ǸJẸ́ O MỌ̀?
Báwo ni àwọn Júù ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ṣe ń múra òkú sílẹ̀ kí wọ́n tó lọ sin ín?
Àwọn Júù kì í jẹ́ kó pẹ́ rárá kí wọ́n tó sìnkú. Lọ́pọ̀ ìgbà, ọjọ́ tí òkú bá kú náà ni wọ́n máa ń sin ín. Ohun méjì ló fà á tí wọ́n fi máa ń tètè sin òkú wọn. Ìdí àkọ́kọ́ ni pé òkú kì í pẹ́ jẹrà ní Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn tí ojú ọjọ́ ti máa ń móoru gan-an. Ìdí kejì ni pé, láyé ìgbà yẹn, wọ́n gbà pé tí wọ́n bá fi òkú ẹnì kan sílẹ̀ láìsin fún ọjọ́ mélòó kan, ṣe ni wọ́n fi tàbùkù sí òkú náà àti ìdílé rẹ̀.
Nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere àti ìwé Ìṣe, a lè rí àkọsílẹ̀ mẹ́rin ó kéré tán nípa àwọn tó jẹ́ pé ọjọ́ tí wọ́n kú náà ni wọ́n sin wọ́n. (Mátíù 27:57-60; Ìṣe 5:5-10; 7:60–8:2) Ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún ṣáájú ìgbà yẹn, nígbà tí Jákọ́bù àti ìdílé rẹ̀ ń rìnrìn àjò, Rákélì aya rẹ̀ ọ̀wọ́n kú. Jákọ́bù kò wulẹ̀ gbé òkú Rákélì wá sin sí ibojì ìdílé wọn, ṣe ló sin ín sí sàréè kan “lójú ọ̀nà . . . Bẹ́tílẹ́hẹ́mù.”—Jẹ́nẹ́sísì 35:19, 20, 27-29.
Ohun tí Bíbélì sọ nípa ààtò ìsìnkú fi hàn pé àwọn Júù máa ń fara balẹ̀ múra òkú sílẹ̀ kí wọ́n tó lọ sin ín. Àwọn mọ̀lẹ́bí àti ọ̀rẹ́ ẹni tó kú náà máa kọ́kọ́ wẹ ara òkú náà, wọ́n á wá fi èròjà atasánsán àti òróró iyebíye pa á lára, wọ́n á sì fi aṣọ wé e. (Jòhánù 19:39, 40; Ìṣe 9:36-41) Àwọn ará àdúgbò àti àwọn míì sì lè wá bá ìdílé náà kẹ́dùn, kí wọ́n sì tù wọ́n nínú.—Máàkù 5:38, 39.
Ṣé bí àwọn Júù ṣe máa ń sìnkú ni wọ́n ṣe sin Jésù?
Ọ̀pọ̀ nínú àwọn ìdílé tó jẹ́ Júù ló máa ń sin èèyàn wọn tó bá kú sínú hòrò tàbí inú ibojì tí wọ́n gbẹ́ sínú àwọn àpáta tí kò fi bẹ́ẹ̀ le, èyí tó wọ́pọ̀ ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì. Ohun tí àwọn baba ńlá ayé ìgbàanì ṣe ni àwọn náà ń tẹ̀ lé. Bí àpẹẹrẹ, inú hòrò Mákípẹ́là tó wà nítòsí Hébúrónì ni wọ́n sin Ábúráhámù, Sárà, Ísákì, Jákọ́bù àti àwọn míì sí.—Jẹ́nẹ́sísì 23:19; 25:8, 9; 49:29-31; 50:13.
Inú ibojì tí wọ́n gbẹ́ sínú àpáta ràbàtà ni wọ́n sin Jésù sí. (Máàkù 15:46) Irú sàréè bẹ́ẹ̀ sábà máa ń ní ẹnu ọ̀nà tóóró. Ó máa ń ní àyè bíi mélòó kan tí wọ́n gbẹ́ síbẹ̀, tí wọ́n lè máa gbé òkú àwọn mọ̀lẹ́bí wọn sí. Tí òkú náà bá ti jẹrà tán, wọ́n á wá kó àwọn egungun rẹ̀ sínú àpótí tí wọ́n fi òkúta ṣe, tí wọ́n máa ń kó egungun òkú sí. Èyí á jẹ́ kí wọ́n tún lè rí àyè sin àwọn míì tó bá kú nínú ìdílé wọn. Bí wọ́n ṣe máa ń sin òkú nígbà ayé Jésù nìyẹn.
Lábẹ́ Òfin Mósè, àwọn Júù gbọ́dọ̀ sinmi lọ́jọ́ Sábáàtì, torí náà wọn kì í lè ṣe ààtò ìsìnkú lọ́jọ́ náà. Torí pé nǹkan bí wákàtí mẹ́ta ló kù kí Sábáàtì bẹ̀rẹ̀ nígbà tí Jésù kú, Jósẹ́fù ará Arimatíà àti àwọn yòókù kò lè parí gbogbo ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe sí òkú Jésù kí wọ́n tó sin ín. (Lúùkù 23:50-56) Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé, lẹ́yìn Sábáàtì, àwọn ọ̀rẹ́ Jésù kan lọ sí ibojì tí wọ́n sin Jésù sí kí wọ́n lè lọ parí ààtò ìsìnkú rẹ̀.—Máàkù 16:1; Lúùkù 24:1.