiṣẹ́ dáadáa mọ́, mo sì ní àwọn ìwàkíwà míì, yàtọ̀ sí ìyẹn, ọgọ́ta sìgá ni mò ń mu lójúmọ́. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ àtàwọn tá a máa ń bá kẹ́gbẹ́ ní ìpàdé ní sùúrù gan-an, wọ́n sì láàánú. Níkẹyìn, mo jáwọ́ nínú ìwà burúkú tí mò ń hù.—2 Kọ́ríńtì 7:1.
ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO TI RÍ: Ní báyìí, èmi àti Anita ti wà pa pọ̀ gẹ́gẹ́ bí tọkọtaya fún ọdún márùndínlógójì [35]. Àwa àti ọ̀kan lára àwọn ọmọ wa àtàwọn méjì lára àwọn ọmọọmọ wa la jọ ń sin Jèhófà. Lẹ́nu àwọn ọdún àìpẹ́ yìí, èmi àti Anita ti láǹfààní láti fi ọ̀pọ̀ àkókò wa kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
Bí a ṣe ń jọ́sìn Jèhófà Ọlọ́run tí mú kí ìgbésí ayé wa ní ìtumọ̀ gidi. Lọ́dún 1970, adájọ́ kan sọ fún ilé ẹjọ́ pé, ọ̀rọ̀ mi ti kọjá àtúnṣe. Àmọ́ pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run àti ìlànà tó wà nínú Bíbélì, mo ti fi hàn pé ohun tí adájọ́ yẹn sọ kì í ṣe òótọ́.