Ǹjẹ́ Gbogbo Àwọn Tó Ń Pe Ara Wọn Ní Kristẹni Ni Kristẹni Tòótọ́?
KRISTẸNI mélòó ló wà láyé? Ìwé Atlas of Global Christianity jẹ́ ká mọ̀ pé lọ́dún 2010, iye Kristẹni tó wà láyé dín díẹ̀ ní ẹgbẹ̀rún ọ̀kẹ́ lọ́nà ọgọ́rùn-ún àti ààbọ̀. Àmọ́ ìwé yìí sọ pé àwọn Kristẹni yẹn pín sí oríṣiríṣi ẹ̀ka ìsìn tó ju ẹgbẹ̀rún mọ́kànlélógójì [41,000] lọ, àti pé olúkúlùkù wọn ló ní ẹ̀kọ́ ìsìn àti ìlànà ìwà híhù tirẹ̀. Abájọ tó fi jẹ́ pé táwọn èèyàn bá wo bí àwọn ẹ̀sìn tí à ń pè ní Kristẹni ṣe pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ, ó máa ń tojú sú wọn tàbí kó tiẹ̀ kó ìrẹ̀wẹ̀sì báwọn. Wọ́n lè wá máa bi ara wọn pé, ‘Ṣé gbogbo àwọn tó pe ara wọn ní Kristẹni náà ni Kristẹni tòótọ́?’
Ẹ jẹ́ ká wo ọ̀rọ̀ náà lọ́nà yìí. Arìnrìn-àjò láti orílẹ̀-èdè kan sí òmíràn sábà máa ń jẹ́ kí àwọn aṣọ́bodè mọ ọmọ orílẹ̀-èdè tóun jẹ́ kó tó lè kọjá. Ó sì ní láti fi ìwé àṣẹ ìrìnnà rẹ̀ hàn wọ́n láti fi jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀. Bákan náà, tí ẹnì kan bá kàn sọ pé òun gba Kristi gbọ́, ìyẹn nìkan kò tó láti fi hàn pé Kristẹni tòótọ́ ni. Ó gbọ́dọ̀ tún ní ẹ̀rí tó máa fi hàn pé òótọ́ ló ń sọ. Kí wá ni ẹ̀rí náà?
Ẹ̀yìn ọdún 44 Sànmánì Kristẹni ni wọ́n kọ́kọ́ lo ọ̀rọ̀ náà “Kristẹni.” Lúùkù tó jẹ́ òpìtàn kan nínú Bíbélì sọ pé: “Áńtíókù . . . ni a ti kọ́kọ́ tipasẹ̀ ìdarí àtọ̀runwá pe àwọn ọmọ ẹ̀yìn ní Kristẹni.” (Ìṣe 11:26) Ṣàkíyèsí pé àwọn tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yin Kristi ni wọ́n pè ní Kristẹni. Kí ló máa fi hàn pé ẹnì kan jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù Kristi? Ìwé kan tó ń ṣàlàyé ọ̀rọ̀ inú Májẹ̀mú Tuntun, ìyẹn The New International Dictionary of New Testament Theology, sọ pé: “Ẹni tó bá jẹ́ ọmọlẹ́yìn Jésù gbọ́dọ̀ fi gbogbo ayé [rẹ̀] fún un pátápátá láìkù síbì kankan . . . jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀.” Nítorí náà, ẹni tó bá jẹ́ Kristẹni tòótọ́ yóò máa tẹ̀ lé gbogbo ẹ̀kọ́ àti ìtọ́ni Jésù Olùdásílẹ̀ ìsìn Kristẹni, láì jẹ́ kó ṣẹ́ kù síbì kankan.
Lónìí, ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe kí á rí àwọn èèyàn tó ń ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ lára àwọn tí à ń pè ní Kristẹni? Kí ni Jésù sọ pé a máa fi dá àwọn ọmọlẹ́yìn òun tòótọ́ mọ̀? Jẹ́ ká wo bí Bíbélì ṣe dáhùn àwọn ìbéèrè yìí. Nínú àwọn àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí, a ó ṣàyẹ̀wò nǹkan márùn-ún tí Jésù sọ, tí àwọn ojúlówó ọmọlẹ́yìn rẹ̀ gbọ́dọ̀ máa ṣe, èyí tá a fi máa dá wọn mọ̀ yàtọ̀. A ó sì wo ẹ̀rí tó fi hàn pé àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ń ṣe nǹkan wọ̀nyẹn. A tún máa wo àwọn tó ń ṣe bíi tiwọn lára àwọn tó sọ pé Kristẹni làwọn lónìí.